Search This Blog

BÍBÍIRE Apá kìn-ín-ní

Àbí yóó wù ọ́ láti gbọ́ àkọsílẹ̀ yìí dípò kíkà á? Tẹ ibí.

Láti kékeré ni mo ti máa ń gbọ́ ọ lẹ́nu àwọn àgbàlagbà pé, "Bíbíire ò ṣeé fowó rà." Ọ̀rọ̀ ọ̀hún ò fìgbà kan yé mi rí àfìgbà tí mo bẹ̀rẹ̀ si í dàgbà. Ẹni a bíire ló réèyàn gidi pè é wáyé. Ẹni a bíire ló rí òbí tó ṣe é fi yangan pè ní bàbá àti ìyá. Ẹni a bíire lòbí ń jòkóò Pṣèpàdé lórí bí ètò ayé rẹ̀ ò ṣe ní í lọ́ kí wọ́n tóó bí i. 

Òun gan-an pàápàá la lè pè lọ́mọ́ èèyàn. Torí bó bá jẹ́ ti ká bímọ sílẹ̀ ni, béèyàn ti ń bímọ náà lajá ń bí tiẹ̀. Ohun tó ya ọmọ èèyàn sọ́tọ̀ ò ju pé kí àwọn òbí rẹ̀ tóó bí i ni wọ́n ti mọ irú ìṣòro tí í máa kojú èèyàn láyé, láti ìgbà náà sì ni wọn óó ti bẹ̀rẹ̀ si í palẹ̀mọ́ bí àtigbáyé ọmọ ọ̀hún ò ṣe ní í nira. 

Ọwọ́ bàbá gan-an ni ìpalẹ̀mọ́ ọmọ ti ń bẹ̀rẹ̀. Torí kò sọ́kùnrin tí yóó ní òun kò mọ̀ pé kóun tóó le dẹnu fífẹ́ kọ obìnrin tí yóó gbà fóun, òun gbọ́dọ̀ ti múra dáadáa débi pé ọkàn obìnrin ọ̀hún yóó balẹ̀ pé òun tó ẹrù rẹ̀ í gbé. Ẹrù wo lobìnrin wáá ń dì bọ̀ sílé ọkọ rẹ̀ tó ju ọmọ lọ. Ọwọ́ obìnrin lọmọ́ wà, ìkáwọ́ rẹ̀ náà sì ni Ọlọ́run tọ́jú àṣẹ láti sọ ọkùnrin di bàbá ọmọ sí. Ìyẹn bí a bá yọwọ́ obìnrin tí wọ́n fipá bá lòpọ̀ tàbí ẹni tí wọ́n fi lọ́kọ láyé ijọ́un.

Àwọn èèyàn gidi tí wọ́n ti wo ara wọn dáadáa pé àwọn kúnjú òṣùwọ̀n yìí ni wọ́n ń bí ẹni a bíire. Irú wọn lọmọ le fi yangàn pé àwọn òbí òun nìyẹn.

Kò tètè yé mi. Àwá kàn máa n fi ọ̀rọ̀ náà ṣeré láàárín ara wa gẹ́gẹ́ bíi ọmọdé ni. Bí a bá fẹ́ẹ́ fojú di ẹnì kan pé kò le ṣe nǹkan kan, a óó ní wọn ò bí i dáa kó ṣe é. Àṣé ọ̀rọ̀ tó wúwo gidi ni.

Irú eré báyìí lèmi àti àwọn akẹgbẹ́ mi fi ọ̀rọ̀ yìí ṣe nínú kíláàsì lọ́jọ́ kan. N ò tilẹ̀ rántí ohun tá à ń sọ pé wọn ò bí onítọ̀hún dáa kó ṣe mọ báyìí torí ọjọ́ ọ̀hún ti pẹ́ gidi. N ò lérò pé mo ju ọmọ ọdún mọ́kànlá sí mẹ́jìlá lọ nígbà náà. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí olùkọ́ mi sọ fún wa, n ò le gbagbe títí tí n óó fi wọlẹ̀ Ọlọ́run sùn.

Àlejò tó wá a wá sí kíláàsì ló sọ fún un pé ọ̀rọ̀ tí àwọn ọmọ yìí fi ń ṣeré ò dáa o. Nígbà tí yóó sì dáhùn, ó ní "Ẹ̀h! Èwo ni wọ́n bíiré nínú gbogbo wọn náà tẹ́lẹ̀? Nígbà tó jẹ́ yíyé làwọn òbí wọn yé wọn jọ sílẹ̀ bíi ẹyin adìẹ. Kí wọ́n jọ máa pe ara wọn lọ́mọ ìrankíran. Èwo làgbà nínú ọmọ ajá!"

Pẹ̀lú bá a ṣe kéré tó nígbà náà, ara gbogbo wa sì wàlẹ̀ sìì bíi epo gbígbóná tí wọ́n paná nídìí ẹ̀. Ọ̀rọ̀ burúkú tí ò yẹ kéèyàn sọ létí ọmọdé lobìnrin yìí sọ. Ṣùgbọ́n ohun tó jẹ́ olórí ìbànújẹ fún wa gan-an ni pé — òótọ́ ọ̀rọ̀ ni.

Àh! Mo ti sọ̀rọ̀ jìnnà kí n tóó júwe ara mi. Ẹ má bínú, ohun tó kú ń dunni ní í pọ̀ lọ́là ẹni. 

Aríyìíkẹ́ lorúkọ mi. Ìlú Ìlobùú tó wà nípìnlẹ̀ Ọ̀ṣun ni wọ́n ti bí ìyá àti bàbá mi. Torí ìdí èyí bí mo bá pe ara mi lójúlówó ọmọ ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, n ò jayò pa. Ẹlẹ́karùn-ún ni mi nínú àwà ọmọ méje tí ìyá mi bí fún bàbá mi.

Nígbà tí mo bá bẹ̀rẹ̀ si í bá ìtàn ìgbésí ayé mi lọ, ẹ óó rídìí tí mo fi ní òótọ́ ọ̀rọ̀ lobìnrin burúkú tó pe ara rẹ̀ lólùkọ́ yìí sọ fún wa. 

Ṣùgbọ́n ohun tóun ò mọ̀ ni pé...


Ẹni a bí i re, kò dà bíi ẹni a tọ́ọre. Ẹni a tọ́ọre náà ò tún wáá dà bíi ẹni tó yàare.
Aríyìíkẹ́ lorúkọ mi. Èyí nìtàn ìgbésí ayé mi.


Post a Comment

0 Comments