Search This Blog

Ìtàn ṣókí nípa ìgbésí ayé Olóyè Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ (Yorùbá)

 

Àbí yóó wù ọ́ láti gbọ́ àkọsílẹ̀ yìí dípò kíkà á? Tẹ ibí
Ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ààrẹ àná orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni Olóyè Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́. Òun ni olóri ààrẹ àkọ́kọ́ tí yóó darí ìjọba Nàìjíríà lẹ́ẹ̀mejì, bó ti darí Nàìjíríà lásìkò ológun, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe ààrẹ fún un lásìkò ìjọba tiwa-n-tiwa. Oríṣìíríṣìí àṣeyọrí ni Ọbásanjọ́ ti ṣe lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó sọ orúkọ rẹ̀ di mánigbàgbé fún gbogbo ọmọ Nàìjíríà. Òun ni olóri ológun àkọ́kọ́ tí yóó gbéjọba fáwọn olóṣèlú alágbádá, ọ̀kan pàtàkì sì ni nínú àwọn tí wọ́n jagun abẹ́lé Nàìjíríà lọ́dún 1967 sí 1970. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Yorùbá tí orúkọ wọn ti là kọjá ilẹ̀ Yorùbá, Áfíríkà àti àgbáyé lápapọ̀ ni.

ÌBẸ̀RẸ̀ ÌGBÉSÍ AYÉ Ẹ̀

A bí Olóyè Olúṣẹ́gun Mathew Òkìkìọlá Ọbalúayésanjọ́ sínú ìdílé Amos Àdìgún Ọbalúayésanjọ́ (Ọbásanjọ́) Bánkọ́lé àti Àṣàbí Ọbalúayésanjọ́ nílùú Abẹ́òkúta lọ́jọ́ karùn-ún, oṣù kẹta ọdún 1937.

Iléèwé Saint David Ebenezer School tó wà n'Íbògún ló ti kẹ́kọ̀ọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1948, lẹ́yìn tó ṣetán níbẹ̀ ló lọ sí Baptist Boys High School l'Ábẹ́òkúta, níbi tó ti kàwé girama láàárín ọdún 1952 sí 1957.

Ó wọ iléeṣẹ́ ológun Nàíjíríà (Nigerian Army) lọ́dún 1958. Lẹ́yìn tó wọlé tán ló lọ sí àwọn ilé-ẹ̀kọ́ ológun lóríṣìíríṣìí láti kọ́ ìmọ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń jagun. Àwọn ilé-ẹ̀kọ́ tó lọ náà ni:

Mons Cadet School, Aldeshot, England.

Royal College of Millitary Engineers, Chatham, England.

School of Survey, Newbury, England.

College of Millitary Engineering, Poona.

Royal College of Defence Studies, London

 

ÀWỌN OGUN TÓ KÓPA NÍNÚ Ẹ̀:

Rògbòdìyàn orílẹ̀-èdè Congo: Ọ̀kan nínú àwọn ogun tó burú jùlọ lágbàáyé ni rògbòdìyàn tó ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Congo láàárín ọdún 1960 sí 1965. Nínú ìwádìí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀, èèyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún ẹgbẹ̀rún ló pàdánù ẹ̀mí wọn látara ogun yìí. Nínú àwọn ológun Nàìjíríà tó jà lórúkọ àjọ orílẹ̀-èdè àgbàyé (United Nations) lásìkò rògbòdìyàn yìí ni Ọbásanjọ́ wà.

Ogun Abẹ́lé Nàìjìríà: Ogun abẹ́lé Nàìjíríà tó wáyé láàárín ọdún 1967 si 1970. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ ogun yìí sí ogun Ojukwu, àwọn mi-in sì ń pè é ní ogun Biafra. Ọbásanjọ́ wà lára àwọn adarí ogun lásìkò ogun abẹ́lé yìí. Kódà, òun gan-an ló gba ìtúúbá àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Biafra fún Nàìjíríà lọ́jọ́ kejìlá, oṣù kìn-ín-ní ọdún 1970.


ỌBÁSANJỌ́ NÍNÚ ÌJỌBA OLÓGUN:

Ó fẹ́rẹ̀ má sí bí a ṣe fẹ́ẹ́ sọ̀rọ̀ ìjọba ológun Nàìjíríà tí a kò ní í dárúkọ Ọbásanjọ́ sí i. Nínú ìjọba ológun lorúkọ rẹ̀ tí túbọ̀ tàn sí i, níbẹ̀ náà ló ti di ọmọ Yorùbá àkọ́kọ́ tó di olóri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ṣùgbọ́n lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ kọ́ ló bẹ̀rẹ̀ o, òun náà bẹ̀rẹ̀ lábẹ́ àwọn aṣíwájú kan ni. Lásìkò ìjọba rẹ̀, Ọ̀gágun Yakub Gowon fi í ṣe kọmíṣánnà fún iṣẹ́ àti ilé gbígbé àwọn ọmọ Nàìjíríà.

Lọ́jọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù keje, ọdún 1975, àwọn kan nínú àwọn ọmọ ogún ìjọba Nàìjíríà kóra wọn jọ, wọ́n sì fìbọn gbàjọba lọ́wọ́ Ọ̀gágun Yakub Gowon. Àwọn ọmọ ogun tó fìbọn gbàjọba yìí yan Ọ̀gágún Murtala Mohammed gẹ́gẹ́ bíi olórí ìjọba tuntun, wọ́n sì yan Ọbásanjọ́ gẹ́gẹ́ bíi olórí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba pátápátá.

Nígbà tí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀gá ológun, Lt. Col. Bukar Suwa Dimka, gbìyànjú láti fìbọn gbàjọba lọ́wọ́ Murtala lọ́dún 1976, Ọbásanjọ́ wà lára àwọn olórí ológun tí wọ́n ní láti pa lẹ́yìn tí wọ́n pa Murtala Muhammed kí wọ́n tóó le gbàjọba. Ṣùgbọ́n wọn ò rí i pa. Òun nìkan sì kọ́ lorí kó yọ nínú ikú òjijì yìí, lára àwọn mì-ín tórí kó yọ lásìkò náà ni Ọ̀gágun Theopilus Yakubu Danjuma. Èyí ló mú kí ikọ̀ Dimka pàdánù ipò olórí ìjọba tí wọ́n ń wá.

Ọbásanjọ́ àti Danjuma gba àkóso ìjọba Muritala padà, àjọ Ìjọba Àpapọ̀ Ológun (Federal Millitary Council) sì yan Ọ̀gágun Ọbásanjọ́ gẹ́gẹ́ bíi olóri ìjọba tuntun.

Ó ṣèlérí láti tẹ̀lé ìlànà ìjọba Muritala Muhammed tó pinnu láti dá ìjọba padà fàwọn aráàlú, ìyẹn dẹ̀mókírésì, lọ́dún 1979. Èyí tó mú ṣẹ lọ́jọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹwàá, ọdún 1979. Shehu Shagari ni ààrẹ tó gbéjọba sílẹ̀ fún. Bẹ́ẹ̀ ló kọ̀wé fiṣẹ́ ológun sílẹ̀ lọ́jọ́ náà.

Ṣùgbọ́n Ọbásanjọ́ fiṣẹ́ sílẹ̀ ni o, Nàìjíríà kò fi í sílẹ̀. Ìgboyà láti sọ ohunkóhun tó bá ń dùn ún lọ́kàn báyòówù kó le tó sì tún sún un lọ sẹ́nu ikú.

Ọbásanjọ́ bẹnu àtẹ́ lu ìṣèjọba Ọ̀gágun Sani Abacha tó tẹ àwọn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú mọ́lẹ̀, èyí sì mú kí wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé ó fẹ́ẹ́ dìtẹ̀ gbàjọbà lọ́wọ́ Abacha ni. Ni wọ́n bá pe Ọbásanjọ́ lẹ́jọ́ ní kóòtù àwọn ológun, wọ́n sì dájọ́ ikú fún un níbẹ̀.

Ṣùgbọ́n ọjọ́ ikú tí wọ́n dá fún Ọbásanjọ́ ò tí ì pé tí Abacha pàápàá fi pa ipò dà. Oríṣìíríṣìí awuyewuye ló wà lórí ikú tó pa olórí ìjọba náà tórí bí iléeṣẹ́ ìjọba ṣe ń sọ pé ẹ̀jẹ̀ ríru ló pa á, bẹ́ẹ̀ ni àwọn oníwàádìí àti àwọn aṣojú orílẹ̀-ede kan ń ní bẹ́ẹ̀ kọ̀ lọ̀rọ̀ rí, ó ṣée ṣe kó jẹ́ májèlé ni wọ́n fún un jẹ. Olórí ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ pàápàá, Hamza al-Mustapha, gbàgbọ́ pé pípa ni wọ́n pa ọ̀gá òun. Àwọn ará Isrẹlí kan ló sì ń nàka sí pé wọ́n ṣiṣẹ́ ọ̀hún. Èyí tó mú kí ọ̀rọ̀ náà tiẹ̀ wáá dojú rú pátápátá ni pé lọ́jọ́ tó kú náà ni wọ́n sin ín láì ṣàyẹ̀wò òkú ẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi àṣà Mùsùlùmí, ẹnì kan kò lè sọ pàtó nǹkan tó pa á gan-an àfi ohun tí ìjọba bá sọ fáráayé.

ỌBÁSANJỌ́ NÍNÚ ÌJỌBA DẸ̀MÓKÍRÈSÌ

Lọ́dún 1999 tí Ọ̀gágun Abubakar Abdulsalam fẹ́ẹ́ gbéjọba sílẹ̀ fúnjọba alágbádá, Ọbásanjọ́ dìde láti dupò ààrẹ Nàìjíríà lorúkọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú People’s Democratic Party (PDP), òun sì ló gbégbá orókè nínú ìdìbò ọdún naa.

Ọbásanjọ́ sin Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bíi ààrẹ láti ọdún 1999 yìí títí dí ọdún 2007 tó fipò náà sílẹ̀ fún ààrẹ ìjẹta, Umaru Musa Yar’adua.

Ní báyìí, ilé ìkàwé àti oko rẹ̀, ìyẹn Olusegun Obasanjo Presidential Library àti Obasanjo Farms, ló  kù tó ń mójú tó. Bẹ́ẹ̀ ni kò sì yéé sọ̀rọ̀ nípa ìjọba bí wọ́n bá ń ṣìnà tàbí wọ́n ṣe ohun kan tó dáa fáráàlú. Ọ̀kan nínú àwọn àgbà tó kù tí a ní ní Nàìjíríà ni.

Post a Comment

0 Comments