Search This Blog

MIÒLÈWÁÁKÚ

Àbí yóó wù ọ́ láti gbọ́ àkọsílẹ̀ yìí dípò kíkà á? Tẹ ibí.



Ẹ kú déédé àkókò yìí ní gbogbo ibi tẹ́ ẹ ti ń ka àkọsílẹ̀ yìí. Ìtàn kékeré kan ni mo mà mú wá ságọ̀ọ́ yín. Ìtàn olówe ni, torí ẹ̀ ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ẹ́ kà á gbọdọ̀ jẹ́ olóye kó le yé yín dáadáa.

Láyé àtijọ́-tijọ́ nígbà tí ojú ṣì wà lórúnkún, bàbá ọlọ́lá kan bímọ méjì. Àkọ́bí ń jẹ́ “Ojú-mi-ò-ní-í-ríbi”, àbúro rẹ̀ sì ni wọ́n sọ ní “Mi-ò-lè-wáá-kú”. Nígbà tí bàbá yìí kú, ìfẹ́ tó wà láàárín àwọn ọmọ ẹ̀ ò jẹ́ kí wàhálà kankan wà lórí ogún bàbá wọn. Wọn ò wulẹ̀ pín ogún ọ̀hún, níṣe ni wọ́n pa gbogbo ẹ̀ pọ̀ tí wọ́n jọ ń ṣàkóso lórí ẹ̀ láì síjà kankan.
Kò pẹ́ kò jìnnà làwọn ọmọọ̀yá mẹ́ta kan dé, wọ́n láwọn fẹ́ẹ́ fipá gba ogún bàbá wọn lọ́wọ́ wọn. Àwọn ọmọọ̀yá mẹ́tẹ̀ẹ́tà yìí náà lórúkọ tiwọn. Àkọ́bí tó dàgbà jùlọ nínú wọn ni wọ́n ń pè ní Ikú, àbúrò tó tẹ̀lé e ń jẹ́ Ìnira, àbígbẹ̀yìn inú ẹbí wọn sì ni wọ́n sọ ní Ẹ̀rù.

Ohun tó wáá ya ni lẹ́nu jùlọ nínú ọ̀rọ̀ àwọn ọmọọ̀yá mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ni pé Ẹ̀rù tó kéré jùlọ nínú wọn gan-an ló ga jùlọ. Òun nìkan sì ló pé léèyàn. Ẹ̀rù ga níwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà méje àtààbọ̀, bó ṣe ga yìí náà ló ṣe síngbọnlẹ̀. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú bí Ẹ̀rù ṣe ga tó yìí, kò mọ ìjà ẹyọ̀ kan ṣoṣo jà, ariwo lásán ló mọ̀ ọ́n pa. Ẹ̀gbọ́n ẹ̀, Ìnira, tí ò ga tó o ló mọ̀jà í jà.
Ìnira tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ò ga ju ìwọn ẹsẹ̀ bàtà márùn-ún àtààbọ̀ lọ. Èèyàn násán-násán kan báyìí ni. Ẹni téèyàn le fojú di ni. Lóòótọ́ ló le na ẹnikẹ́ni lulẹ̀ báyòówù kónítọ̀hún tóbi tó o, ṣùgbọ́n kinní kan ba àjào rẹ̀ jẹ́ – afọ́jú ni kò ríran. Ẹ̀rù ní í máa sọ fún un ibi tí olódì rẹ̀ wà.

Nínú àwọn ọmọọ̀yá mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tá a wáá kà sílẹ̀ yìí, kò séyìí tó lọ́kàn láti pààyàn àfi Ikú tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n wọn àgbà. Òun nìkan ló dájú láàárín wọn, kò sì síbi tí yóó lọ tí kò ní í mú ọ̀bẹ alápatà kan báyìí dání. Ṣùgbọ́n aràrá ni Ikú, kò ga ju ìwọn ẹsẹ̀ bàtà mẹ́ta lọ. Béèyàn bá wáá rí Ikú, yóó lérò pé ó kúrú jù bẹ́ẹ̀ lọ ni torí ó yarọ kò léè dìde. Àyà ló fi ń fà bíi ejò.

Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ni wọ́n wáá kan ilẹ̀kùn Ojúmiònííríbi àti Miòlèwáákú, wọ́n láwọn fẹ́ẹ́ gba ogún bàbá wọn lọ́wọ́ wọn. Fìrìgbọ̀n Ẹ̀rù tóó ba ẹnikẹ́ni lẹ́rù, kò sẹ́ni tí yóó mọ̀ pé kò le jà.

Ṣùgbọ́n inú tó ń bí Ojúmiònííríbi ò jẹ́ kó ronú dáadáa tó fi fò dìde. Ó ní, “Ká kú lọ́mọdé kó yẹni, ó sàn ju ká dàgbà láì ládìyẹ ìrànà, ojú tèmi ò ní í ríbi!” Bí Ẹ̀rù ṣe gbóhun Ojúmiònííríbi, ó tàdí mẹ́yìn. Ojúmiònííríbi ṣàkíèsí, òun ló sì kọ́kọ́ wọ́ mọ́ra.

Ìgbájú-Ìgbámú tí Ojúmiònííríbi kó bò Ẹ̀rù ó jẹ́ kó rójú ṣàlàyé ibi tó wà fún Ìnira. Ìnira káwọ́ méjèèjì sókè, ó ń ní, “Ta ló ń lu ta ni?” “Níbo lọkùnrin tó ń gbó wa lẹ́nu wà?”
Ojúmiònííríbi ń pariwo sọ fún àbúrò rẹ̀, “Miòlèwáákú, tẹ Ikú lójú mọ́lẹ̀! Tẹ Ikú lójú mọ́lẹ̀, Miòlèwáákú!”

Ṣùgbọ́n sòró ti de Miòlèwáákú, ọ̀bẹ ọwọ́ Ikú ló tẹjú mọ́ tí kò fi lè kúrò lójú kan.
Ibi ìjà ni Ikú kọjú sí ní tiẹ̀. Ó ń sọ fún Ìnira, “Kọjú sápá ọ̀tún, rìn síwájú díẹ̀. Tún kọjú sápá ọ̀tún, ọwọ́ rẹ ti fẹ́ẹ́ tó o. Tún rìn síwájú díẹ̀, óyá nawọ́-nawọ́! Ó ti wà lárọ́wọ́tó rẹ̀!”
Ojú kan níbẹ̀ ni Miòlèwáákú wà tí ọwọ́ Ìnira fi tó Ojúmiònííríbi. Ìnira gbé Ojúmiònííríbi, ó nà án mọ́lẹ̀ wàà! Ó tún gbé e lẹ́ẹ̀kejì, ó nà án mọ́lẹ̀ wàà! Ojúmiònííríbi kígbe bíi ọmọdé, ìrora tó ń faradà pọ̀ ju ẹ̀mí ẹ̀ lọ.
Ẹ̀rù wáá dì í lórí mú, Ìnira di ọwọ́ ẹ̀ méjèèjì mú títí tí Ikú fi fàyà fà lọọ dúnbú ẹ̀ bíi ìgbà tééyàn bá ń dúúbú ẹran.

Miòlèwáákú wo òkú ẹ̀gbọ́n ẹ̀ nílẹ̀, ó sì bú sígbe. Ẹ̀rù dìde nílẹ̀ wìrì ó kígbe mọ́ ọn, “Nu ojú rẹ nù! Pá ẹnu rẹ mọ́!” Miòlèwáákú súré nu ojú nù, ó sì dákẹ́ páfe.

Ẹ̀rù ò fẹ́ kó rántí ọjọ́ òní bíi ọjọ́ ìjà, tórí bó bá wò ó bẹ́ẹ̀ yóó rántí pé òun tàdí mẹ́yìn nígbà tí Ojúmiònííríbi dìde. Ẹ̀rù wáá bẹ̀rẹ̀ si í peṣẹ́ bíi akọni tí òun kì í ṣe. 
Ó rìn tìgbéraga-tìgbéraga lọọ bá Miòlèwáákú, ó ní, “Kúnlẹ̀! Kí o sì da àtẹ́lẹwọ́ rẹ méjèèjì délẹ̀! Títí dọjọ́ ikú rẹ o kò gbọdọ̀ ṣíjú ọwọ́ náà sókè! Gbogbo ohun tí mo bá ti ń wí látòní lọ, máa wípe ‘Bẹ́ẹ̀! Bẹ́ẹ̀! Bẹ́ẹ̀ ni!’ O gbọ́ àbó ò dáhùn!”
Miòlèwáákú ní “Bẹ́ẹ̀-Bẹ́ẹ̀-Bẹ́ẹ̀ ni!”

“Ní báyìí, gbé òkú alátakò yìí. Yan án kí o jẹ ẹ́, kí o sì lọọ ri egungun rẹ̀ mọ́bi tó ó máa jí lọ láràárọ̀!” Ẹ̀rù ló ń pàṣẹ bẹ́ẹ̀ o. Miòlèwáákú dáhùn, ó ní, “Bẹ́ẹ̀-Bẹ́ẹ̀-Bẹ́ẹ̀ ni!”
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò dùn mọ́ Miòlèwáákú nínú. Ó wù ú láti ṣọ̀fọ̀ ẹ̀gbọ́n ẹ̀, ṣùgbọ́n kò sóhun mì-ín tó le ṣe àfi ohun tí àwọn olúwa rẹ̀ bá sọ fún un.

Miòlèwáákú ṣe òkú ẹ̀gbọn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe pàṣẹ fún un, láràárọ̀ ló sì gbọdọ̀ máa lọ síbẹ̀ kó le rántí ohun tí í ṣẹlẹ̀ sẹ́ni tó bá gbó Ẹ̀rù àti àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lẹ́nu lórí bóhun ṣe fẹ́ẹ́ gbé ayé òun.

Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, Miòlèwáákú fẹ́yàwó, ó sì bímọ. Ó sọ ọmọ rẹ̀ ní Ojúmiònííríbi níràntí ẹ̀gbọ̀n rẹ̀. Ojúmiònííríbi gbọ́njú bá bàbá ẹ̀ lórí ìrákòrò ni, torí ẹ̀ kò kà á sí nǹkan kan láti máa rákò kiri bíi bàbá ẹ̀. Ojoojúmọ́ ló sì ń tẹ̀lé e lọ sójú oórì Ojúmiònííríbi àkọ́kọ́ tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n bàbá ẹ̀.

Lọ́jọ́ kan ni Ojúmiònííríbi béèrè lọ́wọ́ bàbá ẹ̀ pé kí ló wà nínú ilẹ̀ ibi tí àwọ́n máa ń rá lọ lójoojúmọ́. Tẹkún-tẹkún ni bàbá ẹ̀ fi sọ ìtàn Ojúmiònííríbi àkọ́kọ́ fún un àti ohun tó fà á táwọn fi ń rá kiri bíi ẹran.

Kín ni Ojúmiònííríbi kejì gbọ́ ìtàn yìí sí ni, wàhálà mì-ín tún bẹ̀rè. Ó lóun óó wá gbogbo ọ̀nà láti nàró dìde bíi èèyàn, òun óó sì fa bàbá òun náà dìde kó le nàró bíi èèyàn. Bàbá rẹ̀ bẹ̀ ẹ́ títí kò dáhùn, ọmọ yìí ò gbọ́rọ̀ sí bàbá ẹ̀ lẹ́nu.

Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan tó ti ń gbìyànjú láì sinmi, Ojúmiònííríbi kékeré fi ẹsẹ̀ méjèèjì lélẹ̀, kò sì nílò láti rákò kò tóó le dé ibikíbi tó bá fẹ́ẹ́ lọ.

Lọ́jọ́ tó dìde yìí náà ni Ẹ̀rù àti àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ méjèèjì tún dé láti wáá fòfin wọn múlẹ̀. Ká má fọ̀rọ̀ gùn, ìjà ọ̀hún dà bíi ìjà wọn pẹ̀lú Ojúmiònííríbi àkọ́kọ́ ni. Ìyàtọ̀ ibẹ̀ kàn ni pé tẹkún-tẹkún ni Miòlèwáákú fi ń pariwo, “Bẹ́ẹ̀-Bẹ́ẹ̀-Bẹ́ẹ̀!” títí tí wọ́n fi pa ọmọ rẹ̀ lójú ẹ̀.

Bí Ẹ̀rù ṣe pàṣẹ pé kò ṣe ẹ̀gbọ́n rẹ̀ náà ló ní kó ṣe ọmọ rẹ̀. Ó wáá pàṣẹ pé ọmọ yòówú tó bá bí lẹ́yìn èyí, kò gbọdọ̀ sọ ọ́ ní Ojúmiònííríbi, Miòlèwáákú tó jẹ́ orúkọ ẹ̀ ni kó máa sọ àwọn ọmọ náà.

Mìòlèwáákú ò sọ nǹkan mì-ín ju, “Bẹ́ẹ̀-Bẹ́ẹ̀-Bẹ́ẹ̀” lọ bó ṣe ń tẹ̀lé àṣẹ Ẹ̀rù.
Kò pẹ́ kò jìnnà, ó bímọ mì-ín lóòótọ́, ó sì sọ ọ́ ní Miòlèwáákú. Òun àti Miòlèwáákú kékeré yìí ni wọ́n jọ ń rá lọ síbi tí wọ́n ri eegun àwọn Ojúmionííríbi sí.

Lọ́jọ́ kan ni Mìòlèwáákú kékeré bèèrè lọ́wọ́ bàbá ẹ̀ pé kí ló wà níbi táwọn ń wá yìí, àti pé kín nìdìí táwọn ṣe gbọdọ̀ máa wá síbẹ̀ láràárọ̀? Miòlèwáákú àgbà ò fẹ́ẹ́ sọ gbogbo ìtàn fún un kó má di pé òun náà yóó máa pariwo pé òun fẹ́ẹ́ dìde. Ó kàn sọ fún un pé “Ibi tí a máa ń ri eegun ọmọ agboolé wa tó bá dìde rìn bíi èèyàn mọ́lẹ̀ sí rèé.”

Miòlèwáákú kékeré bèèrè lọ́wọ́ bàbá ẹ̀ pé “Ṣé a lè dìde fẹsẹ̀ méjì nìkan rìn bíi èèyàn ni?” Miòlèwáákú àgbà dáhun pé “Bẹ́ẹ̀ ni, ṣùgbọ́n lọ́jọ́ tá a bá dìde nàró bíi èèyàn la óó kú o!”

Miòlèwáákú ò wulẹ̀ sọ fún bàbá ẹ̀ bóyá òun yóó dìde tàbí òun kò ní í dìde. Ní kọ̀rọ̀ ibì kan ló ti ń gbìnyànjú àti dìde, kóun le ga débi tí púpọ̀ nínú àwọn ọmọ agboolé wọn kò ga dé.

Kẹ̀rẹ̀ kẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan, Miòlèwáákú kékeré dìde nàró bíi èèyàn. Ọjọ́ tó nàró bíi èèyàn náà ni Ẹ̀rù àti àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tún dé, bí wọ́n ṣe pa àwọn Ojúmiònííríbi náà ni wọ́n ṣe pa Miòlèwáákú kékeré lójú bàbá ẹ̀. Bàbá ẹ̀ ò sì lè ṣe nǹkan kan ju bó ṣe ń pariwo “Bẹ́ẹ̀-Bẹ́ẹ̀-Bẹ́ẹ̀!” tẹkún-tẹkún lọ.
Ní kúkúrú, ọmọ méje ni Miòlèwáákú bí tó jẹ́ pé lójú ẹ̀mí ẹ̀ ni Ikú pa gbogbo wọn. Ẹ̀ṣẹ̀ kan náà ni gbogbo wọn ṣẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdí tí oníkálukú wọn fi ṣe é yàtọ̀ síra wọn. Òmíràn dìde nítorí àwọn babańlá rẹ̀ ti dìde rí, òmí-ìn nínú wọn sì dìde nítorí ó fẹ́ẹ́ dé ibi téèyàn kì í sáábà dé nínú ìran wọn.

Nígbà tó yá ni Miòlèwáákú kúkú dà á ságídí, ó lóun ò ní í bímọ mọ́ nígbà tó jẹ́ pé gbogbo ọmọ tó ń bí, bó tilẹ̀ sọ wọ́n ní Miòlèwáákú, ìwà Ojúmiònííríbi ni gbogbo wọn ń wù tó sì ń ṣokùnfà ikú wọn.

Lẹ́yìn ọdún gbọọrọ, Ẹ̀rù kú, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ Ìnira tẹ̀lé e, Ikú pàápàá fò ṣánlẹ̀ ó gbọ̀run lọ, kò sẹ́ni tó le fipá mú Miòlèwáákú pé kó máa rákò kiri bíi ẹran tàbí pé kò gbọdọ̀ fèsì sọ́rọ̀ gbogbo ju “Bẹ́ẹ̀-Bẹ́ẹ̀-Bẹ́ẹ̀ ni!” lọ. Lọmọ aráayé bá sáré lọọ bá Miòlèwáákú, wọ́n sọ fún un pé kó dìde bíi èèyàn tórí èèyàn làwọn babańlá rẹ̀. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ yìí ti di bárakú fún Miòlèwáákú o. Ẹ̀yìn ti gan kò le dìde bíi èèyàn mọ́, ọpọlọ ti jọ́bà débii pé ó ṣòro fún un láti ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀rọ̀ tí ẹnikẹ́ni bá fi lọ̀ ọ́. Èsì kan ṣoṣo tí gbogbo ayé máa ń gbọ́ lẹ́nu rẹ̀ kò ju “Bẹ́ẹ̀-Bẹ́ẹ̀-Bẹ́ẹ̀ ni!”
Báwọn aráayé bá ti ń sọ fún un pé èèyàn làwọn babańlá rẹ̀, kó ṣe bíi wọn – yóó ní, “Sé bẹ́ẹ̀-bẹ́ẹ̀-bẹ́ẹ̀ ni? Èmi ò mọ nǹkan mì-ín sọ ju bẹ́ẹ̀-bẹ́ẹ̀-bẹ́ẹ̀ ni lọ!”

Ọmọ aráayé ò wáá mọ ohun tí wọ́n le ṣe sọ́rọ Miòlèwáákú, kì í ṣe ewúrẹ́ tí wọn ò bá pa kí wọ́n fi dálá, gbogbo ìwa àti ìṣesí ẹ̀ kàn jọ tewúrẹ́ ni. Kì í ṣèèyàn tí wọn ò bá pè síjìíròrò ọ̀jọ̀gbọ́n pé kóun náà sọ ojú tó fi wo ọ̀rọ̀. Ó kàn fojú jọ̀ọ̀yàn ni, gbogbo ìṣesí ẹ̀ ò yàtọ̀ sí tẹranko.

Títí dòní àárọ̀ yìí, Miòlèwáákú ṣì wà láyé o – tó ń ṣe “Bẹ́ẹ̀-bẹ́ẹ̀-bẹ́ẹ̀ ni” fún gbogbo ayé. Kò jéèyàn – kò jẹ́ranko – kò jẹ́ nǹkan kan.
Ìtàn àwọn ọmọ bàbá ọlọ́lá méjèèjì yìí ba’ni nínú jẹ́ gidigidi. Ó rọrùn láti dá wọn lẹ́bi tàbí dá wọn láre fún ohun tí wọ́n ṣe tàbí tí wọn ò ṣe. Ṣùgbọ́n bó bá jẹ́ ìwọ̀ l’Ẹ̀rù dúró níwájú rẹ tó ní kó o má kówó lórí òwò dáadáa kan nítorí irú ẹ kọ́ lèèyàn tí i ṣòwò tí í ṣàṣeyọrí; tàbí tó ní kó o jòkòó mọ́lẹ̀ nínú kíláásì, o kò gbọdọ̀ bèèrè ohun tí kò yé ọ lọ́wọ́ olùkọ̀ọ́ nítorí àwọn akẹgbẹ́ rẹ óó fi ọ́ ṣẹ̀fẹ̀; tàbí tó ní kó o déjú mọ́lé, kò sẹ́ni tí yóó tì ọ́ lẹ́yìn láti di ààrẹ orílẹ̀-èdè yìí nítorí pé o jóbìnrin, ǹjẹ́ o le gbóyà láti já Ẹ̀rù láyà pé kò láṣẹ láti pàṣẹ pé bákan ni kó o ṣe gbélé ayé rẹ?

Àbí o lérò pé kò lè ṣẹlẹ̀? Gbé ọwọ́ ọ̀tún lé oókan àyà rẹ, o ò gbọ́? Ẹ̀rù ló ń kànkùn un. Kí lo ó ṣe.

Fún Olúfẹlá Aníkúlápó Kútì. Fear, not for man.

Post a Comment

0 Comments