Search This Blog

LẸ́TÀ SÍ MÀÁMI

Would you like to read this article in English? Click here
Àbí yóó wù ọ́ láti gbọ́ àkọsílẹ̀ yìí dípò kíkà á? Tẹ ibí

Agbe tí í gbére pàdé Olókun
Má gbére pàdé olókun láàrọ̀ yìí, mo fẹ́ẹ́ rán ọ sí màámi
Màámi Àtètèjí, ọmọ Onílé-Ariwo
Ní mò ń béèrè pé bó ó làwọn ará òkè ọ̀hún.
Ṣé tẹ̀rín-tẹ̀yẹ ni wọ́n fi gbà wọ́n lálejò
Àbí oníkálukú rojú kókó bíi ẹni pé ọ̀rọ̀ àjèjì tó dé ò kan ẹnì kan.
Ṣé ọkọ̀ inira tó wà á débùúté òkè ọ̀hún dẹ̀yìn
Àb’ó dàgbámùréré tó ń yí gbiri tẹ̀lé e lókè aláìlẹ́nìkan
Bèèrè pé ṣé ará ọ̀run ń rí aráayé
Àbí inú òkùnkùn ilẹ̀ tá a sin wọ́n sí náà ni wọn óó wà títí ayérayé.
Bèèrè pé ṣé ẹ̀mí ń pínyà pẹ̀lú ara kó tóó jẹrà
Àbí méjéèjì ń so papọ̀ nínú òkùnkùn sààréè, kẹ́nu tó ń jẹran-jeegun le dẹran fẹ́ran tí ò léegun?
Àìnídàhún sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí ń kọ mí lóminu.
Ó sì ń dá ọgbẹ́ gidi sí ìsàlẹ̀ ọkàn mi.

Àlùkò tí í gbére pàdé Ọlọ́sà
Má gbére pàdé Ọlọ́sà láàrọ̀ yìí, mo fẹ́ẹ́ rán sí màámi.
Màámi Àtètèjí, ọmọ Onílé-Ariwo
Màámi Àtètèjí tí í korí bòjò roko ọba.
Àtètèjí tí í fẹ̀rín gbàwìn kọ́mọ le kàwé dé kémbírííjì
Ṣàlàyé pé látìgbà téégún ti fẹ̀yìn jó wọ̀gbàlẹ̀ ni nǹkan ò ti rọgbọ
Mo ṣẹrú kí n le bọ́ba tan.
Mo dìwọ̀fà kí n le rìn níbi àwọn ẹgbẹ́ mi ń fẹ̀sọ̀ rìn.
Mo bá wọn gbàárù lọ́jà Àkẹ̀sán kí n le dúró sọ níwájú àwọn Akọ̀wé pé èmi náà jẹ́ nǹkan.
Mo wẹ̀yìn wo ọ̀pọ̀ èrò tó ń ṣèlérí lọ́jọ́ ìsìnkú.
Tí wọ́n ń ní ọmọkùnrin yìí dákàn ró àwà ṣetán láti mú ọ bíi ọmọ
Mo wo sààkun ayé lọ mo bèèrè lọ́wọ́ àwọn abánidárò
Mo ní bẹ́mì-ín mi bá wà nínú ìdè, tí tọmọ yín náà wà níbẹ̀
Tẹ́ ò sí láǹfàaní àti mú ju èèyàn kan kúrò nínú àpamọ́ ewu.
Ẹ̀mí ta lẹ ó fi ṣètùtù fẹ́nì kan?
Gbogbo wọn pòṣé ṣààrà!
Wọ́n lọ́gbọ́n àgbọ́njù ti fẹ́ẹ́ ya ọmọdé yìí ní wèrè.
Ṣùgbọ́n màámi ò ní í pè mí láṣiwèrè láéláé.
Tẹ̀rín-tẹ̀yẹ ni óó fi máa pé “O káre laé, ọmọdé yìí. Ẹnì kan ò ṣeé finú tán!”
Lọ́jọ́ ọ̀hún ni mo ti mọ̀ pé mo pàdánu ẹnì kan tó le fẹ̀mí ẹ̀ lélẹ̀ fún mi kódà bí n ò jẹ́ nǹkan kan.
Ṣé mo wáá le dá wọn lẹ́bi pé wọ́n ṣe fẹ́ràn ọmọ wọn jù mí lọ?
Pẹ̀lú ìwúrí ni mo le fi sọ ọ́ níbikíbi pé ìyá mi ò fẹ́ran ẹnì kan jù mí lọ.
Oníkálukú ń pàdà lọ́ ilé lọọ bá ọmọ wọ̀n
 Ṣùgbọ́n ẹni tó ń bọ̀ wáá bá èmi ò ní í le padà wálé mọ́ títí láéláé.

Àlùkò tí í gbére pàdé Ọlọ́sà
Ṣàlàyé pé tọ̀sán-àn-tòru ni mo fi ń roko tó fi sílẹ̀ fún mi.
Ìyà tí mo ń jẹ lóko àdáro ọ̀hún ò tiẹ̀ wáá dùn mí
Bíi ìbànújẹ́ pé ẹni tó foko yìí lọ́lẹ̀ ò ní í le réso ẹ̀ jẹ.

Lèkélèké tí í kóre relé Ìkẹ́fun.
O ò ní í lè lọ sílé Ìkẹ́fun lónì-ín torí mo fẹ́ẹ́ rán ọ sí màámi.
Màámi Àtètèjí, ọmọ Onílé-Ariwo.
Bèèrè lọ́wọ́ ọlọ́kọ̀ mi pé ṣé ó ń ṣàfẹ́ẹ́rí mi.
Torí lójoojúmọ́ lèmí ń ṣàfẹ́ẹ́rí rẹ̀.
Lójoojúmọ́ ni mò ń jowú ẹni tó gbọ́ ìpè ìyá tó ń ṣakọ pé ó láwòómọ́.
Gbogbo ìgbà ni mò ń dákẹ́ ìṣẹ́jú díẹ̀, bí mo bá rí ìyá àtọmọ tí wọ́n ń fa ara wọn lọ lójúde.
Torí èmí mọ̀ pé n ò le rírú ẹ̀ mọ́ láéláé.
Bẹ́ẹ̀ ìgbà tí mò ń rí i, ó mà ṣé o, n ò mọyì.
Ǹ bá mọ̀ kí n ti dọwọ́ ìyá mú—
Kóoru àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ ó má le kúrò lọ́kàn mi títí ayé.

Odídẹrẹ́ ẹyẹ Ìwó
Ọ̀nà rẹ ò gbodò Ọbà láàrọ̀ yìí.
Torí mo fẹ́ẹ́ rán ọ sí màámi.
Màámi Àtètèjí, ọmọ Onílé-Ariwo.
Jíṣẹ́ lọ́hùn-ún pé n ò gbàgbé.
N ò gbàgbé ọjọ́ tó debi sùn kémi le róúnjẹ gidi jẹ.
N ò gbàgbé ọjọ́ tó fi ọgbọ́n àgbà tàn mí
Kí n le fi gbogbo ara dunnú nígbà tí inú tiẹ̀ ń bàjẹ́ gidi.

Odídẹrẹ́ ẹyẹ Ìwó.
N ò gbàgbé ọjọ́ tí mo ṣèlérí pé n ó gbé yèyé mi rèlú Ọba.
N ò gbàgbé bó ṣe gbà mí gbọ́ kódà nígbà tó mọ̀ pé n ò ní kọ́bọ̀ kan.
N ò gbàgbé bí mo ṣe ṣèlérí pé obìnrin ayé kan ò ní í rí i kó má jowú inú ayọ̀ tí mo máa fi í sí.
N ò gbàgbé, torí n ò le mú ìlérí mi ṣẹ.
Òun náà ni ò sì jẹ́ kóhunkóhun le jẹ́ nǹkan kan mọ́.
Odò agbedeméjì ti kún.
Ará ọ̀hún ò sì leè gbóhùn aráabí.
Ohun tó ń mú mi kégbe tantan rèé.
Bóyá ẹyẹ oko ó le gbóhùn mi ròkun.

Agbe tí í gbére pàdé Olókun.
Má gbére pàdé Olókun láàrọ̀ yìí.
Mo fẹ́ẹ́ rán ọ sí màámi.
Màámi Àtètèjí, ọmọ Onílé-Ariwo.

Post a Comment

0 Comments