Search This Blog

Nigeria: Ilé tá a fẹ́ẹ́ wó láì tí ì kọ́

Àbí yóó wù ọ́ láti gbọ́ àkọsílẹ̀ yìí dípò kíkà á? Tẹ ibí.
Nínú orúkọ àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé, ọ̀kan nínú wọn ni Nàìjíríà wà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnì kan kò lè sọ pàtó iye èèyàn tó wà nínú orílẹ̀-èdè yìí, àwọn oníwàdìí ìjìnlẹ̀ fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé èèyàn inú Nàìjíríà ń lọ bíi òkòólúgbadínméjì mílíọ̀nù (218 Million). Èyí ló sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè keje nínú gbogbo orílẹ̀-èdè térò pọ̀ sí jùlọ lágbàáyé, òun yìí kan náà sì ni orílẹ̀-èdè tí èèyàn dúdú pọ̀ sí jùlọ lágbàáyé. Bí a bá pe Nàìjíríà ní olú-ilẹ̀ adúláwọ̀, a ò jayò pa pẹ̀lú èrò èèyàn dúdú tó kún inú ẹ̀ yìí. Àwọn olóyìnbó pàápàá a máa sọ ọ́ pé bí o bá kan èèyàn dúdú márùn-ún, ṣèèṣì ni bí ọ̀kan nínú wọn ò bá jẹ́ ọmọ Nàìjíríà. Orílẹ̀-èdè olómìnira tó lérò tó sì ní ètò ìṣèjọba tirẹ̀ ni. Bí èèyàn bá wáá tún àkọ́lé àkọsílẹ̀ yìí wò pẹ̀lú ohun tá a sọ ṣáájú yìí, yóó máa bèèrè lọ́wọ́ ara rẹ̀ pé kín nìtumọ̀ ilé tá a fẹ́ẹ́ wó láì tí ì kọ́?

Bẹ́ẹ̀ ni, ó tó kó dàrú mọ́-ọ̀n-yàn lójú. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí mo bá wí tẹnu mi tán nínú àkọsílẹ yìí, a óó jọ ṣàgbéyẹ̀wò ẹ̀ bóyá ọ̀rọ̀ wèrè ni tàbí ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n.


Nínú ohun tí à ń pè ní Nàìjíríà lónì-ín, oríṣìíríṣìí ẹ̀yà ló kóra jọ sínú ẹ̀. Mẹ́ta nínú àwọn ẹ̀yà tó tóbi jùlọ ni n óó ṣàgbéyẹ̀wò rẹ̀ fún àkọsílẹ̀ yìí torí àkókò. Ẹ̀yà àkọ́kọ́ tí a óó yẹ̀wò ni ẹ̀yà Hausa tó wà lápá Àríwá Nàìjíríà. Ṣáájú kí òyìnbó amúnisìn tóó dé làwọn ti ń jẹ Emir láàárín ara wọn. Ọwọ́ Emir yìí ni gbogbo ètò ìṣàkóso ìlú wà, fúnra rẹ̀ ni yóó yan àwọn ìjòyè tí yóó máa gbà á nímọ̀ràn lórí ohun gbogbo tó bá fẹ́ẹ́ ṣe. Kò pọn dandan kó gbọ́rọ̀ sí àwọn olóyè wọ̀nyí lẹ́nu, kódà, àwọn pàápàá ni wọ́n gbọ́dọ̀ gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu. Bí àwọn ìjòyè yìí ṣe wáá wà lábẹ́ Emir ni àwọn aráàlú náà ṣe wà lábẹ́ ìjòyè. Aráàlú kan kò jẹ́ rí wọn fín. Ohun tí àwọn ìjòyè yìí bá sọ fún aráàlú ni wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe, ohun tí Emir bá sì sọ fún àwọn ìjòyè ni wọ́n gbọ́dọ̀ tẹ̀lé. Emir ò wáá lẹ́lòmí-ìn tó gbọ́dọ̀ gbọ́rọ̀ sí lẹ́nu àfi Ọ̀lọ́run ọba tó dá a sípò Emir.

Ní apá àtiyọ òòrùn Gúúsù ni ẹ̀yà Ígbò, ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà mẹ́ta tó tóbi jùlọ ní Nàìjíríà, wà. Kóyìnbó amúnisìn tóó dé ọ̀dọ̀ wọn, púpọ̀ nínú wọn ni kì í ní aṣáájú kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìlú Igbo mì-ín a máa ní olórí tí wọ́n ń pè ní Eze, ọwọ́ àwọn ìgbìmọ̀ ìjòyè Ọfọ́ àti Ọzọ́ ni ètò ìṣèjọba wọn máa ń wà. Olórí agboolé kọ̀ọ̀kan ni yóó wà nínú ìgbìmọ̀ Ọfọ́, gbogbo ẹni tó bá sì ṣiṣẹ́ sọ ara rẹ̀ di nǹkan pàtàkì láwùjọ ni wọ́n máa ń fi oyè Ọzọ́ dá lọ́lá. Ìgbìmọ̀ méjèèjì yìí ni wọ́n jọ ń darí ìlú bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn pàápàá ní àwọn ìgbìmọ̀ mí-ìn lábẹ́ tó fààyè gba gbogbo ọmọ ìlú láti dá sí ètò ìṣèjọba. Ohunkóhun tí wọ́n bá jọ fẹnu kò sí nípàdé wọn ni ìlú yóó ṣe. Àwọn fúnra wọn pàápàá nàá sì ni ìlú. Ohun tí èyí ń túmọ̀ sí ni pé nílẹ̀ Hausa, ètò ìṣèjọba wọn kó gbogbo agbara ìṣèjọba sọ́wọ́ Emir. Lọ́dọ̀ àwọn Igbo lọ́hùn-ún, ètò ìṣejọba wọn kó gbogbo agbára ìṣèjọba sọ́wọ́ aráàlú.


Láàárín àwọn Yorùbá tó wà lápá átiwọ òòrun Gúúsù Nàìjíríà, ètò ìṣèjọba tiwọn yàtọ̀ gedegbe sí ti àwọn méjì tá a kà ṣáájú tàbí ká sọ pé ó fẹ́ẹ́ fara pẹ́ tàwọn ẹ̀yà méjééjì tá a ti kà ṣáájú. Ètò ìṣejọba Yorùbá máa ń ni ẹnì kan lókè réré tí wọn yóó máa pè lọ́ba tàbí baálẹ̀. Ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo àṣẹ ìlú yóó wà, kò sì le sọ̀rọ̀ kan kẹ́nìkan ní kó kó o jẹ. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí òun pàápàá ṣe jẹ́ aláṣẹ lórí ìlú làwọn ìjòye kan jẹ́ aláṣẹ lóri òun gan-an alára. Àṣẹ kan ṣoṣo náa ni wọ́n sì le pa lé e lórí, àṣẹ pé kó lọọ ṣígbá wò bó ba fi di pé ètò ìṣèjọba rẹ̀ ń ni aráàlú lára. À ń ṣígbá wò ò sì túmọ̀ sí nǹkan mì-ín ju pé kó fayé sílẹ̀ kó gbọ̀run lọ. Ọba tó bá wáá gbọ́n tó fẹ́ẹ́ pẹ́ lórí oyè yóó máa gbàmọ̀ràn lọ́wọ́ àwọn ìjòyè tó ń ṣojú ìlú yìí ṣáájú kó tóó pàṣẹ máyẹhùn rẹ̀ fún wọn. Wọ́n óó máa tì í sígbó pé “tọba làṣẹ”, òun fúnra rẹ̀ óó sì máa tira rẹ̀ sọ́nà pé “ọwọ́ yín layé wà.”

Bí àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ṣe ní ètò ìṣèjọba tó yàtọ̀ síra wọn náà ni àwọn ẹ̀ya Ijaw, Tiv, Nupe, Calabar, Urhobo, Esan, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ṣe ní èdè, àṣà àti ètò ìṣèjọba tí ò jọra wọn. Gbogbo àwọn ẹ̀yà oríṣìíríṣìí yìí ni òyìnbó tí wọ́n ń pè ní Lord Lugard kó jọ sínú orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo tó pè ní Nàìjíríà. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ orílẹ̀-èdè ni Nàìjíríà bí?

Ẹ jẹ́ ká jọ ṣàgbéyẹ̀wò ẹ̀. Ọ̀rọ̀ méjì ló kóra jọ sínú “orílẹ̀-èdè”. Àkọ́kọ́ ni “Orílẹ̀” èyí tó túmọ̀ sí orírun, orísun, ilé, tàbí ìbẹ̀rẹ̀ nǹkan kan. Ìkejì sì ni “Èdè”, èyí tó túmọ̀ sí àkójọpọ̀ ẹ̀yà ọ̀rọ̀ tó jẹ́ àjọmọ̀ láàárín àwọn èèyàn tó ń gbé nínú ìlú kan tàbí jẹ́ ọmọ ẹ̀yà kan. Bí a bá wáá fẹ́ẹ́ fi ìtumọ̀ méjèèjì yìí wá ìtumọ orílẹ̀-èdè, a lè pe orílẹ̀-èdè ní ilẹ̀ ibì kan tó dúró gẹ́gẹ́ bíi orírun èdè tí a lè fi ṣe àmi ìdánimọ̀ àti ìyàsọ́tọ̀ irúfẹ́ ẹ̀ya èèyan kan. Ǹjẹ́ bí a bá bèèrè pé kín ni èdè Nàìjíríà, irú ìdáhùn wo ni yóó ti ẹnu ọmọ Nàìjíríà jáde? Kò jẹ́ jẹ́ pé ẹ fẹ́ẹ́ dáhùn pé English, torí gbogbo wa la mọ orírun èdè yìí, a sì mọ àwọn tó ni ín. Europe la lè pè ní orírun English lónì-ín. Àwọn Ingvaeones ló ni èdè English, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tó sì ń ṣàṣeyọrí nípa fífi èdè yìí ṣàkóso ara wọn ti ara ìran yìí wá ni tàbí kí wọ́n ní ìbátan tó jinlẹ̀ pẹ̀lú wọn.


Bó bá sì jẹ́ èdè Yorùbá lẹ fẹ́ẹ́ pè ní èdè Nàìjíríà, ìbéèrè kan ṣoṣo ni mo ní fún yín kí n tóó le gba ìdáhùn yín wọlé – “Ǹjẹ́ gbogbo ọmọ Nàìjíríà le sọ pé èdè àwọn ni Yorùbá?” Rárá o, àwọn kan wà tí wọ́n ń jẹ́ Yorùbá, wọ́n ní ilẹ̀ tiwọn, wọ́n ní ìtan, àṣà, àti ìṣe tiwọn tó yàtọ̀ sí ti gbogbo ẹ̀yà ènìyàn tó kù lágbàáyé. Àwọn elédè yìí pọ̀ rẹpẹtẹ sí apá ibì kan tí wọ́n ń pè ní Nàìjíríà lónì-ín. Inú Nàìjíríà yìí kan náà ni àwọn elédè Ígbò wà. Ẹnì kan ò jẹ́ bèérè lọ́wọ́ ọmọ Ígbò pé kín ni èdè rẹ̀ kó wí pé Yorùbá lèdè òun. Ó le lọ́mọ Nàìjíríà lòun o, ṣùgbọ́n bí ẹ bá béèrè èdè orírun rẹ̀, Ígbò ni yóó pè é. Bẹ́ẹ̀ náà ni lọ́dọ̀ ọmọ Hausa àti àwọn ẹ̀yà tó kù. Ẹ óó máa gbọ́ “Ijaw ni mí láti Nàìjíríà”, “Yorùbá ni mí láti Nàìjíríà”, “Nupe ni mi láti Nàìjíríà”, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Èyí tó túmọ̀ sí pé, ọmọ orílẹ̀-èdè Ijaw, Yorùbá, Nupe, tàbí ọ̀kan nínú àwọn èdè tó nílẹ̀ tirẹ̀ nínú Nàìjíríà ni mi. Pẹ̀lú àlàyé tí a ṣe sókè yìí, a ò lè pe Nàìjíríà lórílẹ̀-èdè. Ohun ti a lè pè é ni Orílẹ̀ tó kó ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè sínú. Bó ṣe rí gan-an nìyẹn.

Ohun tó sì ń fa wàhálà rèé látìgbà tí Nàìjíríà ti gbòmìnira lọ́wọ́ ìjọba amúnisìn lábẹ́ àwọn Bìrìtìkó. Fún ẹni tí kò bá tún tí ì yé dáadáa, ẹ jẹ́ ká jọ fi ilé bínúkonú ṣàpèjúwèé. Ilé bínúkonú tí àwọn mì-ín ń pè ní Face-me-I-Face-You ni àwọn ilé olójú púpọ̀ tó máa ń ni yàrá oríṣìíríṣìí tó kọjú síra wọn. Oríṣìíríṣìí èèyàn ni yóó wá láti ààyè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti gba yàrá nínú ilé bínúkonú. Nígbẹ̀yìn, yàrá kọ̀ọ̀kan le ní tọkọtìyàwò àti ọmọ wọn tí wọ́n jọ ń gbébẹ̀. Ẹbí kọ̀ọ̀kan ló mọ bí wọ́n ṣe ń ṣètò inú ilé wọn, irú ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń fún ọmọ wọn, àti irú ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ń bá ọmọ wọn wí fún. Ohun tí oníyàrá kìn-ín-ní yóó bá ọmọ rẹ̀ wí fún, oníyàrá kejì le má fi bẹ́ẹ̀ kà á sí ẹ̀ṣẹ̀ líle lójú tirẹ̀. Lóòótọ́ inú ilé kan náà ni àwọn ẹbí yìí ń gbé ṣùgbọ́n oníkálukú mọ yàrá rẹ̀, oníkálukú sì mọ bàbá tó bí i.

Kééyàn wáá wo gbogbo àwọn tó ń gbé nínu ilé bínúkonú yìí kó pè wọ́n ní ọmọ ẹbí kan tàbí ọmọ agboolé kan, ǹjẹ́ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ le kẹ́sẹ̀jarí bó bá gba inú làákáyè ọlọ́pọlọ pípé kọjá? Ìbéèrè ni o.


Bí ọ̀rọ̀ Nàìjíríà ṣe rí gan-an rèé. Ibi tí ọ̀rọ̀ ọ̀hún tún wáá burú sí ni pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé bínúkonú ni wọ́n kó oríṣìíríṣìí ẹbí sí, níṣe ni wọ́n ń ṣètò ilé ọ̀hún bíi agboolé tí ẹnì kan nínú àwọn ọmọ inu ilé yóó di baalé wọn fún ìgbà díẹ̀. Nígbà tí ọmọ inú yàrá kan bá di baálé ilé yìí, tó pàṣẹ pé àwọn ọmọ inú yàrá kan ni kí wọ́n máa gbálẹ̀ inú ile tàbí pé àwọn ọmọ kan ni kí wọ́n máa roko iwájú ìta ilé, àwọn obi wọn yóó máa kùn pé àwọn ọmọ inú yàrá oníyàrá ló fi ń ṣẹrú inú ilé. Nígbà tí ọmọ tàwọn náà bá di baálé ìyà ò ní í jẹ àwọn àbúro rẹ̀ tí wọ́n jọ jẹ́ ọmọ yàrá kan. Bí ọ̀rọ̀ Nàìjíríà ṣe rí látìgbà tí a ti gbòmìnira lọ́wọ́ Bìrìtìkó rèé. Kàkà kí ewé àgbọn sì dẹ̀, níṣe ló tún ń pele sí i débii pé èso ìpínyà tí wọ́n ń gbìn lókè ń kan àwọn ọmọ elédè kan náà tó wà nípìnlẹ̀.

Fún ẹni tí kò bá gbàgbọ́, ẹ jẹ́ ká jọ béèrè lọ́wọ́ ara wa pé báwo ni ọmọ orílẹ̀-èdè kan náà yóó ṣe jọ ṣèdánwò níbì kan náà pé àwọn fẹ́ẹ́ wọ iléèwé kan náà nínú orílẹ̀-èdè wọn tí àwọn méjèèjì yóó jọ yege ìdánwò bákan náà, tí iléèwé tó jẹ́ tìjọba orílẹ̀-èdè wọn yóó sì máa wí pé lágbájá la óó kọ́kọ́ gbà nítorí pé ọmọ ipìnlẹ̀ yìí ni, bí ààyè bá ṣẹ́kù nílẹ̀ ni a óó gba tàmẹ̀dù nítorí pé kì í ṣe ọmọ ìpìnlẹ́ yìí, ọmọ ilẹ̀ ibòmí-ìn ni. Ìyẹn nìkan kọ́ o, àwọn iléèwé mì-ín yóó tún ṣètò ẹ̀dínwó gidi fún ọmọ ìpínlẹ̀ wọn tó wà nílééwè yìí, owó gọbọi lẹnikẹ́ni tó bá ti ìpínlẹ̀ mì-ín wá yóó san kó tóó le gbẹ̀kọ́ níbẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ọmọ agboolé kan ṣoṣo tí a pè ní Nàìjíríà ni wọ́n, wọn kì í ṣe ọmọ ilé bínúkonú tó kọ́ yàrá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún oríṣìíríṣìí ẹbí tó pàdé nínú ẹ̀? Èyí túmọ̀ sí pé ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan tóbi ju orílẹ̀-èdè lọ tàbí ká sọ pé jíjẹ́ ọmọ Nàìjíríà oníkálukú wà lọ́wọ́ apá ibi tó bá wà nínú orílẹ̀-èdè yìí tó jẹ́ tàwọn èèyan rẹ̀.

Ìwé òfin ìṣẹ̀dálẹ̀ Nàìjíríà fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé àparò ọmọ Nàìjíríà kan kò ga ju ọ̀kan kódà bí ọ̀kan bá gun orí ebè. Ìyẹn ni pé, ẹnikẹ́ni tó bá ti jẹ́ ọmọ Nàìjíríà le dìbò yan aláṣẹ ìlú tàbí ní kí àwọn aráàlú dìbò yan òun láti di aláṣẹ ìlú níbíkíbi lórìlẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ẹ jẹ́ ká jọ bi ara wa léèrè, ó di Hausa mélòó ló gbégbá ìbò nípìnlẹ́ Ígbò pé òun fẹ́ẹ́ di gómìnà wọn. Ó di Yorùbá mélòó ló gbégbá ìbò nípínlẹ́ Hausa pé òun fẹ́ẹ́ di aṣòfin fún wọn. Ọ̀tọ̀ ni pé ó gbégbá ìbò kò wọlé, àní ó di ará ẹ̀yà mí-ìn mélòó tó gbégbá ìbò rárá pé òun fẹ́ẹ́ di gómìnà ìpínlẹ̀ tí wọ́n ń gbé? Ẹ kà wọ́n ṣé wọ́n pé ogún? Ṣe kò sí èyí tí iṣẹ́ òṣèlú wù nínú gbogbo àwọn ará ẹ̀yà yìí ni tàbí gbogbo wọn ń wò ó pé orí ilẹ̀ onílẹ̀ làwọn wà, bí àwọn bá fẹ́ẹ́ di aṣáájú èèyàn àfi kí àwọn padà sí yàrá àwọn? Bí ọmọ Nàìjíríà nípìn-ín-lẹ̀ rẹ̀ bá kọ̀ láti dìbò fún ará ẹ̀yà mí-ìn tó lóun fẹ́ẹ́ di gómìnà nípìn-ín-lẹ̀ rẹ̀, ṣé nítorí pé kò kúnjú òṣùwọ̀n ló ṣe kọ̀ láti dìbò fún un ni tàbí nítorí pé ọmọ Nàìjíríà yìí wá láti inú ẹ̀yà mí-ìn tí àṣà àti ìṣe wọn yàtọ sí ti àwọn èèyàn òun. Ǹjẹ́ a sì lè dá a lẹ́bi bó bá ronú bẹ́ẹ̀.

Ẹ jẹ́ ká tún ṣàgbéyẹ̀wò ìwà àwọn ẹ̀yà ńlá mẹ́ta àkọ́kọ́ Nàìjíríà nípa wíwo ìtàn wọn. Èyí kò túmọ̀ sí pé bí gbogbo ọmọ ẹ̀yà yìí ṣe rí rèé o, àgbéyẹ̀wò lásán lèyí pẹ̀lú bí ojú mi ṣe rí i – ẹlòmí-ìn le ṣàgbéyẹ̀wò ìwà àwọn ẹ̀yà yìí kó ní bẹ̀ẹ́ kọ́ ló rí.

Bí ẹnì kan bá lọọ bá Hausa pé òun fẹ́ẹ́ bá a jà, bí òun bá sì fi ṣẹ́gun rẹ̀, abẹ́ òun ni yóó máa wà títí láéláé. Hausa yóó bá onítọ̀hún jà pẹ̀lú gbogbo ohun tó ní, bí onítọ̀hún bá sì fi le ṣẹ́gun rẹ̀ tí Hausa tẹríba fún un, gbogbo ohun tí wọ́n jọ fi orúkọ Ọlọ́run dá májẹ̀mú pé wọn yóó jọ ṣe fún ara wọn ni wọn yóó ṣe. Kódà bí onítọ̀hún bá dàgbà tó rebi àgbà ń rè, Hausa tó tẹ̀ lórí ba yìí le tẹrí ba fún ọmọ rẹ̀ nítorí kò fẹ́ẹ́ yẹ àdéhùn tó bá onítọ̀hún ṣe lórúkọ Ọlọ́run pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé bí Ọlọ́run kò bá kọ ọ́ bẹ́ẹ̀ ni, kò yẹ kónítọ̀hún le ṣẹ́gun òun pẹ̀lú gbogbo ipá tí òun sà láti ṣẹ́gun rẹ̀. A lè pe àṣà yìí ní àṣà olóòótọ́ tó gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, tí kì í sì í yẹ àdéhùn.

Bí onítọ̀hún bá lọọ bá ọmọ ẹ̀yà Ígbò pẹ̀lú àgbékalẹ̀ kan náà. Bí Ígbò bá fi gbà láti bá onítọ̀hún jà, ó ti dá a lójú pé kò ní í ṣẹ́gun òun. Nínú kí òun ṣẹ́gun rẹ̀, tàbí kí òun bá a jà títí tí òun yóó fi kú ni torí bó bá jẹ́ èèyàn ẹlẹ́ran ara bíi tòun tí Ọ̀lọ́run dá ni onítọ̀hun, kò yẹ kó le kápá òun. A lè pe àṣà yìí ní àṣà ẹni tí kò kọ̀ láti kú fún òmìnira rẹ̀ nítorí ó gbàgbọ́ pé Ọlọ́run tó dá gbogbo èèyàn bákan náà kò dá òun láti wà lábẹ́ ẹnikẹ́ni. Báyòówù kí ẹnikẹ́ni lágbára tó, onítọ̀hún tọ́ ara rẹ̀ débẹ̀ ni, òun pàápàá sì lè dépò tó wà tàbí jú bẹ́ẹ̀ lọ bí òun bá tẹpá mọ́ṣẹ́ láti dà bẹ́ẹ̀.


Bí afìjàgbọ̀gá yìí bá lọ sílẹ̀ Yorùbá pẹ̀lú ètò kan náà tó gbé wọ ẹ̀yà méjèèjí àkọ́kọ́, bí Yorùbá bá fojú inú wò ó pé ẹni tóun le dá mú ni, yóó bá a jà pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ̀ láti fi hàn pé òun kì í ṣojo, yóó sì ṣẹ́gun. Ṣúgbọ́n bó bá fi rí i pé onítọ̀hún le ṣẹ́gun òun bí àwọn bá jọ wọ̀yá ìjà, tàbí bóyá ó fojú di í bá a jà kó tóó rí i pé onítọ̀hún le lú òun pa. Kàkà kó bá onítọ̀hún jà rárá débi tí yóó fìyà jẹ ẹ́, tàbí kó gbà kó lu òun pa, Yorùbá yóó ba rúbúrúbú fún amúnilẹ́rú yìí pé ó ti di olúwa òun. Ẹ̀yìn tí ara onítọ̀hún bá balẹ̀ tán ni Yorùbá yóó bẹ̀rẹ̀ si í kọrin “erin ká re’lé o wáá jọba” fónítọ̀hún, ohun tó sì gbẹ̀yin erin tó tóbi gbàǹgbà ju ìjàpá lọ nínú ìtàn ìjàpá-tìrókò-ọkọ-yánníbo ni yóó kẹ́yìn onítọ̀hún. A lè pe èyí ní àṣà ẹni tí kò ní í kọlu òkun nígbà tó ń ru kódà bó bá fẹ́ẹ́ sọdá sódìkejì òkun, àṣà ẹni tó ṣòroó fogun kó lẹ́rú nítorí ìjà wọn kì í tán, ìja wọn ò sì mọ lọ́lọ́wọ́ nìkan, wọ́n le máa bá ọ̀ta wọn jagun nígbà tóun rò pé àwọn jọ ń ṣeré.

Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe sọ ṣáájú pé ojú tí èmi fi rí àwọn ẹ̀ya mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni mo fi ṣàpèjúwe wọn yìí, n ò ní bẹ́ẹ̀ ló rí lójú ẹnikẹ́ni, kódà yóó dáa bí ẹ̀yin pàápàá bá le ṣèwádìí fúnra yín láti wo ìwà ẹ̀yà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Ṣùgbọ́n bí èsì ìwádìí yín bá fìdí ọ̀rọ̀ mi múlẹ̀, èwo nínú àṣà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni a lè kó dànù pé àṣà burúkú ni. Ṣé ti Olóòótọ́ tó gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run tí kì í sì í yẹ àdéhùn ni tàbí ti Akínkanjú tó gbàgbọ́ pé kò sóhun tóun ò le dà láyé, ẹnì kan ò sì lè mú òun lẹ́rú nítorí pé ó lágbára ju òun. Tàbí àṣà olóye tó ní mọ̀jà-mọ̀sá là á mọ akínkanjú lógun ni ká pè láṣà tí kò dáa? Tàwọn mẹ́ta péré la kà yìí o, a ò mẹ́nu ba tàwọn ẹ̀yà rẹpẹtẹ mì-ín tó kún inú Nàìjíríà.

Bí a bá sì fẹ́ẹ́ sòótọ́ fúnra wa, ǹjẹ́ ọ̀kankan nínú àwọn ẹ̀yà yìí le gbà kí ará ẹ̀yà mí-ìn ṣe adarí nínú ẹ̀yà òun nígbà tó mọ̀ pé àṣà àti ìṣe rẹ̀ yàtọ̀ gedegbe sí tòun?

Títí dì bí a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, Hausa ló ń di gómìnà Hausa, Yorùbá ló ń ṣe gómìnà láàrin Yorùbá, ní gbogbo ilẹ̀ Ígbò náà ńkọ́, ọmọ ìpìnlẹ́ wọn ni wọ́n ń yàn láti ṣe gómìnà lé wọn lórí, bó sì ṣe rí ní gbogbo ẹ̀yà Nàìjíríà rèé. Ǹjẹ́ a wáá le sọ pé a ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ẹ́ dá orílẹ̀-èdè Yorùbá, Ígbò, Hausa, Nupe, Edo, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ sílẹ̀ nígbà tó jẹ́ ohun tó ti ń bẹ nílẹ̀ rèé tipẹ́tipẹ́ kò ì sí Nàìjíríà. Ohun ti a ṣe sọ láti ìbẹ̀rẹ̀ àkọsílẹ̀ yìí pé ilé tá a fẹ́ẹ́ wó láì tí ì kọ́ ni Nàìjíríà, torí kì í ṣe orílẹ̀-èdè rárá, orílẹ̀ tó kó oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè sínú ni.

Ǹjẹ́ Nàìjíríà wáá le di orílẹ̀-èdè àbí kò sóhun tẹ́nìkan le ṣe sétò ìpinyà yìí ju ká fọ́ àwọn ẹ̀yà yìí sí wẹ́wẹ́ kí oníkálukú gba ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀? Látìgbà tí Nàìjíríà ti gbòmìnira lọ́wọ́ ìjọba Bìrìtìkó làwọn adarí rẹ̀ láti ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ti ń béèrè ìbéèrè yìí lọ́wọ́ ara wọn. Ọ̀rọ̀ ọ̀hún kò tilẹ̀ jẹ́ ìṣòro fún ìjọba Bìrìtìkó nígbà tí wọ́n ń darí Nàìjíríà, pàápàá nígbà tó jẹ́ pé kò sí ohun tó kàn wọ́n bí Nàìjíríà jẹ́ orílẹ̀-èdè tabí kò jẹ́ bẹ́ẹ̀. Iṣẹ́ Nàìjíríà ni kó ti pèsè ìwúlò fún ìjọba Bìrìtìkó tó kó o jọ, kí ìwúlò ọ̀hún sì máa lọ bẹ́ẹ̀ láì jẹ́ pé àwọn èèyàn dúdú tí wọ́n bá lórí ilẹ̀ náà dí i lọ́wọ́. Ìyàsọ́tọ̀ èèyàn dúdú àti èèyàn funfun nígbà náà mú kí gbogbo ẹ̀yà inú Nàìjíríà fọwọ́sowọ́pọ̀ jà láti gba ara wọn lọ́wọ́ ẹni tí wọ́n rí bíi aráàta, èyí sì mú kí wọ́n dà bíi ọmọ agboolé kan ṣoṣo. Nígbà tóyìnbó lọ tán tó ku àwọn nìkan nínú ohun tó ń jẹ́ Nàìjíríà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín ara wọn gẹ́gẹ́ bí wọn ti rí tòyìnbó.

Àwọn kan gbà pé kí ìyàtọ̀ yìí máa wà lọ bẹ́ẹ̀ nínú Nàìjíríà nítorí wọ́n gbàgbọ́ pé oníkálukú yóó padà gba ilé ẹ̀ lọ lọ́jọ́ kan bíi ténánti ilé bínúkonú tó gbàgbọ́ pé òun óó kúkú kó lọ sílé òun nígbẹ̀yìn. Àwọn kan ń ṣiṣẹ́ lórí kí ìyàtọ̀ yìí máa wà bẹ́ẹ̀ lọ nítorí wọ́n fẹ́ẹ́ dúró bíi aṣojú àti olórí kékeré nínú Nàìjíríà. Wọn ò ní í ṣeé bá wí bí wọ́n bá hùwà ìbàjẹ́, torí ẹni bá lù wọ́n yóó dà bíi ẹni tó lu ẹ̀yà wọn ni. Bí àǹfààní kan bá sì kan gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè, àwọn ni wọn yóó pè bíi ọba kékeré inú ẹ̀ya wọn pé kí wọ́n wáá gba àǹfààní ọ̀hún kí wọ́n sì pín in fún ẹni tí wọ́n bá wò ó pé ó tọ́ sí nínú ẹ̀yà wọn. Bí ẹnì kan bá ń fẹ́ẹ́ lo ẹ̀yà wọn fún ohunkóhun, àwọn ni yóó bá dúnà-án-dúrà iye tí wọ́n fẹ́ẹ́ ta ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ẹ̀ya wọn nínú àjọṣepọ̀ Nàìjíríà.

Àsíá Vatican City State

Bí a ò bá ní í fẹ̀kọ tanná fún ara wa, gbogbo àwọn ẹ̀yà inú Nàìjíríà ló tóó dá dúró gẹ́gẹ́ bíi orílẹ̀-èdè olómìnira tí yóó lórúkọ tirẹ̀ nínú orúkọ orílẹ̀-èdè àgbáyé. Ṣé èrò ní a ó ní kò tó fún wọn ni, àṣà ni wọn ò ní ni àbí ààyè tí wọn yóó pè ní tiwọn ni kò sí? Orílẹ̀-èdè olómìnira ni Nauru, orílẹ̀-èdè olómìnira ni Niue, orílẹ̀-èdè olómìnira ni Vatican City State. Bí a bá pa gbogbo èrò Nauru àti Niue papọ̀, kò tó iye èèyàn tó wà nínú ẹ̀yà Ijaw, ọ̀kan nínú awọn ẹ̀yà tó kéré jùlọ ní Nàìjíríà. Lọ́dún 2020, ètò ìkànìyàn tí wọ́n ṣe ni Nauru fi hàn pé gbogbo èèyàn tó wà níbẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ó lé òjìlélẹ́gbẹ̀rin-dín-mẹ́fà (10,834), tórílẹ̀-èdè Niue ò sì ju ẹgbẹ̀rún kan ó lé òjìlélẹ́ẹ̀dẹ́gbẹ̀rún-dín-mẹ́tà (1,937) lọ nígba tí wọ́n kà á lọ́dún 2021. Báyòówú kí wọ́n yára bímọ tó láwọn orílẹ̀-èdè yìí, wọn ò lè tí ì pé mílíọ̀nù kan lọ́dún 2023. Vatican City State tá a sì dárúkọ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, ààyè rẹ̀ kò tó ìlàjì ìpínlẹ̀ Èkó tó kéré jùlọ nínú gbogbo ìpínlẹ̀ Nàìjíríà rárá bí a bá ní ká wọn gbogbo orílẹ̀-èdè ọ̀hún ní tìbùú-tòòró, ìgbà tí wọ́n tílẹ̀ tún ṣètò ìkànìyàn lórílẹ̀-èdè ọ̀hún lọ́dún 2019, díẹ̀ báyìí làwọn inú ẹ̀ fi lé nírinwó, 453 ni gbogbo wọn. Bí Yorùbá bá wáá lóun fẹ́ẹ́ dá dúró pẹ̀lú èèyàn tó lé ní àádọ́ta mílíọ̀nù, tí Ígbò lóun ń lọ pẹ̀lú èèyàn tó lé lógójì mílíọ̀nù, tí Hausa ní àwọn fẹ́ẹ́ dá Arewa sílẹ̀ pẹ̀lú èèyàn tó ń lọ bíi ọgọ́fà mílíọ̀nù, tàbí àwọn ẹ̀yà kéékèèkéé Nàìjíríà tó tóó gbé Vatican City State mì lóǹkà ni wọn yóó láwọn fẹ́ẹ́ dá dúró tí a óó ní wọn ò lóun àmúyẹ láti di orílẹ̀-èdè olómìnira? Ṣùgbọ́n kó tóó di pé àwọn èèyàn yìí láwọn fẹ́ẹ́ gba òmìnìra, ó yẹ ká bi wọ́n léèrè pé lọ́wọ́ ta ni wọ́n ti fẹ́ẹ́ gbòmìnira? Ṣé lọ́wọ́ Nàìjíríà tá a ti sọ ṣáájú pé kò tí ì sí láyé ni wọ́n ti fẹ́ẹ́ gbòmìnira ni, tàbí lọ́wọ́ àwọn olórí ẹ̀ya wọn tó ń forúkọ wọn pàṣẹ nínú àjọṣepọ̀ Nàìjíríà?

Ṣe ẹ ò gbàgbé ilé bínúkonú tí a fi ṣàkàwé Nàìjíríà lẹ́ẹ̀kan? Kí àwọn ẹbí inú ilé yìí wáá láwọn fẹ́ẹ́ kó lọ sínú ilé táwọn kọ́ fúnra àwọn kí wọ́n le gbòmìnira lọ́wọ́ láńlọọ̀dù ilé yìí, bẹ́ẹ̀ wọ́n mọ̀ pé ilé yìí ò ní láńlọ̀ọ̀dù kan àfi awọ̀n baálé inú yàrà kọ̀ọ̀kan tó ń di olórí fún un lọ́dún mẹ́rin-mẹ́rin. Kí ọ̀kan nínú àwọn baálé ilé yìí máa wáá sọ pé awọ̀n ọmọ inu yàrá òun ò tó bẹ́ẹ̀ kí wọ́n láwọn fẹ́ẹ́ kó kúró nínú ilé yìí. Ẹ jẹ́ ká bi àwọn ọmọ pàápàá léèrè pé ọwọ́ ta ni wọ́n ti fẹ́ẹ́ gbòmìnira gan-an, ṣé lọ́wọ́ bàbá wọn ni àbí lọ́wọ́ baba oníbaba tí wọ́n jọ ń gbélé bínúkonú yìí?

Bí àwọn ẹ̀yà Nàìjíríà bá fẹ́ẹ́ túká láti lọọ dá orílẹ̀-èdè mí-ìn sílẹ̀, ẹnu kí wọ́n sọ fún àwọn aṣojú wọn nílé ìgbìmọ aṣòfin pé kí wọ́n gbé é síwájú àwọn akẹgbẹ́ wọn tí wọ́n jọ wà nílé aṣòfin ni láti jíròrò lé e lórí kí wọ́n le rómìnira. Àbí ẹ̀yà kan wà nínú Nàìjíríà yìí tí kò ní agbẹnusọ tiwọn nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin? Àbí ará ẹ̀yà mí-ìn ló ń ṣojú wọn nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin ni? Ṣebí oníkálukú ló léèyàn nímosàn, kí ló dé tí gbogbo ọmọ ẹ̀yà Nàìjíríà ṣì ń mu kíkan? Ṣé ọmọ ló yẹ kó kú fún òmìnira bàbá ni, àbí baba ló yẹ kó kú fómìnira ọmọ rẹ̀? Ṣé aráàlú ló yẹ kó kú fún òmìnira orílẹ̀-èdè ni àbí àwọn aláṣẹ tí wọ́n ń pe ara wọn ní aṣojú ẹ̀yà wọn níbi tí dídùn bá ti yọ ló yẹ kó dúró fún òmìnira àwọn èèyan wọn ní tikú-tìyè? Bí ìṣòro aṣáájú bá wà fún àwọn ẹ̀yà Nàìjíríà lásìkò tó yẹ kí wọ́n máa figagbá pẹ̀lú àwọn aṣáájú ẹ̀yà mí-ìn pé dáadáa tí àwọn ń ṣe nínú ẹ̀yà àwọn rèé, irú aṣáájú wo ni yóó gòkè nínú orílẹ̀-èdè tuntun tí wọ́n fẹ́ẹ́ dá sílẹ̀ tí wọn ò ti ní í rí ẹ̀yà kan dá lẹ́bi fún àìlàṣeyọrí wọn?


Kó má wáá jẹ́ kìkìdá ìṣòro nìkan la mẹ́nu bà nínú àkọsílẹ̀ yìí, ẹ jẹ́ ká mú ojútùú wá sáwọn ìṣòrò kọ̀ọ̀kan tí a ti nàka sí ṣáájú. A mẹ́nu ba àìdáyé Nàìjíríà nítorí ìpinyà tó wà láàárín àwọn ẹ̀yà tó kóra jọ sínú ẹ̀. Ìpinyà yìí sì mú kí àwọn ẹ̀yà Nàìjíríà fẹ́ẹ́ gba ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ṣáájú kí Nàìjíríà tóó dé. Ṣùgbọ́n kí a tóó sọ̀rọ̀ lórí ọ̀nà tí àwọn ẹ̀yà yìí yóó fi lọ lọ́tọ̀ọ́tọ̀ bó ti tọ́ àti bó ti yẹ, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa bí Nàìjíríà ìbá ṣe rí ká pé ó wà lórí ilẹ̀ ayé lónì-ín. 

Nínú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tá ò rí rí, tó sì ṣeé ṣe kí a má rí, gbogbo ààyè àti ohun ìní Nàìjíríà ni yóó jẹ́ ti gbogbo ẹni tó bá ń jẹ́ ọmọ Nàìjíríà. Gbogbo àṣà àwọn ẹ̀yà Nàìjíríà ni yóó wà lójú kan fún àgbéyẹ̀wò, àwọn alákòóso orílẹ̀-èdè yóó yọ gbogbo ohun tó dáa nínú àwọn àṣà wọ̀nyí sójú kan láti fi dá àṣà Nàìjíríà, wọn yóó sì yọ́ èyí ti kò dáa tàbí tí kò bá ìgbà mu mọ́ nínú àwọn àṣà yìí dànù kó máa bómi lọ. Ọmọ ẹ̀yà Nàìjíríà kan kò ní í le dá ọ̀rọ̀ àṣírí sọ láàárín ara wọn torí gbogbo èdè yìí nìjọba yóó ṣiṣẹ́ láti so papọ̀ kó le bí èdè tuntun. Àbí ẹ lérò pé kò le ṣẹlẹ̀, ẹ bèèrè ibi tí èdè Broken tabí Pidgin ti wá lọ́wọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà láàárọ̀ yìí. Iṣẹ́ gidi yóó bẹ̀rẹ̀ láti rí i dájú pé ìtàn, ìmọ̀, èdè àti àṣà gbogbo ẹ̀yà yìí di àjọmọ̀ fún gbogbo ọmọ Nàìjíríà kí wọ́n le gbà á ní tiwọn.

Ẹnì kan kò ní í gba oyè kan nítorí pé ó jẹ́ ọmọ ẹ̀yà kan, nígbà tí gbogbo ọmọ Nàìjíríà bá ti sọ ara wọn di ọmọ agboolé kan, ẹni tó kúnjú òṣùnwọn jùlọ ni wọn yóó jọ fọwọ́sowọ́pọ̀ fi joyè fún àǹfààní gbogbo ìlú. Gbogbo ẹ̀yà Nàìjíríà yóó lọ sínú ìtàn, níbi tí wọn ò ti ní í dá ẹ̀yàmẹyà sílẹ̀, níbi tí wọn ò ti ní í tan ẹnì kan pé ọ̀kan dáa ju ọ̀kan lọ, níbi tí wọn óó ti wọ inú ara wọn, tí wọn óó sì para dà di ẹyọ̀ kan ṣoṣo...ẹ̀yà Nàìjíríà.

Àlá yìí dáa, ṣùgbọ́n ó le má wáyé láéláé. Torí látigbà ayé ìjọba ológun Gowon tí ẹ̀yàmẹyà dógun abẹ́lé sílẹ ni ìjọba àpapọ̀ ti ṣiṣẹ́ láti so àwọn ẹ̀yà wọ̀nyí papọ̀ gbẹ̀yìn, ohun kan ṣoṣo tí wọ́n ṣe láti bi odi tó pín àwọn ẹ̀yà wọ̀nyí sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ wó ni ètò National Youth Service Corps (NYSC) tí wọ́n kàn nípá fún gbogbo ọmọ Nàìjíríà tó bá fẹ́ẹ́ kàwé gboyè. Látìgbà náà, òǹṣèjọba Nàìjíríà kan kò ṣe nǹkan kan láti so àwọn ẹ̀yà yìí pọ̀. Àìṣe nǹkan kan yìí sì ń mú wọn lọ́wọ́ sí ìdàgbàsókè ẹ̀yàmẹyà nínú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.


Ká tilẹ̀ wáá sọ pé àlá yìí lè wáyé, ṣùgbọ́n à ò fẹ́. Ọ̀rọ̀ ọ̀hún dà bíi ẹni tó ń wá ohun tó wù ú ni tí a sì ń fi nǹkan mì-ín lọ̀ ọ́ pé ó dáa, bó bá dáa bí kò bá wù ú ńkọ́. Ohun àkọ́kọ́ tí a ní láti ṣe ni ká ṣàkọsílẹ̀ gbogbo àìdáa Nàìjíríà àti ìdí tí kò ṣe lè dáa, ká bẹ̀rẹ̀ si í bá àwọn ará ẹ̀yà wa sọ̀rọ̀ lórí bí ikú Nàìjíríà yóó ṣe ṣàǹfààní fún àwọn ẹ̀yà Nàìjíríà. Nígbà tí àwọn ará ẹ̀yà yìí bá ti gbà láti gbé e síwájú àwọn olóṣèlú tí wọ́n yàn sípò gẹ́gẹ́ bíi ọlọ́gbọ́n ààrin wọn pé kí wọ́n jíròrò lórí ikú Nàìjíríà, oníkálukú wọn yóó sọ ohun tó rí sí ọ̀rọ̀ yìí, gbogbo ohun tí wọ́n bá sì sọ yóó wà nínú àkọsílẹ̀. Nítorí pé gbogbo wọn kò lè sùn kí wọ́n kọrí síbì kan náà àti bí ìpinnu yìí ṣe ṣe pàtàkì tó fún orúkọ àwọn baba ńlá wa, àwa gangan àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ wa, àwọn olóṣèlú yóó ṣètò ìdìbò pé kí gbogbo ọmọ inú ẹ̀yà tó wà ní Nàìjíríà dìbò láti dájọ́ Nàìjíríà. Bí wọ́n bá fi dìbò pé kí oníkálukú ó máa lọ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, lẹ́sẹ̀ kan náà ni gbogbo ohun tó ń jẹ́ Nàìjíríà yóó parẹ́ lórí ilẹ̀ ayé yìí tí yóó sì di ohun tí a óó máa sọ pé nígbà kan rí, ibì kan ń bẹ tó ń jẹ́ Nàìjíríà.

Ṣùgbọ́n bí a bá ní láti máa wárí lábẹ́ orílẹ̀-èdè mí-ìn ká tóó le dá orílẹ̀-èdè olómìnira tuntun sílẹ̀, bí ẹnu wa kò bá le ká àwọn olóṣèlú tó ń ṣojú wa kí wọn kọrí síbi tá a kọjú sí, bí a ò bá le bá àwọn èèyàn inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan sọ̀rọ̀ kí wọ́n rí dáadáa tó wà nínú ikú Nàìjíríà, kí wọ́n pinnu lọ́kàn ara wọn láti pa á kí wọ́n sì fi òkú rẹ̀ kọ́ orílẹ̀-èdè tiwọn tí yóó dúró fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, gbogbo ẹ̀sùn tí à ń kà sí Nàìjíríà lẹ́sẹ̀ la óó kó lọ sínú gbogbo orílẹ̀-èdè tí a bá fi ẹ̀yà dá tí a óó sì fi fọ́ òun náà túká. Èpè kọ́ o, àsọ̀tẹ́lẹ̀ tó jẹyọ níbi ìwòye lásán ni.

Musa Babátúńdé-Kọ́gà lorúkọ mi. Láti fèsì sí àkọsílẹ̀ yìí, ẹ lè fi àtẹ̀ránṣẹ́ sí irismediaps@gmail.com. Ẹ sì lè fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí nọ́mbà yìí lórí Whatsapp: +2348085548868

Òjò ni mí n ò bẹ́nì kan ṣọ̀tàá, ẹni eji rí leji ń pa. Ààrá ni mí n ò bẹ́nì kan ṣọ̀tẹ̀, ẹni ó bá dí mi lọ́nà ni yóó ríjà arábámbí onígba ọta.

Ojú tí mo fi rí ohun tó ń lọ lágbo òṣèlú rèé, ìyòókù tún dọjọ́ mì-ín t’Édùmàrè bá ní kí ẹ̀mí mi ó dà láàyè tẹ́nu mi óó ti lè rí ọ̀rọ̀ sọ.

Ire o.

Post a Comment

0 Comments