Nígbà tí àwọn oníwàdìí ìjìnlẹ̀ wo sààkun ohun tó ń ṣe sábàbí àìsàn àti ẹ̀mí kúkúrú fénìyàn, wọ́n rí í pé bí a ṣe ń jẹun àti bí a ṣe ń gbé ilé ayé wa kópa púpọ̀ nínú bí ẹ̀mi wa óó ṣe gùn tó torí adẹ́dàá ti ṣàkótán ohun tí yóó kógun ja àìsàn yòówù tó bá fẹ́ẹ́ bá wa jà sínú ara. Ohun tó kù fún wa ni láti rí i dájú pé ohun tí à ń jẹ àti àwọn nǹkan tí à ń ṣe ń ró àwọn akọgun inú ara yìí lágbára sí i láti kógun ja àìlera wọ̀nyìí.
Kò ní í ṣàì yà yín lẹ́nu pé lára àwọn nǹkan tó le ran àwọn akọgun inú ara yìí lọ́wọ́ láti kógun ja àrun inú ara loorun. Bẹ́ẹ̀ ni, oorun sísùn.
Lásìkò tí èèyàn bá ń sùn gan-an ni àwọn akọgun inú ara yìí máa ń lè ṣiṣẹ́ wọn dáadáa, torí ẹ̀ làwọn elétò ìlera ṣe máa ń gba àwọn ẹbí àti ará aláàrẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n fún un láàyè láti sùn dáadáa kí àwọn èròjà inú ara wọ̀nyí lè ṣiṣẹ́ wọn bó ṣe yẹ.
Fún ẹni tó bá ti lé ní ọmọ ogún ọdún sókè, ó yẹ kí onítọ̀hún máa gbìyànjú láti sun oorun wákàtí méje kílẹ̀ tóó mọ́, ó kéré tán nìyẹ̀n. Fún àwọn ọmọdé, ìwádíì iléeṣẹ́ CDC (Center for Disease Control) orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà gbé e jáde pé ó yẹ kí wọ́n máa sùn fún wákàtí mẹ́wàá. Àwọn ọmọ tí à ń tọ́ lọ́wọ́ ni wọ́n ní ó yẹ kí wọ́n máa rí oorun wákàtí méjìlá sùn láti le kógun ja àrùn yòówù tó bá fẹ́ẹ́ dìde nínú ara wọn.
Tó bá tásìkò féèyàn láti sùn, ó fẹ́ẹ̀ má sí ohun tó le dá èèyàn dúró láti pa ojú dé, ṣùgbọ́n ìṣòro a máa wà fẹ́lòmí-ìn láti pajúdé lórù, wọn óó máa yí sọ́tùn-ún sósì lórí ibùsùn ni títí tílẹ̀ óó fi mọ́. Bẹ́ẹ̀ àkóbá tí èyí ń ṣe nínú ara kò kéré rárá.
Ìwádìí iléeṣẹ́ ìjọba Amẹ́ríkà, www.pubmed.gov, ṣàlàyé pé iná tó máa ń tàn lójú ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán, fóónù àtàwọn kọ̀m̀pútà wa gbogbo a máa dá oorun mọ́ wa lójú.
Nítorí ìdí èyí, bó bá ti di lálẹ́ tó yẹ kẹ́ ẹ ti wà lójú oorun, ẹ pa àwọn tẹlifíṣàn yín, ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ tàbí àwọn nǹkan tó le tanná sí yín lójú. Kódà bó bá ṣeé ṣe, ẹ lè sùn sínú yàrá tó ṣókùnkùn dáadáa tàbí kí ẹ lo ìbòjú oorun (Sleep mask) tó wà lóde nísìnyìí bí ó bá ń ṣòro fún yín láti rí oorun sùn.
Púpọ̀ nínú àwọn àrùn tó ń dà wá láàmú tí a padà ń náwó òògùn lé lórí ló ṣeé dènà bí a bá le mójútó àwọn akọgun inú ara yìí. Òun pàápàá làwọn elétò ìlera gbójúlé láti fi kojú ìjà sí àwọn àrùn tuntun tí wọn ò tí í róògùn ìwòsàn fún. Èyí ló ṣe ṣe pàtàkì kí ẹ̀yin fúnra yín ṣe gbogbo ohun tó bá ṣeé ṣe lápá ọ̀dọ̀ yín láti ró àwọn akọgun yìí lágbára kí wọ́n le kojú ìjà sí àrùn yòówù tó bá fẹ́ẹ́ dí ìlera ẹ̀yin àti ẹbí yín lọ́wọ́.
A ò ní í ṣàárẹ̀ o.
0 Comments