Search This Blog

ÌJÀ Ò DỌLÀ – ÌJÀ Ń JÁ DỌ́LÀ

 


Àbí yóó wù ọ́ láti gbọ́ àkọsílẹ̀ yìí dípò kíkà á? Tẹ ibí.
Bí àwọn òṣèré Yorùbá bá ṣetán láti fi eré wọn kọ́ọ̀yàn ní sùúrù, wọn óó ní ìjà ò dọlà, orúkọ burúkú ní í fún’ni. Àwọn gan-an sì kọ́ ni wọ́n ni ọ̀rọ̀ yìí o, ọ̀rọ̀ táwọn àgbàlagbà fi máa ń fa ọmọ sẹ́yìn láyé àtijọ́ tó bá fẹ́ẹ́ sọ ara rẹ̀ doníjàgídíjàgan nìyẹn.

Ṣùgbọ́n lónì-ín, òwe àtijọ́ pátápátá ni. Láyé ọjọ́un nìjà ò dọlà, lọ́wọ́ yìí, ìjà ti ń já dọ́là béèyàn bá rìn ín lọ́nà tó yẹ. Àwọn ọmọ ẹ̀ṣẹ́ kan ń pànìyàn mẹ́fà sì ti ń fẹ̀yìn ọwọ́ gba pọ́n-ùn nílẹ̀ Yorùbá yìí.

Àwọn Yorùbá tó ṣẹ̀dàá owe ìjà ò dọlà yìí pnáà ni wọn máa n pòwe pé “ọgbọ́n ọdúnnì-ín, wèrè ẹ̀mì-ín.” Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé ọ̀rọ̀, ìwà, ìṣe tàbí àṣà tí ayé ń gbé kiri lónì-ín pé tàwọn ọlọ́gbọ́n ni, ó le dọ̀la kó di ohun tí wọn óó máa fẹnu tẹ́ḿbẹ́lú pè lọ́rọ̀ wèrè.

Lóòótọ́ ni pé kì í ṣe ohun tó sunwọ̀n rárá láti dojú ìjà kọ ọmọlàkejì ẹni. Kò sì sẹ́nì kan tí yóó fún ọkùnrin tó dojú ẹ̀ṣẹ́ kọ ìyàwó ẹ̀ lórúkọ gidi láéláé. Ṣùgbọ́n àwọn kan wà tó jẹ́ pé iṣẹ́ kí wọ́n lùùyàn dákú l’Ọlọ́run rán wọn, a ò sì lè dá wọn lẹ́bi bí wọ́n bá ń fẹ̀ṣẹ̀ lugbá – lu àwo nínú ilé. Ohun tó yẹ ká ṣe ni láti fọ̀nà tí wọn yóó gbé kinní ọ̀hún gbà hàn wọ́n kó baà lè sọ wọ́n lórúkọ ire dípò orúkọ burúkú láwùjọ.

Bẹ́ ẹ bá tẹ orúkọ Ryan Garcias sórí ìkànnì ẹ̀rọ ayélujára Google lónì-ín, iye tọ́kùnrin náà ní lápò níbi ẹ̀ṣẹ́ kíkàn kì í ṣe kékeré, mílíọ́nù mẹ́wàá owó dọ́là ($10,000,000.00) ni. Béèyàn bá wo ti Tyson Fury, ẹ̀fọ́rí ò ní í jẹ́ kẹ́lòmí-ìn tó ń fi báírò jẹun róórun sùn, mílíọ́nù márùndínláàádọ́rin owó dọ́là ($65,000,000.00) ni tiẹ̀. Àwọn tá a tiẹ̀ ń dárúkọ yìí tiẹ̀ tún jìnnà, ti Anthony Joshua tó jẹ́ ọmọ Ìjẹ̀bú ń’lẹ̀ẹ́lẹ̀ ń’bẹ̀un ńkọ́, ọgọ́rin mílíọ́nù owó dọ́là ($80, 000, 000.00) ló jẹ́ tiẹ̀ tí kì í ṣe pé wọ́n dá a sí i lọ́wọ́. Kí wáá làwọn tó ń fẹ̀ṣẹ̀ẹ́gbawó yìí ń ṣe táwọn tó ń fẹ̀ṣẹ̀ẹ́gbẹ̀wọ̀n ò ṣe?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń wò ó pé kò sí ohun tó dáa kan nínú ìjà jíjà, bẹ́ẹ̀ bí kò ju ẹ̀ẹ̀kan sí ẹ̀ẹ̀mejì nínú ayé ọmọkùnrin, kò ní í ṣàì kó sínú ìṣòro tí yóó nílò kó jìjàgbara rẹ̀ sílẹ̀. Bó bá jẹ́ ẹni tó ti kọ́ bí wọ́n ṣe ń ju ọwọ́ ẹ̀ṣẹ́ méjì sí mẹ́ta tẹ́lẹ̀ ṣáájú ọjọ́ ìṣòro ni, Ọlọ́run le ní kí orí kó o yọ nínú ìṣòro yìí. Ṣùgbọ́n ọmọkùnrin tí kò kọ́ bó ṣe le gba ara rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ ọkùnrin ẹgbẹ́ ẹ̀ tó le fẹ́ẹ́ kó o ní pápámọ́ra lọ síbi tí ò fẹ́ẹ́ lọ, tí ọjọ́ ìṣòro wáá dé tó ń ké pe Ọlọ́run pé kó dìde lórí ìtẹ́ ẹ̀ lọ́run kó wáá gba òun láyé, bíbéélì fúnra rẹ̀ ti fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sónítọ̀hún kò fetí sí i ni o – “ìgbàgbọ́ láì síṣẹ́, òfo ni.” Ṣíkún báyìí ni ọkùnrin ẹgbẹ́ ẹ̀ óó mú un làí sí wàhálà kankan.

N ò sì lérò pé Ọlọ́run yóó bínú pé wọ́n ṣe gbé géńdé ọkùnrin bẹ́ẹ̀ lọ láì sí wàhálà, torí irú ẹni bẹ́ẹ̀ ò lè pé òun ò gbọ́ pé èèyàn ń kojú ìṣòro láyé. Ohun tí ò wáá mú kó palẹ̀mọ́ ara rẹ̀ láti ja àjàbọ́ lọ́jọ́ ìṣòro, tó fi wáá ń ké pe Ọlọ́run pé kó gba òun sílẹ̀ lọ́wọ́ ọkùnrin ẹgbẹ́ ẹ̀ ni yóó rò lẹ́jọ́ tí yóó fi jàre Ẹni tó dá a. Ẹni ó palẹ̀mọ́ ara rẹ̀ fún ìjà gan-an ń ṣubú, ábèlè-ǹ-tàsé ẹni tí ò mọ̀ ju kó jẹun – kó ṣe fàájì – kó sì sùn lọ bíi ẹni pé orí tẹlifíṣàn nìkan layé ti ń le mọ́-ọ̀n-yàn. Àwọn babańlá wa pàápàá a máa sọ ọ́ láyé àtijọ́ pé kò yẹ kí ọmọkùnrin óó dúró lásán. Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé ọkùnrin gbọdọ̀ dúró déédé débii pé bí wọ́n bá ní wọ́n kápá ẹ̀ níbì kan, bí àwọn ọkùnrin ẹgbẹ́ ẹ̀ bá débẹ̀ wọn óó le wí pe “àfi bẹ́ẹ̀!”

A-wáá-ń-kọ́-láti-dáàbò-bo-ara-ẹni kò mọ fún ọkùnrin nìkan o, takọ-tabo ló yẹ kó kọ́ ọgbọ́n àti ète kọ̀ọ̀kan tí wọ́n le fi gba ara wọn sílẹ̀ nínú ìṣòro. Pàápàá níbi tí ayé ń lọ lọ́wọ́ yìí tí à ń gbọ́ ogun ìjínigbé lọ́tùn-ún lósì, béèyàn ò tiẹ̀ níbọ̀n, tí ò lóògùn, ó yẹ kó le kọ́ ibi tí yóó tọ́jú ẹ̀ṣẹ̀ méjì sí lára olódì rẹ̀ tí kò tiẹ̀ fi ní í rójú ríbi tẹ́ni tó kan òun lẹ́ṣẹ̀ẹ́ óó gbà sá lọ.

Ọ̀kan nínú ìmọ̀ ìdáàbòbora-ẹni tí àwọn èèyàn ń kọ́ ni ẹ̀ṣẹ́ kíkàn. Ìjà ọlọ́wọ́ tó jẹ́ pé ìdìkúùkú ọwọ́ nìkan ni àwọn oníjà yóó fi dá sèríà fún ara wọn. Ọjọ́ ìjà yìí ti pẹ́ gidi nínú ìtàn tẹ́nìkan ò lè sọ pé ìgbà báyìí ló bẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n pé wọn óó kọ́kọ́ pé wò ó gẹ́gẹ́ bíì eré ìdárayá Olympic tí wọ́n ṣì ń ṣe lágbàáyé dóní, ọdún eré Olympiad kẹtàlélógún tí wọ́n ṣe lọ́dún ọ̀rìnlélẹ́gbẹ̀ta-le-mẹ́jọ kí wọ́n tóó bí Jésù olùgbàlà ni, ìyẹn 688 BC. Láti ìgbà náà títí dòní sì ni àwọn oníjà ọ̀hún ti ń níyì lójú aráayé.





Kéèyàn tóó wáá le di ẹni àpéwò níbi ìjà ọlọ́wọ́ yìí, ohun méjì ló nílò. Àkọ́kọ́ ni òṣùwọ̀n rẹ̀ bó ṣe wúwo tó àti ìmọ̀ béèyàn ṣe ń fi ẹ̀ṣẹ́ kíkàn sọ olódì rẹ̀ di aláìlágbára. Níbo wáá lèèyàn ti lè kọ́ ohun méjì yìí, ilé ìsán-an-gun tí wọ́n ń pè ní Gym Center ni. Inú ilé ìsán-an-gun yìí ni wọ́n ti ń di ẹrù wíwo rùùyàn tí yóó fi kún òṣùwọ̀n íwúwo rẹ̀, tí yóó sì jẹ́ kó le dá ara rẹ̀ gbé. Béèyàn bá ṣe wúwo tó lọwọ́ ẹ̀ṣẹ́ rẹ̀ yóó ṣe wúwo. Ìbẹ̀ gan-an ni wọ́n ti ń pilẹ̀ ọwọ́ ẹ̀ṣẹ́ kan ti í pààyàn lẹ́ẹ̀mẹfà.

Ìpele bíi mẹ́tàdínlógun ni ìdiwọ̀n íwúwo èèyàn nínú ilé ìsán-an-gun yìí, ṣùgbọ́n ìpele mẹ́tẹ̀ẹ̀tàdínlógún ló ṣeé pín sí ìsọ̀rí mẹ́ta. Ìsọ̀rí kìn-ín-ní ni tàwọn afúyẹ́-bíi-eeṣin (Flyweight) tó bẹ̀rẹ̀ láti kílò méjìdínláàádọ́ta, ìsọ̀rí kejì ni tàwọn afúyẹ́bíìyẹ̀ẹ́ (Featherweight) tó bẹ̀rẹ̀ láti kílò mẹ́tàdínlọ́gọ́ta, ìsọ̀rí kẹta sì làwọn awúwomáṣeégbé (Heavyweight) tí afàìdúkookò mọ́ni wọn ń dẹ́rùú ba ni. Òṣùwọ̀n àwọn wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ láti kílò méjìléláàádọ́rún-ùn sí iyekíye tí wọ́n bá le dé.

Béèyàn bá wáá di ẹrù wúwo ru ara rẹ̀ títí tó fi di awúwomáṣeégbé, bí kò bá kọ́ ìmọ̀ ẹ̀ṣẹ́ kíkàn yìí, ọ̀rọ rẹ̀ dá bíi ọ̀rọ alágbára-má-mèrò baba ọ̀lẹ ni. Tórí bí afúyẹ́-bíi-eeṣin bá mọ ọwọ́ rẹ̀ lò dáadáa, ó le fẹ̀yin rẹ̀ nalẹ̀ báyòówù kó tóbi tó. Ohun tó ṣe ṣe pàtàkì láti ní akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tí yóó dánilẹ́kọ̀ọ́ lórí béèyàn yóó ṣe lo agbára rẹ̀ fi ṣẹ́gun nínú ìjà yóówù tó bá bá ara rẹ̀ rèé.

Ohun méjèèjì yìí ló la ìnáwó lọ, ìyẹn wíwọ ilé ìsán-an-gun àti gbígba akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tí yóó kọ́ni níjà, iye tí yóó sì náni wà lọ́wọ́ àdúgbò tèèyàn bá wà.

Nínú ìwádìí ìkànnì ayélujára Superprof, àwọn ará Ìbàdàn le rí ilé ìsán-an-gun bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ ẹ̀ṣẹ́ kíkàn wọn láwọn ibi wọ̀nyìí:

1. Supermax Gym tó wà nítòsí iléèfowópamọ́ FirstBank ójú ọ̀nà Jericho.

2. My Figure 8 Gyming Center tó wà ní Olúyọ̀lé Estate Road.

3. Oyo State Executive Gym tó wà ní Mokola Hill.

4. Ìkẹrin ni Elle ‘n’ Elle Fitness, Art and I.T Center tó wà lójú ọ̀nà Akóbọ̀, nítòsí ilé-ẹ̀kọ́ IDC Primary School, Ìbàdàn.

Àwọn ará Èkó le rí tiwọn bẹ̀rẹ̀ láwọn ilé ìsán-an-gun wọ̀nyìí:

1. Lagos Boxing Hall of Fame Gym tó wà ní Sùúrùlérè.

2. Elitebox Fitness tó wà ní òpópónà Adétòkunbọ̀ Adémọ́lá, Victoria Island.

3. Alpha Fitness Studio tó wà ní Centro Mall, Lekki Phase 1.

Bó bá sì jẹ́ Àbújá lẹ̀yín wà, ẹ lè bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ yín ní:

1. Bodyrox Fitness Studio tó wà ní Central District Area, Abuja.

2. The Bodyline Gym náà wà ní agbègbè Gwarimpa fún gbogbo ẹni tó bá fẹ́ẹ́ bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ ẹ̀ṣẹ́ kíkàn.

Gbogbo àwọn ilé ìsán-an-gun wọ̀nyìí ló ní iye tí wọ́n ń gbà láti sọni di Sámúsììnì alágbára, ṣùgbọ́n gbogbo rẹ̀ ló lérè nígbẹ̀yìn. Bó bá jẹ́ ẹni tó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ yìí láti kàn fi le dáàbò bo ara rẹ̀ ni, ìwọ̀nba ni ìnáwó rẹ̀ yóó mọ tí yóó fi rí ohun tó ń wá. Bó bá sì jẹ́ ẹni tó fẹ́ẹ́ fi ẹ̀ṣẹ́ kíkàn ṣiṣẹ́ jẹun táwọn èèyàn yóó máa pé wò ó ni, lóòótọ́ ni pé yóó náwó nára jú ẹni tó kàn kọ́ ọ láti dáàbò bo ara rẹ̀ lọ o, ṣùgbọ́n nígbà tó bá di pé àwọn iléeṣẹ́ tó ń gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ẹ́ bá bẹ̀rẹ̀ si ì dù ú lọ́tùn-ún lósì káàkiri àgbáyé ni yóó tóó mọ ìyì ohun tóun kọ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé òun.

Ìwọ̀nba iléèsán-an-gun tá a dárúkọ sókè yìí kọ́ ló wà láwọn ìpínlẹ̀ yìí o, ìwọ̀nba àwọn tá a lè dárúkọ fún yín rèé kí àkọsílẹ̀ yìí má dohun tí yóó kàn gùn lọ rẹẹrẹẹrẹ. Bí ìpínlẹ̀ yín kò bá sí nínú ìpínlẹ̀ mẹ́ta tá a dárúkọ sókè yìí, ẹ lè béèrè lorí ìkànnì ayélujára Google pé níbo ni ilé ìsán-an-gun wà ládùúgbò yín. Bí ẹ bá ti tẹ̀ ẹ́ síbẹ̀ lédè gẹ̀ẹ́sì pé “Gym centers around me” lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni yóó dárúkọ èyí tó sún mọ́ yín jùlọ. Ó ṣe ni láànú pé ifá Google kò tí ì gbọ́ Yorùbá dunjú, ède Yorùbá ni n ò bá ní kẹ́ fi bèèrè. Ṣùgbọ́n ifá ìgbàlódé yìí kò tí ì gbọ́ Yorùbá débi tá a lè fi èdè wa bèèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ẹ̀.

Bí kò bá sì sí ilé ìsán-an-gun yìí ládùúgbò yín, ayé ti lu jára débii pé ó fẹ́ẹ́ má sí ohun téèyàn ò lè kọ́ lórí fóónu rẹ̀. Ẹnu kẹ́ bẹ̀rẹ̀ si í ṣèwádìí kéekèeké lórí fóónu yín ni, gbogbo fídíò ohun tó yẹ kí ẹ ṣe láti fi sọ ara yín di awúwomáṣeégbé yóó sì dohun àgbéléwò.

Ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn tí Ọlọ́run kọ iṣẹ́ ẹ̀ṣẹ́ kíkàn mọ́ lórílẹ̀-èdè yìí ò ríbòmí-ìn lò ó sí ju kí wọ́n fi wọ inú ẹgbẹ́ òkùnkùn lọ, tàbí kí wọ́n fi sọ ara wọn di ọmọ agbèrò tí í fẹ̀ṣẹ́ gbowó ípá lọ́wọ́ dẹ́rẹ́bà, bẹ́ẹ̀ wọ́n le fi ayé wọn ṣe ohun tó dáa jù báyìí lọ.

Ọ̀rọ̀ ọ̀hún sì tún wà lọ́wọ́ ìjọba pàápàá láti pèsè ètò tí yóó mú kí àwọn èèyàn ṣíjú sí eré ìdárayá tó ń pawó rẹpẹtẹ fáwọn orílẹ̀-èdè káàkiri àgbáyé. A ò lè ṣàì ní ọmọ lílé láwùjọ, a ò lè pa wọ́n rẹ́, a ò sì lè dà wọ́n nù pé kí wọ́n máa hùwà líle wọn títí tí wọn óó fi ṣe èyí tí yóó sọ wọ́n dèrò ẹ̀wọ̀n. Ohun tó yẹ ni ká ṣètò tí wọn óó fi lo ohun tí Ọlọ́run fún wọn lọ́nà tí yóó fi wúlò fáwùjọ. Bí wọ́n ṣe ń ṣe láwọn orílẹ̀-èdè tó ń ní láárí lágbàáyé nìyẹn.

Èyí à ń sọ dùn, mo fẹ́ẹ́ bèèrè lọ́wọ́ ẹ̀yin tẹ́ ẹ̀ ń ka àkọsílẹ̀ yìí, kín ni ìdinwọn ìwúwo yín? Ṣé afúyẹ́-bíi-eeṣin lẹ̀yin ni, àbí afúyẹ́bíìyẹ́? Àbí àgbà ọ̀jẹ̀ tí wọ́n ń pè ní awúwomáṣeégbé lẹ̀yin? Ẹ lè dáhùn sísàlẹ̀ àkọsílẹ̀ yìí tàbí kẹ́ tẹ ibí láti bá mi sọ̀rọ̀ lórí ìkànnì ìbára-ẹni-sọ̀rọ̀ Whatsapp. Àbí ojú ń tì yín láti sọ ohun tẹ́ ẹ wọ̀n? Ẹ má jẹ́ kójú ó tì yin o, afúyẹ́bíi-eeṣin kú lèmì tí mo ń jó ẹnu belebele látàárọ̀ yìí. Ṣùgbọ́n ọ̀la ṣì ń bẹ níbẹ̀, èmi àti yín le fọ̀la kó ara wa gba ilé ìsán-an-gun lọ ká le bẹ̀rẹ̀ mú kinní ọ̀hún níbàádà. Ìgbà kan ò pẹ́ jù fẹ́ni tó bá níkan-án ṣe.

Ire o.

Post a Comment

0 Comments