Search This Blog

ÌTÀN ṢÓKÍ NÍPA ÌGBÉSÍ AYÉ ABÍMBỌ́LÁ AWÓLÍYÌ, OBÌRIN ÀKỌ́KỌ́ TÍ YÓÓ DI DÓKÍTÀ NÍ NÀÌJÍRÍÀ

Àbí yóó wù ọ́ láti gbọ́ àkọsílẹ̀ yìí dípò kíkà á? Tẹ ibí.

Nígbàkigbà tí àwọn òǹpìtàn Nàìjíríà bá jókòó láti ròyìn àwọn obìnrin pàtàkì nínú iṣẹ́ ìṣègùn òyìnbó, kò sí bí wọ́n ṣe fẹ́ẹ́ yọ ọ̀rọ̀ Dókítà Abímbọ́lá Awólíyì sẹ́yìn o, torí òun gan-an ni ọmọ Nàìjíríà àkọ́kọ́ lóbìnrin tí yóó di oníṣègùn òyìnbó lórílẹ̀-èdè rẹ̀.

A bí arábìnrin Abímbọ́lá sí ìpínlẹ̀ Èkó lọ́dún 1910. David Akérélè lorúkọ bàbá rẹ̀, Rufina Akéréle sì ni ìyá rẹ̀ ń jẹ́. Ìlú Èkó yìí náà ló ti bẹ̀rẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní St. Mary's Catholic School. Lẹ́yìn tó ṣetán níbẹ̀ ló tẹ̀síwájú ní ilé-ẹ̀kọ́ girama Queens College kan náà tó wà ní Yábàá. Bó ṣe ń parí ẹ̀kọ́ girama yìí ni ó gba ilé-ẹ̀kọ́ gíga University of Dublin lọ, ibẹ̀ ló sì ti kàwégboyè Degree àkọ́kọ́ nínú ìmọ̀ ìṣègùn òyìnbó.

Nílé-ẹ̀kọ́ gíga Dublin yìi, ipò àwọn tí èsì ìdánwò wọn dáa jùlọ ni wọ́n tò ó sí, èyí tí wọ́n pè ní First Class Honors. Ó gba àwo fún iṣẹ́ apòògùn, àwọn òyìnbó fúnra wọn sì kọ ọ́ sínú èsì ìdánwò rẹ̀ pé àyàsọ́tọ̀ ni ìmọ̀ rẹ̀ nípa ẹ̀yà ara ènìyàn níbi tó dáa dé.

Síbẹ̀ Abímbọ́lá kò dúró, ó ṣì tún tẹ̀síwájú nínú ìmọ̀ ìṣègùn òyìnbó yìí ní Royal College of Physicians, Royal College of Obstetricians and Gynaecology àti Royal College of Paediatrics and Child Health.

Ẹ̀yìn tó parí àwọn ẹ̀kọ́ yìí ló ṣẹ̀ tóó padà sí Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bíi òṣìṣẹ́ elétò ìlera tó ń mójútó ọ̀rọ̀ nípa ilé ọmọ obìnrin (Gynecologist) nílééwòsàn Massey Street Hospital tó wà l'Ékòó. Ipò oníṣègùn kékeré ló fi bẹ̀rẹ̀ títí tó fi di ọ̀gá pátápátá níléèwòsàn náà láti ọdún 1960 títí di 1969. Lọ́dún 1962 ni iléeṣẹ́ ètò ìlera Nàìjíríà yàn án gẹ́gẹ́ bíi àgbà akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nínú ìmọ̀ nípa ilé ọmọ obìnrin (Gynecologist) àti ìgbẹ̀bí (Obstetrician).

Oríṣìíríṣìí àmì-ẹ̀yẹ̀ ló gbà nígbà ayé ẹ̀, lára àwọn àmì-ẹ̀yẹ̀ tó gbà ni MBE (Most Excellent Order of the British Empire), OFR (Officer of the Order of the Federal Republic of Nigeria). Nídìí iṣẹ́ rẹ̀ náà ni wọ́n ti fi oyè Ìyá Àbíyè Gbogbo Èkó dá a lọ́lá, Aláàfin Ọ̀yọ́ náà sì fi í jẹ Ìyálájé ìlú Ọ̀yọ́.

Yàtọ̀ sí iṣẹ́ ìṣègùn òyìnbó tó mumú lọ́kàn rẹ̀ yìí, Abímbọ́lá tún na ọwọ́jà rẹ̀ sídìí iṣẹ́ àgbẹ̀. Ó ní oko adìẹ sílùú Agége, níbi tí wọ́n ti ń sin àwọn ẹranko oníyẹ̀ẹ́, tí wọ́n sì gbin igi ọsàn sí rẹ́kẹrẹ̀kẹ.

Elizabeth Awólíyì ni olùdásílẹ̀ àti ààrẹ àkọ́kọ́ ẹgbẹ́ obìnrin tí wọ́n pè ni National Council of Women Societies ẹ̀ká Èkó. Òun sì ni ẹnì kejì tí yóó di ààrẹ gbogbogbò fún ẹgbẹ́ náà lọ́dún 1964.

Ìfarasìn àti àṣeyọrí Abímbọ́lá lẹ́nu iṣẹ́ tó yàn láàyò yìí kò ní kó pàdánù àṣeyọrí tí ọ̀pọ̀ obìnrin máà ń ṣe. Abímbọ́lá lọ́kọ, bẹ́ẹ̀ ló sì bímọ. Dokita S. O. Awólíyì ló fẹ́, wọ́n sì bímọ méjì fún ara wọn, ọkùnrin kan àti obìnrin kan.

Lọ́jọ́ kẹrìnlá, oṣù kẹsàn-án ọdún 1971 ni Abímbọ́lá jáde láyé lẹ́ni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́ta (61). Ní ìrántí rẹ̀ ni wọ́n dá iléèwòsàn Dr. Abimbola Memorial Hospital sílẹ̀.

Abímbọ́lá jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn akọni obìnrin tó lo ìgbésí ayé rẹ̀ láti fi ṣiṣẹ́ gbé ògo ilẹ̀ Yorùbá àti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ga.

Post a Comment

0 Comments