Search This Blog

BÍBÍIRE Apá Kejì


  


Mo sọ nínú apá kìn-ín-ní orí yìí pé bí wọ́n bá ń ka àwọn ọmọ tí wọ́n bíire, àfi ẹni tí kò bá mọ ìtumọ ọ̀rọ̀ náà délẹ̀délẹ̀ ni yóò kà mí mọ́ wọn. Nígbà tí mo bá bẹ̀rẹ̀ si í ṣàlàyé inú ilé tí mo ti jáde, ọ̀rọ̀ mi yóò túbọ̀ yé yín dáadáa.

Iṣẹ́ àgbẹ̀ niṣẹ́ bàbá mi. Ìṣẹ́ tó jogún lọ́dọ̀ àwọn babańla rẹ̀ ni. Kí ì ṣe pé ó dá ní oko tirẹ̀ o, òun àti àwọn àbúrò rẹ̀ mẹ́rin ni wọ́n jọ ni oko ọ̀hún. Àwọn àbúrò rẹ̀ yìí ni Bọ̀ọ̀dá Ràímì, Bọ̀ọ̀dá Tájù, Bọ̀ọ̀dá Mùtáírù, àti Bọ̀ọ̀dá Tàfá.

N ò tóó pè ọ̀kankan nínú wọn ní bọ̀ọ̀dá o, baba ni gbogbo wọ́n jẹ́ fún mi. Ṣùgbọ́n bí ìyá mi ṣe dárúkọ wọn látorí èyí tó dàgbà sí èyí tó kéré jùlọ nínú wọn rèé lọ́jọ́ tí wọ́n ń sọ̀tàn oko wa fún mi.

Bí wọ́n ṣe jogún ilẹ̀ oko yìí lọ́wọ́ bàbá wọn náà ni bàbá wọ́n ṣe jogún ẹ̀ lọ́wọ́ bàbá tirẹ̀. Pẹ̀lú ìtàn tí àwa bá, ìran keje tí yóó jogún oko náà ni ti bàbá mi. Oko tí wọ́n sì jogún yìí ò fi bẹ́ẹ̀ tó ǹnkan torí bí bàbá mi ti rí làwọn baba rẹ̀ náà rí, wọ́n rọ́jú bímọ rẹpẹtẹ. Bí ilẹ̀ ọ̀hún sì ṣe ń ti ọwọ́ ẹbí kan dọ́wọ́ ẹbí mì-ín ló ń dínkù sí i; nígbà térò ti pọ̀ jù lórí ẹ̀.

Púpọ̀ nínú ẹ̀ ló pàdà bá títà lọ nígbà tí ọ̀làjú wọ àdúgbò wa. Èyí tó kan ìdí igi ìya bàbá mi nìkan ló pàdà ṣẹ́kù sádùgbò náà. Òun àti àwọn ọmọ ìyá rẹ̀ ni wọ́n jọ sowọ́pọ̀ pé àwọn ò ní í pín ilẹ̀ náà kó má baà kéré lójú. Iṣẹ́ làwọn óó máa fí i ṣe. Nígbàkigbà tí èrè rẹ̀ bá sì dé, àwọn óó jọ máa pín in ní dọ́gba-n-dọ́gba ni. Mẹ́ta nínú àwọn àbúrò bàbá mi lèmi gbọ́njú bá. Bọ̀ọ̀dá Mùtáírù ti ṣaláìsí kí wọ́n tóó bi mi. Ìyàwó kan àti ọmọ méjì lòún fi sílẹ̀. Bọ̀ọ̀dá Tàfá tó jẹ́ àbúrò sí i ló ṣú ìyàwó rẹ̀ lópó, òun náà ló sì ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀ mọ́ tirẹ̀ látìgbà náà.

Kò sígbà tí mo tẹ̀lé bàbá mi lọ sóko tí kì í ṣàlàyé bí gbogbo ibi tí àwọn aráàta wáá kọ́lé sí nísìnyìí ṣe jẹ́ oko wọn nígbà kan. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọ̀làjú ò jẹ́ kíṣẹ́ oko níyì mọ́, gbogbo àwọn tó nilẹ̀ ti tà á wọ́n ti bọ́ sígboro. Èyí tó wà l’Ékòó wà l’Ékòó, àwọn tó sì kọ́rí sílẹ̀ Hausa náà ń ba wọn sọ èdè àbókí lọ́hùn-ún. Àsìkò ọdún iléyá nìkan la máa ń rí gbogbo wọ́n nílé Bàbá Baálé.

Bí gbogbo ẹbí mi bá péjú tán, àwà nìkan tóó dá odidi ìlú kan silẹ̀. Títí di bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, èmi gan-an ò mọ iye gbogbo wa tán. Mo ṣá mọ̀ pé a pọ̀ dáadáa ni.

Ògì ni ìyá mi ń sẹ́ tà ní tiẹ̀. Púpọ̀ nínú ìnáwó ilé sì ni ògì ìyá mi ń gbé torí bí a bá fi dá iṣẹ́ àgbẹ̀ baba mi nìkan ni, ǹnkan yóó ti bàjẹ́ tipẹ́. Ṣùgbọ́n kò jẹ́ tẹnu ìyá mi jáde bẹ́ẹ̀ láéláé. Ó bẹ̀ru bàbá mi kọjá “kà-a-sí-ǹnkan”.

Ṣé mo sọ fún yín nínú apá kìn-ín-ní pé èmi ni ẹlẹ́karùn-ún nínú ọmọ méje tí ìyá mi bí fún bàbá mi. Ṣùgbọ́n lọ́dọ bàbá mi, ẹlẹ́kẹjọ ni mí nínú ọmọ mẹ́tàlá tó bí. Torí ìyá mi nìkan kọ́ ló fẹ́, ó fẹ́ obìnrin mì-ín tó bímọ mẹ́fà fún un.

Pẹ̀lú bí a ti ṣe pọ̀ tó yìí, inú yàrá kan náà ni gbogbo wa kọ́kọ́ ń gbé. Lóòótọ́ yàrá ọ̀hún fẹ̀ dáadáa, ṣùgbọ́n abẹ́ òrùlé kan ni bàbá mi fẹ́ ìyàwó méjì sí. Kọ́tínnì ló fi la yàrá náà sí méjì. Yàrá ìyá kékeré la óó kọ́kọ́ kàn ká tóó ṣí kọ́tínnì wọ yàrá ìyáà mi. Ìyá tó bí mi gan-an yìí nìyàálé. Nígbà tí ìjà ojoojúmọ́ pọ̀ ni bàbá mi ṣẹ̀ tóó fi búlọ́ọ́kù yọ yàrá kan sí i fún ìyá kékeré. Mo ti ń ka ìwé kẹta kí bàbá mi tóó pín yàrá fún àwọn ìyàwó rẹ̀ yìí. Pínpín tó sì pín in náà ò pé kíjà ó parí, ó kàn yàtọ̀ díẹ̀ sígbà kan tó jẹ́ pé ilẹ̀ ọjọ́ kan ò lè ṣú kí wọ́n má lu ara wọn ni.

Ọjà oko nìyá kékeré ń tà ní tiẹ̀. Òun ló ń mójú tó èrè oko tó bá kan bàbá mi. Lára ohun tó sì ń fà ìjà lọ́pọ̀ ìgbà náà réè torí òun ló dà bìí ẹyinlójú bàbá mi. Ọkọ kẹta sì ni bàbá mi jẹ́ sí i. Ọmọ méjì ló bí fún ọkọ ààrọ̀ rẹ̀ kí wọ́n tóó kọ ara wọn sílẹ̀, ọmọ kan ṣoṣo ló bí fún ọkọ kejì kíyẹn tóó kú. Ilé bàbá mi lààyè ti gbà á dáadáa tó ríbi bímọ mẹ́fà sì. Mo rò pé torí ẹ̀ náà ni ò ṣe lè bínú lọ pẹ̀lú gbogbo ohun tóun àti ìyá mi jọ fojú ara wọn rí.

Ògì tí ìyá mi ń tà lòún gbájúmọ́ ní tiẹ̀. Gbogbo àwa ọmọ rẹ̀ náà sì la bá a tà á. N ò ju ọmọ ọdún méje lọ tí mo ti ń kiri ògì. Níbi ògì tí mò ń kiri yìí ni mo ti pàdé Ìyá Ráfẹ́ẹ́lì oníkẹ́míìsì.

Ìyá Ráfẹ́ẹ́lì ní ańgẹ́lì àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run rán sí mi lórí ilẹ̀ ayé yìí. Òun ló bẹ àwọn òbí mi pé ọmọ tó já fáfá ni mí kí wọ́n jẹ́ kí n kàwé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sówó àti rán mi níléèwé àdáni, Ìyá Ráfẹ́ẹ́lì oníkẹ́míìsì yìí ló kówó iléèwé ìjọba tí mo bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀. Iléèwé ọ̀hún náà ni mo lọ yìí tí wọ́n ti rán mi létí pé ń ò kì í ṣe ọmọ tí wọ́n bíire.

Ṣùgbọ́n ohun tí àwọn ò mọ̀ ni pé...

-----------------------------------------------------------------------

Ẹni a bí i re, kò dà bíi ẹni a tọ́ọre. Ẹni a tọ́ọre náà ò tún wáá dà bíi ẹni tó yàare.

Aríyìíkẹ́ lorúkọ mi. Èyí nìtàn ìgbésí ayé mi.👩

Post a Comment

0 Comments