Search This Blog

Bíbíire Apá Kẹta


N ò tó ẹrú ẹni tí í fẹjọ́ sun baba mi pé wọ́n pè mí lọ́mọ ìrankíran níléèwé. Ẹ̀mẹẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lòun àti àwọn àbúro rẹ̀ ṣèpàdé lórí bóyá kí wọ́n gbà fún Ìya Ráfẹ́ẹ́lì láti fi mí síléèwé ìjọba. Mo rántí bí Bọ̀ọ̀dá Tàfá ṣe ń tẹnu mọ́ ọn fún bàbá mi pé kó má gbà fún Ìyá Ráfẹ́ẹ́lì tó fẹ́ẹ́ rán mi níléèwé, ó ní bí wọ́n ṣe máa ń dọ́gbọ́n gba ọmọ lọ́wọ́ òbí ẹ̀ rèé, tí wọn yóó sì padà sọ ọ́ di Kiriyó nígbẹ̀yìn. Ó kìlọ̀ fún bàbá mi pé n ò ní í gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu lọ́jọ́ iwájú.

Bọ̀ọ̀dá Ràímì ò pé iléèwé òyìnbó ò dáa ní tiẹ̀, àmọ̀ràn tóun ń gba baba mi ni pé kí wọ́n sọ fún Ìyá Ráfẹ́ẹ́lì pé bí yóó bá rán ọmọ rẹ̀ níléèwé, Sàíídì tó jẹ́ àkọ́bí ìyá mi lọ́kùnrin ni kó rán lọ. Gbogbo owó tí wọ́n bá ná lórí emi tí mo jẹ́ ọmọ obìnrin yìí, ilé ọkọ mi ni n óó padà fi àdàgbá ètò rẹ̀ rọ̀ sí. Bọ̀ọ̀dá Tájù ló ní ọ̀rọ̀ ọ̀hún ò mọ́gbọ́n wá, bí wọ́n bá fẹ́ kí wọ́n rán mi níléèwé ni kí wọ́n jẹ́ kí wọ́n rán mi, bí wọn ò bá sì fẹ́ ni kí wọ́n sọ fóbìnrin náà. Kò bójú mu kí wọ́n máa wáá là lé ẹni tó fẹ́ẹ́ bá wọn ránmọ níléèwé pé irú ọmọ kan ni kó rán, irú ọmọ kan ni kó má rán pàápàá nígbà tó jẹ́ pé gbogbo ọmọ kọ́ ni orí ẹ̀ gbé ìwé.

Láàárín wọn kúkú lèmi àti ìyá mi wà tí wọ́n fi ń sọ gbogbo èyí, kò sẹ́ni tó le dún “o” nínú àwa méjèèjì. Ọlọ́run nìkan ló mọ bó ṣe kó sí wọn nínú tí wọ́n fi padà fẹnu kò níbi ìpàdé kẹta pé kí wọ́n gbà fún mi láti lọ síléèwé. Èmi àti ìyá mi ò sí nípàdé ọ̀hún, a ò mọhun tí wọ́n sọ níbẹ̀ tí wọ́n fi fẹnu kò pé kí wọ́n gbà fún Ìyá Ráfẹ́ẹ́lì láti rán mi nílééwè. Ṣe mo wáá tún le lọọ bá Bàbá mi pé wọ́n pè mí lọ́mọ tí wọn ò bíire níléèwé yìí? Yóó ní ohun tí àwọn àbúrò òun sọ ń ṣẹ bọ̀ nù un, wọ́n ti fẹ́ẹ́ máa kọ́ ọmọ òun sóun, ó le torí ẹ̀ yọ mi níléèwé. 

Ìyá mi ló ṣàkíèsí pé mò ń ká gúọ́gúọ́ kiri látìgbà tí mo ti tiléèwé dé, nígbà tó sì bèèrè n ò mọ̀gbà tí mo ṣàlàyé ọ̀rọ̀ burúkú tí wọ́n fi rán mi sílé fún un. Mo rí i lójú ìyá mi pàápàá pé ọ̀rọ̀ tí mo sọ bà á nínú jẹ́, ó kàn fi ọgbọ́n gbé e kúrò lára mi pé kí n má wobẹ̀ ni. Ó ní, “Má dá a lóhùn jàre. Òun tí ì rọ́la ná tó ń pe ọmọ ẹnì kan lọ́mọ tí wọn ò bíire. B’Ọ́lọ́run bá sì bẹ̀rẹ̀ si í fìyà jẹ irú wọn, àwọn èèyàn óó máa bá wọn káànú, wọn ò ní í mọ ohun tí wọ́n ṣe. Gbé ọ̀rọ rẹ̀ kúrò lọ́kàn, Ọlọ́run óó dá a lẹ́jọ́ tó tọ́ sí i. Dáákun jára mọ́ ewedú tó ǹ tọ́, kó o le tètè lọ̀ọ̀ bá Ìya Ráfẹ́ẹ́lì ní ṣọ́ọ́bù fún lẹ́sínǹnì yín. Má jẹ́ kẹ́lẹ́nu burúkú fẹnu bèèpẹ̀ sí gààrí rẹ.”

Lóòótọ́ ni, mo ṣì ń lọ sọ́dọ̀ Ìyá Ráfẹ́ẹ́lì fún lẹ́sínǹnì. Aago mẹ́rin sáago mẹ́fà ni mo máa ń lọ lọ́jọ́ iṣẹ́, ọjọ́ Sátidé nìkan ni mo máa ń lọ laago mẹ́wàá ààrọ̀ sáago méjì ọ̀sán. Èmi àti Ráfẹ́ẹ́lì náà ló máa ń dá kọ́ nínú ṣọ́ọ́bu rẹ̀ o, kì í ṣe pé ó nílé lẹ́sínǹnì tó ti ń ṣiṣẹ́ tíṣà. Ọmọ rẹ̀ nìkan ló kúkú ń dá kọ́ láàrọ̀ ọjọ Sátidé kan tí mo kiri ògì lọ sọ́dọ rẹ̀, níbi tó ti ń kanra mọ́ ọn pé kó pe ọ̀rọ̀ onísílébù mẹ́ta papọ̀ tíyẹn ò rí i pè ni mo ti pè é láì jẹ́ pé mo lọ iléèwé rí “Fẹ-dẹ-ra-lí (Federal)”. Bó ṣe gbọ́ tí mo pè é ló sáré wẹ̀gbẹ́ pé ṣe ọmọ ìyá ológì tí kò déléèwé rí ló kàwé tọ́mọ òun ò le kà yìí? Láti ọjọ́ náà ló ti gbé ọ̀rọ̀ mi sórí bíì pé nǹkan mì-ín wà níbẹ̀. Títí tó fi délé wa, tó sì fi gba àṣẹ àwọn òbí mi láti fi mí síléèwé.

Látìgba yìí kan náà ló ti ń kọ́ èmi àti ọmọ rẹ̀ ní lẹ́sínǹnì. Kò sì sígbà tí n óó lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ tí inú mi kì í dùn lọ, torí yàtọ̀ sí ẹ̀kọ́ ìwé tí n ò lè rí kọ́ nílé wa tó wà níbẹ̀, oúnjẹ tí n ò lè rí jẹ nílé wà ń bẹ níbẹ̀ tí Ìyá Ráfẹ́ẹ́lì kì í fi í dùn mí. Bí ọba ni Ìyá Ráfẹ́ẹ́lì ṣe ń dáná. Ẹran tó jẹ́ pé ọjọ́ ọdún iléyá nìkan ni wọ́n máa ń fún wa jẹ nítorí kí wọ́n má “bà wá jẹ́”, àrìnnàpàdé lo ó máa kò wọ́n nínú ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ tí Ìyá Ráfẹ̀ẹ̀lì bá gbé fún mi, níbi tí tinú-ẹran àtedé óó ti máa bèèrè ikú tó pa ara wọn lórí ẹ̀bà elépo rẹ́súrẹ́sú to korí bẹ̀fọ̀ọ́. Kò sọ́jọ́ tí mo kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ tí n ò kí í wọ̀nà de ọ̀sán ọjọ́ kejì tàbí àárọ̀ ọjọ́ Sátidé tí n óó tún lọ. Tẹ̀rín-tọ̀yàyà ni mo fi máa ń pàdé ẹ̀.

Ṣùgbọ́n lọ́jọ́ yìí, inú mi ò dùn - oun náà sì ṣàkíyèsí. Mo jẹun lóòótọ́ kò lọ lẹ́nu mi, ó kọ́ mi níwèé kò wọrí. Nígbà tó wáá kù díẹ̀ káago mẹ́fà lù ló ní kí n pàwé dé. Ó bèèrè lọ́wọ́ mi pé kí ló ṣẹlẹ̀, mo ní kò sí nǹkan kan. Ó ní ṣé mọ́tò ti padà pa ológbò Bàámi ni? Mo rọra rẹ́rìn-ín díẹ̀. Ta-ń-tọ́lọ́hun ló ń bèèrè un, abàmi ológbò tí í jògì tútú. Ó mọ̀ pé èmi àti ológbò yìí ò gba tara wa, mo ti ròyìn bí mo ti ṣe fẹ́ẹ́ pa á tipẹ̀ tó jẹ́ pé ẹ̀ru Bàámi ló ń bà mí fún un. Mo ní kò sóhun tó ṣe Tańtọ́lọ́hun. Obìnrin yìí ṣá lọ́ mi nífun títí tí mo fi sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún un, mo ní, “Tíṣá wa ní wọn ò bí mi ire!”

Ó fara balẹ̀ gbọ́ bí ọ̀rọ̀ ọ̀hún ṣe ṣẹlẹ̀ àti bó ṣe di pé wọ́n pè mí lọ́mọ aláìníran. Ó bá mi wí pé ọ̀rọ̀ burúkú lèmi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi náà fi ń ṣere, ṣé èmi náà rí i bó ṣe dùn mí nígbà tí wọ́n fi bú mi. “A ò mọ̀. A ò mọ̀ pé kò dáa! A ò mọ!”

Kí n tóó sọ̀rọ̀ yìí délẹ̀ ni omi ti ń bọ́ lójú mi. Ìya Ráfẹ́ẹ́lì fà mí mọ́ra, ó sì dì mọ́ mi gbágbáágbá. Orí àyà rẹ̀ ni mo ń sunkún sí. Gbogbo tí mò ń sunkún yìí kò fi mí sílẹ̀, ó rọra rẹ̀ mí lẹ́kún kó tóó bẹ̀rẹ̀ si í sọ̀rọ̀ ìtùnú fún mi. Ó ní, “Aríyìíkẹ́! Ọmọ àrà ọ̀tọ̀ ni ẹ. Ṣé ìwọ náà ò rí i pé o gbọ́n ju ọjọ́ orí ẹ lọ ni. Èwo nínú àwọn ẹgbẹ́ ẹ ló máa ń ronú bí ìwọ̀ ṣe ń ronú. Nígbà mì-ín tó o bá ń bá mi sọ̀rọ̀ báyìí, mo máa ń rò pé àgbàlàgbà kan ni mò ń bá rojọ́ ni. Lọ́jọ́ wo ló débí tó o bá ọ̀rẹ́ kankan níbí? O ò lè bá ọ̀rẹ́ kankan níbí torí ìwọ nìkan lọ̀rẹ́ mi. Tẹ́nì kan bá wáá sọ fún ẹ pé wọn ò bí ẹ dáadáa, sọ fún un pé irọ́ ló pa - ẹnu ẹ̀ ń rùn. Torí ọmọ oníyàá méjì nìwọ. Ìwọ lọmọ Ìyá Àríkẹ́ Ológì – Ìwọ tún lọmọ Ìyá Ráfẹ́ẹ́lì Oníkẹ́míìsì. Ìyá méjì ò dẹ̀ lè bíìyàn kí wọ́n má bí i dáadáa. Nu ojú ẹ nù jọ̀ọ́, Àríkẹ́ ọmọ oníyàá méjì! O dẹ̀ mọ̀ pé mi ò láìkì kí n máa rómi lójú ẹ.” Bí mo ṣe gbọ́ bẹ́ẹ̀ ni bú sẹ́rìn-ín. Ara mi sì fúyẹ́ bíi ìgba téèyàn bá gbé nǹkan wúwo kúrò lára mi. Mo ní, “Ìyá Ráfẹ́ẹ́lì, ẹ̀yin àti mi-dẹ̀-mi-dẹ̀ Èkó yín yìí.”

Bí a ṣe fi ẹ̀rín kásẹ̀ ọ̀rọ̀ yìí lọ́dọ̀ Ìyá Ráfẹ́ẹ́lì rèé tí mo fi padà sílé, àṣé kò tí ì tán nínú obìnrin yẹn. Áàh! Sintín-ń-gbọ́ tọ́ọ́gì ni Ìyá Ráfẹ́ẹ́lì. 

Post a Comment

0 Comments