Ṣùgbọ́n ta lèèyàn dúdú ṣẹ̀ gan-an tí ò dáríjì wá?
Orílẹ̀-èdè kan ń bẹ lórílẹ̀ ayé yìí tá à ń pè ní Greece. Gírísì tá à fi ń para kọ́ o. Orílẹ̀-èdè tó ti pẹ́ dáadáa nínú ìtàn, tó sì tún ṣe bẹ́ẹ̀ gbajúmọ̀ là ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí, àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè yìí sì là ń pè ní Greek.
Ohun méjì ló tinú Greece jáde tó mú kó gbajúmọ̀ tó bẹ́ẹ̀ lágbàáyé, àkọ́kọ́ ni ètò ìjọba aráàlú táwọn olóyìnbó ń pè ní Democracy. Ìkejì sì ni ẹ̀kọ́ ìlànà ìṣàfikún-ọgbọ́n-ẹni táwọ́n olóyìnbó ń pè ní Philosophy.
Inú ìpínlẹ̀ Greece tí wọ́n ń pè ní Athens làwọn òpìtàn lágbàáyé gbàgbọ́ pé dẹ̀mókírésì ti bẹ̀rẹ̀ ní nǹkan bíi ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún ṣáájú kí wọ́n tóó bí Jésù, ọmọ orílẹ̀-èdè Greece tí wọ́n sì ń pè ní Socrates ni ìwé ìtàn sọ fún wa pé ó ṣàgbékalẹ̀ ẹ̀kọ́ ìlànà ìṣàfikún-ọgbọ́n-ẹni, Bàbá Philosophy ni wọ́n ń pè é. Ọkùnrin yìí ni Ìyá wa tó ti dẹni àná lónì-ín, Professor Sophie Olúwọlé, pè ní Ọ̀rúnmìlà àwọn òyìnbó lẹ́yìn ìwádìí àti àgbéyẹ̀wò bí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ rẹ̀ ṣe jọra pẹ̀lú ti Ọ̀rúnmìlà nílẹ̀ Yorùbá. Èyí ni pé ká ní àwọn baba wa náà ń kọ àkọọlẹ̀ ni, a óó le sọ fáyé pé ọ̀dọ̀ Socrates kọ́ ni ẹ̀kọ́ ìlànà ìṣàfikún-ọgbọ́n-ẹni ti wá sọ́dọ wa o, kóyìnbó tóó dé làwa ti ń kẹ́kọ̀ọ́ àròjinlẹ̀. Ọ̀rọ̀ ọjọ́ mì-ín lèyí-un.
Ohun tí mo fẹ́ẹ́ fà yọ nínú dẹ̀mókírésì àti Fìlọ́sọ́fì tí mo mẹ́nu bà ni pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè kan náà làwọn méjèèjì ti wá, síbẹ̀ ìpàkọ́ làwọn méjèèjì kọ síra wọn — wọn ò gba tara wọn.
Ẹ ò ní kín nìdìí? Ètò Dẹmókírésì ń sọ pé gbogbo ọmọ ìlú ló gbọ́dọ̀ lẹ́nu láti sọ pé irú ẹni báyìí ló yẹ kó ṣe adarí ìlú, gbogbo òfin yòówù tí ìlú yóó bá sì ṣe, gbogbo ọmọ ìlú gbọdọ̀ mọ̀ nípa ẹ̀ kí wọ́n sì fọwọ́ sí i kó tóó le wá sí ìmúṣẹ. Kò sí aráàlú tí yóó gbọ́ èyí tí inú ẹ̀ ò ní í dùn. Èyí ni pé ẹnì kan ò ní í pe ara rẹ̀ lọ́ba kó kàn déédé ní iye kan ni kí gbogbo ọmọ ìlú óó máa san lówó-orí tàbí kó ní ìlú kan ṣẹ ìyáláyàá òun ki gbogbo ọmọ ìlú dìhá mọ́ra ogun lọọ kú fóun níbẹ̀. Báwọn ọmọ onílùú ò bá ti fọwọ́ sí i, àbá lásan lọba ọ̀hún dá sápò ara rẹ̀ kò pàṣẹ. Ṣé ẹ̀yin náà ò rí i pé ó dáa bẹ́ẹ̀? Nígbà tí nǹkan wáá dáa tó tó báyìí, kí ló dé tí ọgbọ́n àròjinlẹ̀ ń ta kò ó.
Socrates sọ̀rọ̀ kan nípa Dẹ̀mókírésì tí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ kọ sílẹ̀, ó bèèrè lọ́wọ́ ẹnì kan pé bó bá wà lórí ọkọ̀ ojú omi tó ń lọ lórí òkun tó jẹ́ pé ṣàṣà lọkọ̀ ojú omi tí kì í tẹ̀ rì, ta ni yóó fẹ́ kó yan ẹni tí yóó darí ọkọ̀ ojú omi yìí fóun, ṣé gbogbo èrò inú ọkọ̀ ni tàbí ìwọ̀nba àwọn tó nímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ọkọ̀ ojú omi wíwà àti oríṣìíríṣìí ìṣòro téèyàn le fojú kò lórí agbami yìí. Ìgbà tónítọ̀hún yóó dáhùn, ó ní àwọn tó nímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ọkọ̀ ojú omi lòun óó yàn dípò èrò tí ò mọ irú ìṣòro téèyàn ń fojú kò lórí omi àti ẹni tó le káátò fún iṣẹ́ náà. Socrates wáá ní nígbà tá a mọ̀ pé ẹni tó bá nímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ọkọ̀ wíwà àti ojú ọ̀nà tọ́kọ̀ ń lọ ló yẹ kó le dìbò yan ẹni tó kúnjú òṣùwọ̀n láti jẹ́ dẹ́rẹ́bà ọkọ̀, báwo la ṣe wáá rò ó pé irú wá ògìrì wá ló yẹ kó máa dìbò yan ẹni tí yóó darí ìlú tí ìlú ò ní í bàjẹ́?
Socrates ní ká wo ètò Dẹmókírésì bí ìdíje láàárín dókítà alábẹ́rẹ́ àti oníṣòwò tó ń ta ohun dídùn, ká wáá ní káwọn méjèèjì sọ fáráàlù ẹni tó yẹ kí wọ́n tẹ̀lé. Ó ní nígbà tí onísúìtì bá ń ní “ẹ wo ìsọ̀ mi, kìkìdá ohun dídùn ni mo kó dé. Gbogbo ohun tẹ́ ẹ bá fẹ́ nínú ẹ lẹ le mú jẹ, n ò ní í dì yín lọ́wọ́ mú bíi dókítà tí yóó ní kẹ́ ẹ má fowó yín jẹ ohun tó wù yín. Tó jẹ́ pé kò sóhun tó kó sígbá bí kò ṣe àwọn àgbo kíkorò àti abẹ́rẹ́ oró tí ò ní í jẹ́ kẹ́ le rídìí fi lélẹ̀ lọ́jọ́ mẹ́tà.” Nígbà tí dókítà óó bá sì sọ̀rọ̀ gbe ara rẹ̀ lẹ́yìn, tó ní “gbogbo ohun tó korò àti ìwà ìkà tí olódì mi ní n óó ṣe fún yín yìí, lóòótọ́ ni n óó ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n nítorí ànfààní ara yín ni gbogbo ohun tó jọ ìwà ìkà yìí. Ẹ̀yin ẹ jẹ́ n kí n gún yín lábẹ́rẹ́ wò ná, kẹ́ sì da ọ̀kan nínú àwọn àgbo kíkorò mi sọ́fun. Ẹ óó rí i pé yóó wúlò fún yín lọ́jọ́ iwájú.”
Socrates bèèrè pé bí wọ́n bá ni kí àwọn aráàlú dìbò pé ta ló yẹ kó dúró láàárín ìlú, ta sì ló yẹ kí wọ́n lé dànù sígbẹ̀ẹ́ kó lọ máa bọ́mọ ẹranko ṣe — ta la rò pé yóó dúró láàárín ìlú nínú àwọn méjèèjì yìí bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn yóó padà kábàámọ̀ ìpinnu wọn nígbẹ̀yìn?
Àṣe ara ló ń rò fún Socrates fúnra ẹ̀ pé ohun tí yóó padà ṣẹlẹ̀ sí i lọ́jọ́ iwájú rèé, tórí àwọn aráàlú padà pè é lẹ́jọ́ pé ó ń kọ́ àwọn ọmọ àwọn níkọ̀ọ́kúkọ̀ọ́, ó ń ṣe bíi ẹni pé òun nìkan lòun gbọ́n tán. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bàbá yìí ò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án lẹ́ni àádọ́rin ọdún, tó jẹ́ pé bí wọ́n pa á – bí wọn ò pa á, ọjọ́ ikú ẹ̀ ti ń kànkùn tẹ́lẹ̀. Síbẹ̀ àwọn aráàlú dìbò lórí ẹjọ́ ẹ̀ — àwọn tó fẹ́ kó kú sì pọ̀ ju àwọn tí ò fẹ́ kó kú lọ. Ni wọ́n bá fi ọ̀jọ̀gbọ́n ìlú ṣètùtù fáwọn tó ń bínú ẹ̀ kínú wọn le rọ̀ ní nǹkan bíi ọdún mọ́kàndínnírínwó ṣáájú ọjọ́ tá a bí Jésù ọmọ Màríà. Lóòótọ́ wọ́n padà kábàámọ́ o, ṣùgbọ́n wọ́n ti fi ẹgọ̀ wọn pa ọgbọ́n ìlú nígbà tí agbára wà lọ́wọ́ wọn tí wọn ò sì ní làákàyè bó ṣe yẹ kí wọ́n lò ó.
Lọ́dun 2023 yìí ló pé 2422 yias tí Socrates ti kú, títí dòní sì là ń gbọ́ orúkọ rẹ̀ káàkiri ayé. O ò lè di Lọ́yà nílẹ̀ yìí láì gba ara Socrates kọjá, àwa tó jẹ́ pé ìmọ̀ nípa ìbọ́pọ̀-èrò-sọ̀rọ̀ la lọọ kọ́ níléèwé pàápàá ní láti kàn án nígbà tá a dé ìpele kan nínú ẹ̀kọ́ wa.
Ẹ wáá gbọ́ o, Socrates ò ní kí aráàlú má lẹ́nu níbi ètò òṣèlú o, ohun tí ọ̀jọ̀gbọ́n náà ń sọ ni pé aráàlú tí yóó bá dá sétò òṣèlú gbọdọ̀ nímọ̀ tó kúnná nípa ètò òṣèlú orílẹ̀-ède rẹ̀ kó má jẹ́ pé ìpinnu tí yóó ṣàkóbá fún orílẹ̀-èdè rẹ̀ ni yóó fi àìmọ̀kan dìbò yàn.
Ǹjẹ́ bí àwọn Bìrìtìkó tó mú wa sìn bá mọ èyí láti ọdún tí Socrates ti kú, tí wọ́n mọ̀ pé ètò òṣèlú Dẹmókírésì ò pé láì jẹ́ pé àwọn aráàlú tí yóó dìbò ní ẹ̀kọ́ tó jinlẹ̀ nípa òṣèlú — kín ni wọ́n gbéjọba Dẹmókírésì fún wa pẹ̀lú èdè abínibí tiwọn fún? Ṣé èdè elédè làwọn fi ń ṣe Dẹmókírésì lọ́dọ̀ wọn tó fi ń jẹ́ fún wọn?
Ṣáájú kí wọ́n tóó dé àárín wa la ti ní ètò òṣèlú tá a mọwọ́ ẹ̀ láàárín ara wa. Bí n ò mọ ti gbogbo èèyàn, mo mọ ti ẹ̀yà Yorùbá tó jẹ́ ẹ̀yà mi níwọ̀nba. Kí wọ́n tóó fi ẹni kan jẹ Aláàfin, ó láwọn nǹkan kan tó gbọ́dọ̀ wá láti ilé-ifẹ̀ kí àwọn aráàlú tóó gba onítọ̀hún l’Álàáfin. Ọdọọdún ni Baṣọ̀run Ọ̀yọ́ ń ṣọdún Ọ̀run, ìgbàgbọ́ gbogbo aráàlú ni pé ó fẹ́ẹ́ lọọ bá àwọn Aláàfin àná sọ̀rọ̀ bóyá wọ́n ṣì ń gbádùn ìjọba Aláàfin tó wà lórí oyè tàbí èyí tó ṣe láyé tó kó forí oyè sílẹ̀ fún ọmọọba mì-ín tó tún le ṣèlú ju tirẹ̀ lọ.
Baba ta ló lọ sọ́run tó bọ̀ rí, ta ni ò mọ̀ pé wọ́n kàn ń ṣe èyí láti fi rí i dájú pé Aláàfin ò sọra rẹ̀ dòòṣà mọ́ àwọn ìjòye rẹ̀ lọ́wọ́ ni. Bí àwọn ìjòyè fúnra wọn bá sì bẹ̀rẹ̀ si í kọjá ààyè, a gbọ́ ohun táwọn aráàlú fúnra wọn ń ṣe fún irú wọn. Bẹ́ ò tiẹ̀ gbọ́ gbogbo ẹ̀, ẹ ṣáà gbọ́ nípa Baṣọ̀run Gáà?
Nílẹ̀ Yorùbá yìí, èmi rí i kà nínú ìtàn pé bí Yorùbá bá jagun kó ìlú kan, bí wọ́n bá pa gbogbo èèyàn tí wọ́n kó gbogbo aráàlú lẹ́rú, wọn ò ní í pa ọba ìbẹ̀. Fúnra ọba ni yóó wọlé ṣe bíi ọkùnrin pé ayé òun bájẹ̀, ohun táwọn baba ńlá òun tọ́jú pamọ sóun lọ́wọ́ bàjẹ́ lójú ẹ̀mí òun.
Ṣàṣà lọmọ Yorùbá tó mọ èyí lóde òní, torí ohun tí wọ́n fi kọ́ wa ni pé gbogbo ohun táwọn baba wa ṣe ní ò dáa rárá. Gbogbo ìwa wọn nìwà ẹni ojú ẹ̀ dúdú tí ò róde.
Ó dáa, à gbà bẹ́ẹ̀. Ètò òṣèlú ìgbàlódé tẹ́yìn sì fẹ́ẹ́ kọ́ wá yìí báwo la óó ṣe lò ó, ẹ ní ìwé òfin ni yóó máa darí ìgbésí ayé tolórí-tẹlẹ́mù nínú ètò ìṣèjọba yìí. Ìwé òfin ọ̀hún sì rèé, èdè yín la óó fi kọ ọ́ kalẹ̀. Ìyẹn ni pé bá a bá fẹ́ẹ́ lò ètò ìṣèjọba yìí, gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè wa gbọdọ̀ kọ́kọ́ kọ́ èdè yín ná ká tóó le lò ó. Lóhun tó jẹ́ pé àwọn baba yín pàápàá fìdìí ẹ̀ múlẹ̀ pé lórílẹ̀-èdè yòówù tí wọ́n bá ti fẹ́ẹ́ lo ètò yìí, dandan ni kí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè ọ̀hún nímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa òṣèlú orílẹ̀-èdè wọn. Wàhálà tẹ́ ẹ dà sí wa lágbada wáá pín sípele méjì, ọ̀tọ̀ ni wàhálà ẹ̀kọ́ èdè elédè tá óó kọ́kọ́ kàn ká tóó wọnú òṣèlú orílẹ̀-èdè wa, ọ̀tọ̀ sì ni ẹ̀kọ́ òṣèlú fúnra rẹ̀ tó lọ́jú gidi fẹ́ní tí ò bá ní làákàyè tó kúnná àti àròjinlẹ̀.
Ọ̀rọ̀ ọ̀hún dà bíi ọ̀rọ̀ ẹni tó jẹ́ pé abẹ́rẹ́ àti òwú ló mọ̀ ọ́n fi ránṣọ láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé ẹ̀. Télọ̀ kan wáá sọ fún un pé kó sọ òwú àtabẹ́rẹ́ rẹ̀ nù, òun óó fi maṣíìnì ńlá kan tí wọ́n ń pè ní Industrial ránṣẹ́ sí i. Ìgbà tí maṣíìnì óó de tí télọ̀ alábẹ́rẹ́ àtòwú bèèrè pé báwo lòun óó ṣe lò ó, wọ́n ní kó yẹ̀wé tó bá a wá wò, gbogbo àlàyé bí yóó ṣe lò ó, àwọn ibi tó yẹ kó fọwọ́ kàn tí yóó fi jẹ́ fún un àti ibi tí ò yẹ kó fọwọ́ kàn tó le ṣe é níjàmbá ni wọ́n ti kọ síbẹ̀. Ìgbà tá óó ṣíwèé ọ̀hún, èdè ṣìnkó ni wọ́n kọ sí i. Wọ́n ní kí télọ̀ alábẹ́rẹ́ kọ́kọ́ lọọ kọ́ èdè ṣinkó kó ṣẹ̀ṣẹ̀ tóó kọ́ bí yóó ṣe lo ẹ̀rọ tuntun yìí. Nígbà wo lebi ò ní í pa á kú síbi tó ti ń kọ́ èdè elédè tó jẹ lẹ́yìn rẹ̀ ni yóó ṣẹ̀ tóó kọ́ lílò maṣínnì tí yóó fi jẹun?
Wọ́n wáá yọ àsíá wọn kúrò lójú òpò wọ́n ní ká fi tiwa sí i, àwọn fún wa lómìnira bó bá ṣe wù wá ni ká ṣèlú. Ṣùgbọ́n bá a bá fẹ́ẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ ó ṣe pàtàkì láti gbàgbọ́ nínú ọkàn wa pé a gbọdọ̀ múra bí àwọn, a gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ bí àwọn, a gbọdọ̀ hùwà bí àwọn ká tóó le ṣe ohunkóhun nílẹ̀ wa. Bẹ́ẹ̀ a sì ti gbòmìnira
Àwọn Bìrìtìkó nìkan kọ́ ló ṣèyí ó. Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ làwọn Faransé náà ṣe láwọn orílẹ̀-èdè Áfríkà tí wọ́n mú sìn rí, bẹ́ẹ̀ wọ́n sì fún wọn lómìnira àti ìjọba dẹ̀mókírésì pé kí wọ́n ṣe bó ṣe wù wọ́n. Ìyẹn bí wọ́n bá ti ṣetán láti di fọtokọ́pì àwọn ọ̀gá tó fún wọn lómìnira.
Nígbà tá a bá wáá ń kojú ìṣòro níbi ètò òṣèlú wa, nígbà tí aráàlú ò bá mọ ọ̀nà tó le gbà ran olóṣèlú lọ́wọ́ láti sún orílẹ̀-èdè rẹ̀ síwájú, nígbà tí olóṣèlú bá bẹ̀rẹ̀ sí í wo aráàlú bí ọ̀tá tó jẹ́ pé ojoojúmọ́ ni wọ́n ń wá ìṣubú òun nítorí ayé òun dáa ju tiwọn, nígbà tí àwọn tó yẹ ká máa wò bíi ọlọ́gbọ́n tó wà nílùú bá bẹ̀rẹ̀ sí í lo làákàyè wọn fi bẹnu àtẹ́ lu olóṣèlú tó wà lórí oyè kí aráàlú tí kò láròjinlẹ̀ tó wọn le fi wọ́n rọ́pò níbi tí wọn ò ti ní í fara gbá ìjàmbá tó ń jẹyọ látara ìjákulẹ̀ àìríjọba ṣe olóṣèlú tó wà lórí oyè, tí àwọn ọmọ adúláwọ̀ ń kú sínú omi àti orí ọ̀gbẹlẹ̀ láti sá fún ìṣòro orílẹ̀-èdè wọn, tí àwọn ọmọ onílùú tíjọba wà lọ́wọ́ ẹ̀ ń pariwo pé kí sójà tí wọ́n gbà síṣẹ́ aṣọ́bodè wáá gbàjọba ìlú lọ́wọ́ àwọn — àwọn orílẹ̀-èdè tó kù lágbàáyé óó máa wáá sọ láàárín ara wọn pé “ẹ wo bí àwọn ọmọ adúláwọ̀ ṣe ń ṣe ara wọn lẹ́yìn tí wọ́n gbòmìnira, ṣebí ẹ rí i pé àwọn fúnra wọn ni wọ́n ń bèèrè báyìí pé kí ọmọọ̀yá wọn tí ìbọn wà lọ́wọ́ ẹ̀ ki okùn bọ àwọn lọ́rùn kó máa wọ́ àwọn lọ síbikíbi tó bá wù ú, àwọn ò fẹ́ẹ́ dìbò yan aṣáájú mọ. Ṣé àwọn tó mú wọn sìn wáá jẹ̀bi nígbà tó jẹ́ pé àwọn èèyàn yìí pàápàá fẹ́ràn ìdè ju òmìnira lọ.” Láì mọ́ pé àgbákò táwọn tó mú wa sìn gbé lé wa lọ́wọ́ la ṣì ń bá pò ó títí dòní.
Lónì-ín, a wáá ń gbọ́ lẹ́nu ọmọ adúláwọ̀ tó ń lénu fatafata pé kí ológun gbàjọba lọ́wọ́ olóṣèlú, kò mọ̀ pé ohun tóun ń sọ ni pé kólógun gbàjọba lọ́wọ́ òun, òótọ́ lọ̀rọ̀ Socrates, làákàyè òun ò gbétò òsèlú débi pé òun yóó máa dá sí bó ṣe yẹ kí ìlú lọ.
Ìwọ̀nba sì la lè dá a lẹ́bi mọ, nígbà tó jẹ́ pé Bíbélì ni wọ́n tú sí èdè abínibí rẹ̀ wọn ò tú kọnstitúṣàn. Ó ṣe pàtàkì kí bíbélì wà lédè àbínibí wa kó le yé àwọn baba wa tí wọ́n kọ́kọ́ fi ẹ̀sìn yìí lọ̀, ṣùgbọ́n tó bá di pé a fẹ́ẹ́ kọ́ ìmọ̀ tí a óó fi ṣèlú, ìmọ̀ tí a óó fi gbé nǹkan rere ṣe nínú ayé, a gbọdọ̀ kọ́kọ́ kọ́ èdè wọn kí ìmọ̀ ọ̀hún tóó le yé wa? Àwa ń kọ́ èdè, àwọn ń kọ́ ìmọ̀, a wáá ń bèèrè pé kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè Áfríkà ò ṣẹ̀dá nǹkan tuntun fáyé àfi kí wọ́n máa kówó ra ohun tó ń ti ilẹ̀ òkèèrè wá? Àwọn tá à bá tún wò lọ́jọ̀gbọ́n, ìkókúkòó tí wọ́n ti kó sí wọn lórí láti kékeré ò jẹ́ kí wọ́n le fojú ire wo ara wọn. Ẹ óó máa gbọ́rọ̀kọ́rọ̀ lẹ́nu wọn bíi “èèyàn dúdú ojú ẹ̀ dúdú, èèyàn dúdú inú ẹ̀ dúdú, èèyàn dúdú ọpọlọ ẹ̀ dúdú,” ẹ dáákun – ta ló kun ọpọlọ orí ẹ̀ lọ́dà láti iléèwé Jẹ́léósìnmi?
Bí wọ́n bá ní ohun témi ń sọ yìí kọ́ nìṣòrò wa, àwọn olóṣèlú wa kàn ya ìkà àti ọ̀dájú ni ò jẹ́ ká láṣeyọrí níbi ètò òṣèlú, làákàyè tí Ọlọ́run sì dá sórí àwọn òyìnbó dáa ju ti ọmọ èèyàn dúdú lọ.
Ẹ ní kí wọ́n lọ sí Europe pé a fẹ́ẹ́ ṣèdánwò kékeré kan láti fìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀, kí ìjọba wọn ṣe òfin tuntun pé látì ìsìnyìí lọ, èdè Yorùbá ni wọn yóó máa sọ nílé ìjọba àti níléèwé England. Ìwé òfin ìṣẹ̀dálẹ̀ orílẹ̀-èdè wọn pàápàá, àwọn olóṣèlú ṣetán láti tún un kọ pẹ̀lú àwọn àyípadà oríṣìíríṣìí, èdè Yorùbá sì ni wọn yóó fi kọ ọ́. Ẹnikẹ́ni tí ò bá ti gbọ́ èdè Yorùbá nínú àwọn olóṣèlú àti aráàlú gbọdọ̀ tètè lọọ kọ́ ọ, torí President ò jẹ́ President mọ́ o, Aláàfin la óó máa pè é, Prime Minister la óó máa pè ní Baṣọ̀run. Kí la óó wáá máa pe àwọn Senator, Ìwàrẹ̀fà mẹ́fà tí kì í jẹ́ káwo ó bàjẹ́. Kí ló ń jẹ́ Media? Àní ẹ máa pè wọ́n ní Àyàngalú, ọmọ òfi-kọ̀ǹgọ́ ìlù bókùú Ewúrẹ́ wí kó máa fọhùn bíi èèyàn, tàbí kẹ́ máa pè wọ́n léégún aláre, abi-kókó-létí aṣọ.
Ṣé ẹ wáá rí àdìpọ̀ aṣọ tí wọ́n ń wọ̀ bí àlùbọ́sà ní Europe yìí ò yẹ ọ̀jọ̀gbọ́n o. Ká bẹ̀rẹ̀ ètò tí yóó mú wọn rí súútù wíwọ̀ bíi ìmúra ará oko. Kó di pé bí wọ́n bá fẹ́ẹ́ fi hàn pé àwọn lajú ní Europe, aṣọ dàńṣíkí àti kẹ̀m̀bẹ̀ ni kí wọ́n máa wọ̀ káàkiri. Bí òtútú ilẹ̀ wọn bá wáá fẹ́ẹ́ gbọ̀n wọ́n létè dànù, kí wọ́n má mikàn. Àwọn alágbẹ̀dẹ̀ Áfríkà ń bọ̀ wáá ta éńjínnì tí yóó máa bá wa wì wọ́n láàyè bí ẹran súnsun, kí inú yàrá wọn le dà bí ìgbà tí wọ́n wà l’Áfríkà níbi tóòrùn ti ń mú. Gbogbo ibi tí wọ́n bá ń lọ ni kí wọ́n máa mú irinṣẹ́ adóorupani yìí lọ wọn ò gbọdọ̀ wọ súùtù, aṣọ wa fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ ni kí wọ́n máa wọ̀ káàkiri. Bó ṣe inú ilé, bó ṣe inú ọkọ̀ — irinṣẹ́ ayanran yìí ni kí wọ́n máa gbé kiri bí ẹran àsun láì tí ì kú.
Kí ọmọ England sọ Yorùbá sí ọmọ England ẹgbẹ́ ẹ̀ kíyẹn ní, “I don’t speak Yoruba”, káwọn ọmọ England tó wà nítòsí gbẹ́rìn-ín àrínlamilójú! Kí ọmọ England ẹgbẹ́ ẹ̀ máa sọ fún un pé, “Iwọ ko gbọ édé Yoruba. Edé awọn ọjọbvhọn layé. Edé awọn ogo adulawọ́. Edé awọn ọmọ aladé! Bawó lo ṣe fẹẹ sòríre ni England lai gbọ Yorùbá?” Háà! Ó mà ṣé o.
Bí èdè wọn ṣe rí lẹ́nu wa rèé. Ẹ jẹ́ kí wọ́n ṣe èyí fún ogójì ọdún lásán. Tó bá pọ̀ jù bẹ́ẹ̀, nǹkan le bàjẹ́ kọjá àtúnṣe. Ẹ wáá jẹ́ ká lọọ wo àwọn olóṣèlú wọn lẹ́yìn ogójì ọdún, ẹ jẹ́ ká lọọ wo àwọn ọmọ ìlú, ẹ jẹ́ ká lọọ wo ohun tí ètò ẹ̀kọ́ àti ìdàgbàsókè tẹkinọ́lọ́jì wọn óó dà, kí lẹ rò pé a óó bá níbẹ̀? Ohun tí àwa ọmọ Áfríkà fojú wì fún irínwó ọdún rèé, 400 years. A wáá jí báyé báyìí, a ń kígbe páyé ò dáa, a l’Áfríkà ń rẹ̀yìn, a láwọn olóṣèlú wa dájú, a ń kígbe páwọn aráàlú ò sunwọn. À ń pariwo pé ẹrù Amúkun wọ́ — bẹ́ẹ̀ òkè la tẹjú mọ́ a ò wòsalẹ̀. Hm̀!
Kín ni ń óó máa fi kásẹ̀ ọ̀rọ̀ mi nílẹ̀? Èèyàn mẹ́rin ni mo bá lẹ́jọ́: olóṣèlú, ológun, aráàlú, àti oníròyìn.
Ọ̀RỌ̀ MI FÚN OLÓṢÈLÚ
Ẹ má gbàgbé pé ṣáájú ohun gbogbo, ọmọ ìlú yìí ni yín o. Ẹnì kan ò ní í dalẹ̀ ìlú ẹ̀ kí wọ́n fọkàn tán an nílùú kankan láyé. Lójú temi o, pẹ̀lú ètò tí àwọn òdanilédèrú ṣe kalẹ̀, olóṣèlú tí ara ọ̀run bá ń yá nìkan ló le ṣòótọ́ láàárín àwọn èèyàn rẹ̀. Báwo lèèyàn ṣe fẹ́ẹ́ ṣòótọ́ pẹ̀lú ọ́lọ́dẹ orí tí ò tiẹ̀ mẹnì tó fẹ́ẹ́ wo òun sàn. Ẹ má bínú bí ọ̀rọ̀ mi bá jọ bíi ẹni pé o le jù o. N ò ríun mì-ín tí mo le fi júwèé inú àhámọ́ làákàyè tí wọ́n de Áfríkà sí ni. Ohun tí èmi fẹ́ẹ́ bẹ̀ yín fún ni pé kẹ́ yéé rí iṣẹ́ ìṣèjọba bíi eré ìje tẹ́nì kan óó gbadé táwọn tó kù óó sì máa ṣẹrú ẹ̀. Ẹ yéé rí i bíi yàrá ààbò tí ọlọ́gbọ́n le wá ààyè sá wọ̀ kó le bọ́ nínú ìjàmbá tí àìníjọba gidi ń dá sílẹ̀ l’Áfríkà nítorí kò sọ́nà àbáyọ. Ẹ rí i bíi ọbẹ̀ ìkòkò kan tí alásè mẹ́ta fẹ́ẹ́ sè pẹ̀lú èèlò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ́wọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan. Bí iyọ̀ ò bá wáá ní í já ọbẹ̀ yìí, tí ata ò ní í wọ́n ọn, tí epo ò ní í ṣàì sí níbẹ̀, dandan ni kí àwọn alásè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fọwọ́sowọ́pọ̀. Ìyẹn bí àwọn pàápàá ò bá fẹ́ kí ebi pa awọ́n kú.
Dájúdájú gbogbo yín ò lè fojú kan náà wo ètò òṣèlú, ṣùgbọ́n báyòówù kẹ́ rò ó títí, ṣebí kílùú ó le dáa náà nibi tí ìrònú yín óó padà forí sọ. Bẹ́ ò rò ó pé kó dáa nítorí aráàlú, ẹ́ óó rò ó pé kó dáa nítorí orúkọ yín. Àbí ṣá a rẹ́ni tó fẹ́ẹ́ ṣòṣèlú nítorí káyé óó máa wọn ìran rẹ̀ lépè, èwo nínú yín ni ò fẹ́ kórúkọ òun làlú já káàkiri àgbáyé, káwọn orílẹ̀-èdè mì-ín máa kọ̀wé nípa ẹ̀ lẹ́yin ọgọ́rùn-ún ọdún tó ti kú pé báwo ló ṣe ṣèjọba tí ayé dẹ tolórí tẹlẹ́mù. Ṣùgbọ́n bẹ́ ẹ bá ń fẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹ ní láti tẹ̀lé òfin àkọ́kọ́ tó ṣẹ̀dàá òṣèlú — òfin ìsowọ́pọ̀. Ẹ jọ jíròrò láàárín ara yín, ẹ wo ohun tó yàtọ̀ nínú ipa òṣèlú tẹ́ ẹ yàn láààyò, kẹ́ sì jọ fẹnu kò lórí àwọn ohun tó le máyé rọrùn fún gbogbo wa. Èmi ò ní kẹ́ yéé sòyìnbó nílé ìjọba o, ṣùgbọ́n ẹ gbìyànjú láti ṣiṣẹ́ takuntakun fún àgbọ́yé aráàlú. Aráàlú gbọdọ̀ gbọ́ èdè tẹ́ ẹ fi ń ṣòṣèlú lágbọ̀ọ́yé. Kò báà jẹ́ mílíọ̀nù kan niye èdè tó wà ní Nàìjíríà, ẹ ní kí wọ́n tú ohunkóhun tẹ́ ẹ bá wí sí i. Bá ò bá gbọ́ yín yé, báwo la ṣe fẹ́ẹ́ fún yín lésì, bá ò bá sì fún yín lésì, báwo lẹ ṣe fẹ́ẹ́ mọ irú àtúnṣe tó yẹ kẹ́ ṣe.
Ìwé òfin ìṣẹ̀dálẹ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tá à ń pè ní Constitution gbọdọ̀ wà ní èdè abínibí gbogbo ọmọ Nàìjíríà, gẹ́gẹ́ bí bíbélì ṣe wà lóríṣìíríṣìí èdè fún àgbọ́yé aráàlú. Kí gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè yìí le mọ iṣẹ́ ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìlú, iṣẹ́ olóṣèlú láàárín ìlú, iṣẹ́ àwọn amòfin, iṣẹ́ adájọ́ àti gbogbo òpó tó di ètò ìṣèjọba orílẹ̀-èdè mú. Ohun kan ṣoṣo tó le mú yín sún mọ́ aráàlú rèé tí yóó sì fún yín lágbára àti ìmọ̀ òṣèlú tòótọ́ tá à bẹ̀rù nílé bẹ̀rù lóde. Torí ẹ̀yin àti aráàlú óó dọ̀kan. Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ẹ́ kojú yín nílé tàbí lóde yóó mọ̀ pé òun fẹ́ẹ́ kojú ìpinnu téèyàn tó lé nígba mílíọ̀nù ṣe. Ẹni ó bá tó bẹ́ẹ̀ kó dán an wò. Ẹ̀yin gbọ́ kí wọ́n dìtẹ̀ gbàjọba Amẹ́ríkà, Ṣáínà, tàbí England rí? Bí àwọn olóṣèlú wọn ṣe níyì káyé lẹ̀yin pàápàá yóó níyì láwùjọ àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé gbogbo.
Ẹnì kan ò lè ní ẹ má bá àwọn olóṣèlú Amẹ́ríkà, Europe, China, Russia, tàbí orílẹ̀-èdè yòówù tó bá lóun fẹ́ẹ́ bá wa ṣe lò pọ̀. Ṣùgbọ́n ẹ rí i dájú pé wọn ò mú yín mábẹ́ nínú àjọṣe yòówù tó bá pa yín pọ̀, awa náà ò sì rán yín lọ síbẹ̀ láti lọọ tẹ̀ wọ́n lórí ba. Nínú ohun yòówù tí yóó bá dà yín pọ̀ pẹ̀lú wọn lórí ilẹ̀ ayé yìí, ẹ rí I pé ẹ bá wọn dúró fi ẹ̀gbẹ́ kan ẹ̀gbẹ́. Ẹ bọ̀wọ̀ fún wọn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú tó wá dáadáa àwọn èèyàn rẹ̀ wá sáàrín wa, ẹ̀yin pàápàá sì gbọdọ̀ rí i dájú pé wọ́n bọ̀wọ̀ fún yín gẹ́gẹ́ bíi aṣáájú tí ò ní í gbà kí wọ́n fi ire àwọn èèyàn tirẹ̀ ṣàpínlé.
Ẹ ṣe bí ẹni pé ẹ ò gbọ́ gbogbo ìdìtẹ̀gbàjọba tó ń lọ káàkiri ilẹ̀ Áfríkà. Àṣẹ̀ṣẹ̀gbé ìyàwó áá dà bí ẹni pé wọn ò le jà láéláé, ẹ fún àwọn orílẹ̀-èdè yìí lọ́dún mẹ́rin péré pẹ̀lú ìjọba tuntun tí wọ́n fìbọn kó jọ — ojú alárédè ìyàwó àṣẹ̀ṣẹ̀gbé wọn ń bọ̀ wáá jọ tẹja kánńfánrán. Ẹ̀yin ẹ fi wọ́n'lẹ̀, gbogbo ẹ̀ la óó kúkú gbọ́.
Ilé ni kẹ́ mójú tó. Ẹ di ọ̀kan ṣoṣo pẹ̀lú aráàlú nípa ṣíṣètò àgbọ́yé tó kúnná, kẹ́ ẹ wáá wẹni tí yóó gbàjọba lọ́wọ́ òkòólúgbadínméjì mílíọ̀nù èèyàn. Gbogbo wa le má ṣe tiyín o, ṣùgbọ́n gbogbo wa óó mọ̀ ìdí tẹ́nì kan ò ṣe gbọdọ̀ dìtẹ̀ gbàjọba lọ́wọ́ olóṣèlú wa. Ẹ̀yin ẹ ṣe bí ẹni tí ò rí aláǹgbá tó ń pòòyì ògiri ilé lẹ́kùlé, bí ẹ̀yin bá ti rẹ́ ògiri yìí tó dí papa nínú ilé, ràbàràbà laláǹgbá yìí óó máa ṣe níta kò ní í ríbi wọlé.
Ọ̀RỌ̀ MI FÚN OLÓGUN:
N ò tiẹ̀ mọ èyí tó léwu jù nínú iṣẹ́ ológun àti iṣẹ́ olóṣèlù. Bí ìlú ṣe ń mùjẹ̀ àti làákáyè olóṣèlú, bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ logun ṣe ń gbẹ̀mí àwọn ológun tó ń kọrí sógun. Kò kúkú séyìí tí mo ṣe rí níbẹ̀, ohun tí mo fi ń sọ̀rọ̀ ò ju ọgbọ́n ìwòye lásán lọ. Ṣùgbọ́n èyí mo mọ̀ tó dá mi lójú, ológun tó bá gbaṣẹ́ olóṣèlú kì í nísinmi. Lọ́pọ̀ ìgbà, iṣẹ́ ọ̀hún náà ní í padà gbẹ̀mí wọn pẹ̀lú gbogbo èrò dáadáa tí wọ́n ní. Nígbà tí kinní ọ̀hún bá tún fẹjú tán pẹ̀lú ìwà ìkà ọmọnìyàn, atabá ìjà òṣèlú yìí máa ń padà kan àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ wọn. Ẹ lọọ bèèrè lọ́wọ́ Maradónà àti ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ìgbà èwe rẹ̀ Mamman Vatsa.
Gbogbo àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ àti àwọn aráàta tí wọ́n ń sọ fún yín pé kẹ́ fìbọ̀ngbàjọba yìí ní ohun tí wọ́n ń wá tí wọn fẹ́ẹ́ lò yín fún ni, ní kété tí wọ́n bá ti rí i ni wọ́n óó sọ yín nù sáàtàn bíi èèpò ẹ̀pà tá a yọ tinú ẹ̀ jẹ. Ẹ ń bèèrè pé báwo ni wọ́n óó ṣe gba agbára lọ́wọ́ yín? Bí wọ́n ṣe gbà á lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n lò yín fún náà ni. Ìjà ọwọ́ sì lẹ̀yin mọ̀ ọ́n já, ẹ ò mọ ìjà ẹ̀mí.
Torí ẹ̀, èmi áá rọ̀ yín pé kẹ́ gbájú mọ́ iṣẹ́ ètò ààbò ìlú tó léwu àti wàhálà tiẹ̀ láàyè ọ̀tọ̀. Ẹ má tún gbé àjàgà òṣèlú rù kún ẹrù wúwo tó wà lọ́rùn yín. Ẹni tíṣẹ́ òṣèlú bá wù kó bọ́ kakí sílẹ̀, kó wọ agbádá. Má a bọ̀ láàárín ìlú kó o mọ àwọn aráàlú. Mọ ìwà aráàlú, ohun tí wọ́n fẹ́ àti èyí tí wọn ò fẹ́. Darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú tó bá ọ̀nà ìṣèjọba tó o gbàgbọ́ nínú ẹ̀, bó ò bá sì rí, dá ẹgbẹ́ òṣèlú tìrẹ sílẹ̀ kí o sì fowọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú aráàlú láti gbé e délé ìjọba. Gbogbo àyípadà tó ò ń fẹ́ ni yóó wáyé lọ́nà tó bófin mu.
Ọ̀RỌ̀ MI FÚN Ẹ̀YIN ONÍRÒYÌN
N ò lè sọ pé ẹ̀yin oníròyìn, torí ara yín lèmi náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n gidi niṣẹ́ wa, tó jẹ́ pé bí a bá mú iṣẹ́ lọ́yà tán nínú ìmòye àwa ló kàn, tó jẹ́ pé lẹ́yìn tí a bá ka ìpele àwọn òǹṣèjọba mẹ́tẹ̀ẹ̀ta nínú iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù láwùjọ àwa ló kàn, síbẹ̀ kí ló dé tí àwọn tó wà lókè ṣì ń wò wá bíi dalérú-dalérú? Èmí ti lọ sí ọ̀dọ̀ ẹni tá a fẹ́ẹ́ gbàròyìn lẹ́nu ẹ̀ tó fi wá sórí ìdúró tó ń jẹun, mo sì ti dé ọ̀dọ̀ èyí tó pè wá wọ ọ́fíìsì tó yẹ́ wa sí bíi èèyàn pàtàkì nítorí kò mọ ohun tá óó délé kọ nípa òun.
Nígbà tá a wo gbogbo ohun méjèèje tí à á fi í dá ìròyìn mọ̀, a rí I pé àkoríjọpọ̀ gbogbo ẹ̀ padà sorí kọ́ sábẹ́ ohun kan ṣoṣo — ohun tí kì í sáábà ṣẹlẹ̀ tàbí ohun téèyàn ò rò pé ó lè ṣẹlẹ̀. Bí a bá gbéṣẹ́ ìṣèjọba fólóṣèlú, aráàlú ń retí pé kó tún ìlú ṣe ni. Bó bá ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ bó ṣe yẹ, ìyẹn kì í ṣe ìròyìn àgbọ́yanu hanha. Ṣùgbọ́n bí ẹni tó yẹ kó ṣiṣẹ́ fún ìlú bá di ẹni tí ìlú ń ṣiṣẹ́ fún, bí ẹni tó ti ń ṣe bó ṣe yẹ kó ṣe láti ọdúnnì-ín bá ṣèèṣì yísẹ̀ padà tí ò ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́ — ìròyìn yàjóyàjó rèé. Bá á tí í mọ ìròyìn tí óó tà létí aráàlú gan-an rèé. Èyí loníròyìn ṣe dà bíi igúnnugún tí í wá ìṣubú ẹni tó wà lókè, òótọ́ ibẹ̀ ni pé ìròyìn gidi nípa ẹni gidi kì í tà létí aráyé àfi kí wọ́n gbọ́ ohun tí wọn ò retí nípa ẹ̀.
Níbi tá a wáá dé lónì-ín ẹ̀yin oníròyìn, ǹjẹ́ aráàlú ń retí pé kí olóṣèlú kan wọlé ìjọba lọọ ṣiṣẹ́ ìlú? Ǹjẹ́ kò ti dìròyìn báyìí bá a bá ní olóṣèlú gidi láàárín wa níbikíbi lórí ilẹ̀ adúláwọ̀? Bẹ́ ẹ bá rí olóṣèlú tó ń ṣe dáadáa, ẹ pòkìkí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bẹ́ ẹ ṣe ń pòkìkí ìròyìn burúkú nípa wọn. Ìròyìn burúkú nípa wọn yìí pàápàá, ẹ má dánu ẹ̀ dúró sórí pé ìwà àwọn olóṣèlú yìí ò kàn dáa ni. Ẹ tẹ̀ síwájú kẹ́ ṣèwádìí lórí ohun tó mú wọn ṣe bẹ́ẹ̀, ohun tó jẹ́ kí wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀, àti ohun tí ìlú lè ṣe láti rí I dájú pé irú ẹ̀ ò tún ṣẹlẹ̀ mọ́.
Bẹ́ ẹ bá gba ọ̀rọ̀ lẹ́nu olóṣèlú tó ń tako ohun tí àwọn òǹṣèjọba ń ṣe, ẹ bi í léèrè pé bó bá jẹ́ òun ló wà nípò kín ni yóó ṣe, ọ̀nà wo ni yóó sì gbà ṣe é. Èyí tí ò bá ríhun mì-ín wí ju pé èèyàn burúkú ló wà níjọba ni wọ́n ṣe ń hùwà burúkú, àwọn olóṣèlú apá ọ̀dọ̀ òun lèèyàn dáadáa tó yẹ kí ìlú yàn sípò káyé tóó le dáa, ẹ pa ẹ̀rọ apagbe mọ́ ọn lẹ́nu ẹ ní kó máa lọ ilé. Èyí tó bá sì rí àbá gidi mú wá, ẹ gbé e lọọ bá àwọn tó wà níjọba. Bí wọ́n bá láwọn ò lè mú un lò, ẹ bèèrè ìdí tí wọn ò fi lè mú un lò kẹ́ kọ ọ́ síta káyé gbọ́.
Ẹ má jẹ́ ká gbàgbé pé ọmọ orílẹ̀-èdè yìí làwa náà o. A ò wá sórílẹ̀-èdè yìí wáá ṣòwò, ìlú àbínibí wa la ti ń ṣiṣẹ́. Gbogbo ohun burúkú tá a bá sọ nípa ọmọ Nàìjíríà tó wà nínú òṣèlú, èyí tó wà lójú ayé àti èyí tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba ni yóó padà sí wa lápò. Torí bí àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé bá bẹ̀rẹ̀ si í gbégilé ọmọ Nàìjíríà pé oníbàjẹ́ ni wọ́n, wọn ò ní í yọ tàwọn oníròyìn ìbẹ sọ́tọ̀ o. Ohun kan náà tí mo sọ fólóṣèlú náà ni n óó sọ fún yín, èèyàn kan ò ní í dalẹ̀ orílẹ̀-èdè ẹ̀ kí wọ́n fojú ire wò ó níbikíbi lórílẹ̀-èdè àgbáyé.
Ọ̀RỌ̀ MI FÚN ARÁÀLÚ
Ẹ ǹlẹ́ o, ẹ̀yin ọmọọba. Ohun tí Dẹmókírésì pè yín rèé. Láyé ìgbà kan tó jẹ́ pé ó lójú ẹni tó le dépò aṣíwájú nínú ìran ènìyàn, ó lójú ẹ̀kọ́ tí wọ́n le gbà kí aráàlú kọ́. Àwọn ọmọ ọba àti ọmọ ìjòyè nìkan ló lè kọ́ ọ kí ọmọ aráàlú má le dépò tí wọ́n wà láéláé. Ṣùgbọ́n Dẹ̀mókírésì ní kò gbọdọ̀ rí bẹ́ẹ̀ mọ́, bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ẹ́ di aṣíwájú lórílẹ̀-èdè rẹ̀, onítòhún gbọ́dọ̀ kàn sí ọ láti bèèrè bóyá o fẹ́ bẹ́ẹ̀. Bí ìwọ pàápàá bá sì fẹ́ẹ́ di aṣíwájú, ẹnu kó o wá ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn aráàlú tó kù ni, bí wọ́n bá fi tì ọ́ lẹ́yìn, o di adarí orílẹ̀-èdè nìyẹn. Ẹ ò rí I pé Dẹmókírésì ti sọ gbogbo wa di ọmọ ilé ọba, ìmọ̀ ló kù ká wá tí adé yóó fi pẹ́ lórí o.
Wádìí nípa ìwé òfin ìṣẹ̀dálẹ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (Constitution) tó fún ọ lágbára láti dá sí ètò òṣèlú. A ti sọ fáwọn olóṣèlú pé kí wọ́n tú u sí gbogbo èdè abínibí, ṣùgbọ́n bí wọ́n bá ń pẹ́ jù ẹ pe ara yín jọ nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan kẹ́ tú u sí èdè ẹ̀yà yín. Kẹ́ wáá bẹ̀rẹ̀ si í pé jọ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti kà á bí ìgbà tẹ́ ẹ bá ń ka ìwé ìjọ́sìn yín. Ẹ bẹ̀rẹ̀ si í kà á pẹ̀lú ìwé ìròyìn tó ń jáde lójoojúmọ́ láti fi mọ bí orílẹ̀-èdè yín ṣe ń lọ. Ẹ má wáá nìkàn dá a mọ̀ o, ẹ rí i dájú pé púpọ̀ nínú ará àdúgbò yín ló mọ̀ ọ́n, torí nígbà tí wọ́n óó bá lo agbára tí ìwé òfin yìí fún wọn gẹ́gẹ́ bí ọmọ onílùú láti fi yan aṣáájú gidi tàbí láti fi lé aṣíwájú burúkú dànù, ẹ óó le jọ lò ó lọ́nà tí yóó fi mú ìdàgbàsókè bá orílẹ̀-èdè yín.
Ó ṣe pàtàkì fún gbogbo èèyàn ayé láti wá ìmọ̀ kí wọ́n le wúlò fún ara wọn àti àwùjọ wọn. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tó bá gbọ́ ìtàn wa, yóó mọ̀ pé ó pọn dandan fún ọmọ adúláwọ̀ láti wá ìmọ̀ ká tóó le jẹ́ nǹkan kan lójú ọmọ aráyé. Torí lẹ́yìnkùlé wa ni wúrà àti àwọn òkúta olówó iyebíye tí gbogbo ayé ń wá wà. Àwọn kan fẹ́ẹ́ kó gbogbo kinní yìí kúrò lẹ́yìnkùlé wa lọ́fẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwíjàre pé lábẹ́ ọ̀bọ tó fojú jọ èèyàn làwọn ti kó o, torí ẹ̀ ni wọ́n ṣe dà wá lédè rú, tí wọ́n da àṣà wa rú, tí wọ́n sọ wá dọ̀tá àwọn babańlá wa tó jẹ́ èèyàn, ká le máa dura láti ṣe bíi baba-ńlá wọn ká tóó le fojú jọ̀ọ̀yàn. Èmi ò sọ èyí fún ọ kó o lè lọọ máa bá àwọn òyìnbó ṣọ̀tàá o, torí àwọn òyìnbó tìsìnyìí kọ́ ló ṣe wá báyìí, àwọn babańlá wọn ni. Babańlá gbogbo wọn tún wáá kọ́ o, babańlá àwọn kan nínú wọn ni. Torí ẹ̀ ọmọ adúláwọ̀, àsìkò à-ń-bẹ́nì-kan ṣọ̀tàá kọ́ leléyìí. Kò tiẹ̀ sáàyè ẹ̀ fẹ́ni tí wọ́n ti gba ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ọdún lọ́wọ́ ẹ̀. Dípò ọ̀tá, ọ̀rẹ́ ni kó o bá gbogbo ayé ṣe. Wá ìmọ̀ lọ sọ́dọ̀ òyìnbó, wá ìmọ̀ lọ sọ́dọ̀ lárúbáwá, wá ìmọ̀ lọ sáàrín àwọn ọmọ ṣinkó, láàárín àwọn ọmọ Kọ̀ráà. Wá ìmọ̀, wá ìmọ̀, ọmọ adúláwọ̀ wá ìmọ̀ bíi ìnàkí tó ń wá ìmọ̀ kó baá lè sọ̀rọ̀ bí èèyàn. Báyòówù kó o wáá wá ìmọ̀ tó, má gbàgbé ilé o. Má gbàgbé ohun táwọn baba wa kọ́ wa. Òun nìwọ fúnra rẹ óó rí fi ṣe pàṣípààrọ̀ ní gbogbo ilẹ̀ àjèjì tó o ti ń lọọ kẹ́kọ̀ọ́. Gbogbo ìmọ̀ tó o bá wáá kọ́ yìí ni kó o tú sédè àbínibí, kí àwọn ọmọ ìyá rẹ nílé le kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ yìí láì rin tó bó o ṣe rìn tàbí náwó tó bíwọ ṣe náwó tó.
Hm! Ẹ má bínú pé ọ̀rọ̀ yìí pọ̀ díẹ̀ lónì-ín, kì í kúkú ṣe pé ó wù mí láti gbà yín lákókò rẹpẹtẹ tó bẹ́ẹ̀ — a ò mọ èyí tá óó sọ tá ò ní í sọ̀ omì-ín mọ́ ni.
Láti fèsì sí fọ́nrán yìí tàbí ọ̀kankan nínú àwọn fọ́nrán IRIS MEDIA PROSPECTS SERVICES, ẹ lè kọ̀wé sí irismediaps@gmail.com tàbí kí ẹ pe nọ́mbà yìí, +2348085548868.
Musa Babátúndé-Kọ́gà lorúkọ mi. Òjò ni mí n ò bẹ́nì kan ṣọ̀tàá, ẹni eji rí leji ń pa. Ààrá ni mí n ò bẹ́nì kan ṣọ̀tẹ̀, ẹni ó bá dí mi lọ́nà ni óó ríjà arábámbí onígba ọta. Ojú tí mo fi rí ohun tó ń lọ lágbo òṣèlú rèé o, ìyókù tún dọjọ́ mì-ín tí ààyè bá gbà mí níbi tẹ́nu mi óó ti lè rọ́rọ̀ sọ.
Ire o.
0 Comments