Search This Blog

Rògbòdìyàn ẹ̀sìn nílùú Ìlọrin: Ẹ̀yin ọmọ Ìlọrin, kí lẹ ti wí?

 



Ṣáájú kí n tóó sọ ohunkóhun lórí ọ̀rọ̀ yìí, ó ṣe pàtàkì láti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àlàyé pé gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ẹ́ sọ yìí ń jẹ jáde láti inú ìròrí ọgbọ́n tí Ọlọ́run Olódùmarè fi jíǹkí mi àti àwọn ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ kàákiri àṣà àwọn èèyàn ayé gbogbo. Nítorí ìdí èyí, àwọn ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ẹ́ sọ yìí le má bá yín lára mu nítorí ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọgbọ́n ìròrí tí Ọlọ́run fún yín ju tèmi lọ, ìrírí yín nípa ayé pàápàá le ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ níbi tí tèmi pin sí. Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń gbà yín níyànjú pé kí ẹ má gba ọ̀rọ̀ mi sórí láì kọ́kọ́ gbé e yẹ̀wó nínú làákáyè tí Ọlọ́run fi jíǹkí yín gẹ́gẹ́ bó ṣe fi jíǹkí gbogbo èèyàn àgbáyé, lẹ́yìn àgbéyẹ̀wò yín bí ẹ bá gbà á wọlé – ó dáa bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn àgbéyẹ̀wò yìí bí ọ̀rọ̀ mi bá gbòdì lára yín, ẹ má sọ ọ́ dìjà. N óó fún yín ní ẹ̀rọ apagbe mi ní kété tí mo bá ti sọ̀rọ̀ tán. Ẹ lè pè mí lọ́jọ́ Sánndè yòówù tó bá rọ̀ yín lọ́rùn ká jọ fọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀. Ó ṣeé ṣe kí n rí ẹ̀kọ́ tuntun kọ́ nínú àjọsọ wa. Àwọn ọ̀rọ̀ tí n óó sì máa sọ lọ́jọ́ iwájú yóó le túbọ̀ ṣe ọmọ aráayé láǹfààní nítorí tiyín.

Lọ́jọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù keje ọdún 2023 ni mo rí fídíò ọ̀gá ọlọ́pàá tó pe àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ àti àwọn ààfáà Ìlọrin sípàdé àlááfíà láti yanjú rògbòdìyàn tó wà láàárín wọn kó tóó di pé yóó la ìtàjẹ̀sílẹ̀ lọ. Èyí kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí n óó gbọ́ nípa rògbòdìyàn yìí o. Kódà látìgbà tí wọ́n ti jáwée Jókòó-jẹ́ẹ́ fún arábìnrin Yèyé Ajéṣìkẹ́mi Olókun Ọmọlará Ọlátúnjí tó lóun fẹ́ẹ́ ṣọdún Ọ̀ṣun n’Ílọrin ni mo ti gbọ́ sí ọ̀rọ̀ ọ̀hún. Mo sì gbọ́ nípa ìtahùnsí tó wáyé láàárín Emir ìlú Ìlọrin Shehu Sulu Gambàrí àti Ọ̀jọ́gbọ́n Wọlé Ṣóyínká lórí ọ̀rọ̀ yìí kan náà.

Mo wo gbogbo àwọn tí wọ́n jòkòó nílé ìpàdé yìí, ìbéèrè mẹ́ta sì ń sọ kútú lọ́kàn mi. Àkọ́kọ́ ni pé nínú gbogbo àwọn tó jòkòó yìí, ǹjẹ́ a rí ẹni tó le lóun lágbára ju Ọlọ́run tó dá ayé àti ọ̀run nínú wọn? Bí a ò bá rí ẹni tó lágbára ju Ọlọ́run lọ, ǹjẹ́ a rí ẹni tó lé nawọ́ sókè pé òun lágbára tó Ọlọ́run? Kò pọn dandan kó tiẹ̀ lágbára ju Ọlọ́run lọ, kó kàn le sọ pé níbi tí Ọlọ́run bá jòkòó sí, òun le jòkòó níbẹ̀ kí òun àti Ọlọ́run jọ fẹ̀gbẹ́kẹ̀ngbẹ́ – tó jẹ́ pé o ní ìdiwọn ohun tí Ọlọ́run lè ṣe láì rí òun. Bóun ba fi fọwọ́ sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, bíì ìgbà tí alágbára méjì bá fọwọ́sowọ́pọ̀ fún àṣeyọrí nǹkan kan ni. Bí a ò bá wáá rí ẹni tó le dáhùn “Bẹ́ẹ̀ ni” sí àwọn ìbéèrè yìí nínú ẹlẹ́sìn méjèèjì, tí wọ́n sì nígbàgbọ́ pé Ọlọ́run lókè nìkan ló lágbára ju gbogbo ohun tó ń mí àti èyí tí ò mí, tó le ní kí nǹkan ó máa bẹ - tó sì tún le ní kí nǹkan yéé bẹ mọ́, ǹjẹ́ àwọn wọ̀nyí ò máa fìwà pe Ọlọ́run yìí ní alágbára-má-mèrò tó lágbára jú ohun gbogbo tí ò sì mọ ibi tó yẹ kó lò ó sí? Ǹjẹ́ wọn ò máa fìwà pe Ọlọ́run ní aláṣìṣe tó ṣèèṣì dá onírúurú ẹ̀sìn sáyé, tí àwọn ẹ̀dá ọwọ́ ẹ̀ ní láti ṣiṣẹ́ takuntakun láti pa àṣìṣe rẹ̀ rẹ́ kó tóó di pé ó ba ayé jẹ́?

Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí ò láwọn ń gbèjà Ọlọ́run, ìjà ilẹ̀, ìjà ipasẹ̀ ìgbàgbọ́ àti ìjà èmi jù ọ́ – ìwọ ò jù mí ni wọ́n ń jà n’Ílọrin. Nígbà tí agbẹnusọ àwọn ààfáà yóó sọ̀rọ̀, ó láwọn ò lòdì sì ẹlẹ́sìn àbáláyé tàbí ẹlẹ́sìn kankan. Ohun tí àwọn ń jà fún ni pé ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ẹ́ ṣe ẹ̀sìn oníṣẹ̀ṣe yìí, inú kọ̀rọ̀ yàrá ẹ̀ ni kó ti máa ṣe é. Ó wáá gbé ẹ̀sìn ọ̀hún rìn jìnnà a ò rí irú ẹ̀ rí, kò gbọdọ̀ gbé e kọjá ẹnu ọ̀nà rẹ̀ débi tí wọ́n óó máa wáá ki Ìlọrin lóríkì táwọn ò bá lẹ́nu àwọn baba àwọn. Àwọn mùsùlùmí ló pọ̀ jù n’Ílọrin, láti ayébáyé àwọn ààfáà sì ni wọ́n ni Ìlọrin.

Àwọn oníṣẹ̀ṣe ń sọ pé àwọn làwọn ni Ìlọrin láti ìṣẹ̀ǹbáyé. Ìgbà tí àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí dé ni wọ́n fi ogun lé àwọn sẹ́yìn odi ìlú tí àwọn ò lẹ́nu ọ̀rọ̀ mọ́ nílùú abínibí àwọn. Ọmọ ìlú Ìlọrin làwọn náà, ẹ̀tọ́ tí àwọn mùsùlùmí ọmọ Ìlọrin ní láti ṣe ẹ̀sìn wọn láì ní gbèdéke làwọn náà ní láti fi ṣe ẹ̀sin àwọn láì ní gbèdéke. Bí wọ́n bá ń sọ pé ìlú ààfáà n’Ìlọrin, kí wọ́n máa sọ ọ́ pé àwọn oníṣẹ̀ṣe náà wà níbẹ̀. Torí oníṣẹ̀ṣe làwọn, jíjẹ́ oníṣẹ̀ṣe ò sì gba ẹ̀tọ́ jíjẹ́ ọmọ Ìlọrin kúrò lọ́wọ́ àwọn.

Ṣé ẹ rí i báyìí pé ìja ara wọn làwọn méjèèjì ń jà kì í ṣe ti Ọlọ́run. Ó dáa, ẹ jẹ́ ká fi òfin gbé ọ̀rọ̀ àwọn méjèèjì wò kó tóó di pé a fi làákáyè tá a fi ṣẹ̀dá òfin funra rẹ̀ gbé e yẹ̀wò.

Nínú ìwé òfin ìṣẹ̀dálẹ̀ Nàìjíríà tá à ń pè ní Constitution, tí gbogbo ológun Nàìjíríà, olóṣèlú àti àwọn adájọ́ orílẹ̀-èdè yìí gbọdọ lo gbogbo agbára wọn láti fi bá ẹnikẹ́ni tó bá takò ó já nibíkíbi ní tìbú-tòòró Nàìjíríà, ohun tó wà ní ilà ... ìwé náà ni pé orílẹ̀-èdè yìí kò ní í yan ẹ̀sìn kan ṣoṣo láti borí ẹ̀sìn kejì. Ní gbogbo ibi tó bá tí jẹ́ pé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ló ń pàṣẹ débẹ̀, ẹnikẹ́ni le ṣe ẹ̀sinkẹ́sìn tó bá wù ú níwọ̀n ìgbà tí kò bá ti fi tirẹ̀ dí ẹnìkejì lọ́wọ́.

Èèyàn làwọn tó kọ ìwé òfin ìṣẹ̀dálẹ̀ yìí wọn kì í ṣe àǹjọ̀nnú, ẹ jẹ́ ká jọ wo ohun tí wọ́n rò lọ́kàn wọn tí wọ́n fi kọ ọ́ bẹ́ẹ̀. Lásíkò tí wọ́n kọ ìwé Òfin Ìṣẹ̀dálẹ̀ Orílẹ̀-èdè yìí, ẹ̀sìn kan ṣoṣo kọ́ ló wà ní Nàìjíríà. Àwọn ẹlẹ́sìn yìí sì pọ̀ káàkiri ni. Kò sí bí a ṣe fẹ́ẹ́ yan ọ̀kan ṣoṣo nínú ẹ̀ tí ìjà ò ní í dé. Bó bá sì tún di ọjọ́ iwájú pàápàá, a le rí ọmọ Kristẹni tí yóó ní òun rí dáadáa nínú ẹ̀sìn Ìsìláámù òun fẹ́ẹ́ máa kírun tàbí ọmọ Mùsùlùmí tí yóó ní òun rí ìsinmi nínú Jésù ọmọ Màríà. Bí àwọn bá ti kọ ọ́ pé ẹ̀sìn kan ṣoṣo ni Nàìjíríà yóó ní, ǹjẹ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà ò ní í ní láti sá kúrò nílùú àbínibí wọn bí wọ́n bá fẹ́ẹ́ yí ẹ̀sìn padà. Gbogbo àǹfààní tí wọn ò bá máa ṣe fún orílẹ̀-èdè wọn ni wọn yóó lọ máa ṣe fún orílẹ̀-èdè tó fààyè gba ẹlẹ́sìn rẹpẹtẹ nítorí ìlú wọn ti sọ ara rẹ̀ di olójú kan ṣoṣo. Ohun tó fà á tí wọ́n fi wò ó pé kí oníkálukú máa ṣe ẹ̀sin rẹ̀ bó bá ṣe mọ̀ ọ́n ṣe rèé, níwọ̀n ìgbà tí kò bá ti fi tiẹ̀ dí àwọn tó kù lọ́wọ́. Jíjẹ́ Mùsùlùmí, Krìstẹ́nì, oníṣẹ̀ṣe, oní-híndù, tàbí ẹ̀sìn yòówù tí èèyàn bá yàn láàyò kò dí jíjẹ́ ọmọ Nàìjíríà lọ́wọ́. Gbogbo àǹfààní tí àwọn ọmọ Nàìjíríà sì ní lábẹ́ òfin ló tọ́ sí onítọ̀hún náà.

A ti gbọ́ ohun tí ìwé Òfin tó de gbogbo Nàìjíríà, nínú èyí tí ìlú Ìlọrin jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìlú tó wà lábẹ́ ẹ̀ sọ. Ẹ wáá jẹ́ ká gbé ọ̀rọ̀ yìí sí làákáyè ká jọ wo ohun tí yóó ti ẹ̀yìn ìbéèrè àwọn ẹlẹ́sìn méjèèjì yọ. Agbẹnusọ àwọn ààfáà yìí ní àwọn ọ̀rọ̀ tóun ń sọ yìí kì í ṣe ọ̀rọ̀ àdásọ o, ọ̀rọ̀ gbogbo ọmọ Ìlọrin ni. Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ẹ́ bọ òrìṣà, kó máa bọ ọ́ nínú ilé rẹ̀. Bó bá fi gbé e kọjá ibẹ̀ ó ń wájà àwọn ọmọ Ìlọrin ni.

Dájúdájú, gbogbo èèyàn ò lè sùn kí wọ́n kọrí síbì kan náà. Ṣùgbọ́n bí púpọ̀ nínú ọmọ ìlú bá ti kọrí sójú kan ṣoṣo, kódà bí àwọn tó kù ò bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, ibẹ̀ ni ìlú wọn yóó kọrí sí.

Ohun tí wọ́n ń sọ ni pé bó ṣe wù ọ́ lo ṣe lè ṣe ẹ̀sìn tí kì í ṣe Ìsìláámù nínú ilé rẹ, ṣùgbọ́n bó bá fi di pé ò ń lọ sí àwọn ààyè tó jẹ́ ti gbogbo ọmọ Ìlọrin bíi ojú títì, ojú odò, tàbí àwọn ààyè mí-ìn bẹ́ẹ̀ tólóyìnbó ń pè ní PUBLIC SPACE — ìjà àwọn ọmọ Ìlọrin lò ń wá. Torí mùsùlùmí ni púpọ̀ nínú àwọn ọmọ Ìlọrin, àwọn sì ti fẹnu kò pé Ìsìláàmù ni ẹ̀sìn àwọn n’Ílọrin. Èyí tó túmọ̀ sí pé ọmọ Ìlọrin tí ò bá ní Ìsìláàmù ò pé lọ́mọ Ìlọrin, kò sì lẹ́tọ̀ọ́ sí gbogbo àǹfààní ẹ̀sìn kan náà tí ọmọ Ìlọrin tó jẹ́ mùsùlùmí ní.

Bí ọ̀rọ̀ yìí bá ní ìtumọ̀ mì-ín tó yàtọ̀ sí ohun mo sọ̀ yìí, ẹ dáákun ẹ ṣàlàyé lọ́nà tí yóó gbà yé mi. Ohun tó túmọ̀ sí nínú orí mi ni mo ń ṣàlàyé fún yín yìí.

Bó bá jẹ́ bí mo ṣe rò ó yìí náà ló túmọ̀ sí, èmi ò rò pé ọ̀rọ̀ yìí yẹ kó mú ìjà kankan lọ́wọ́. A ní kóun tó wu’ni ó yọjú, ohun tó dáa ń yọrùn bọ́ọ́ta — bó bá dáa bí ò bá wu’ni ńkọ́?

Èmi mọ ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro yìí tí gbogbo aáwọ̀ yìí óó sì wá sópin. Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé inú Nàìjíríà ṣì ni Ìlọrin wà, tí kì í ṣe pé ẹ ṣetán láti dá ní orílẹ̀-èdè tiyín, ẹ̀yin sì ni Ọlọ́run ní kẹ́ pọ̀ ju àwọn ẹlẹ́sìn tó kù lọ. Níṣe lẹ óó kọ̀wé sí àwọn ọmọ yín tó wà nílé-ìgbìmọ̀ aṣòfin ìjọba àpapọ̀ pé kí wọ́n yí òfin tó wà nílẹ̀ pé Nàìjíríà ò ní í ní ẹ̀sìn kan ṣoṣo padà. Kí wọ́n kọ ọ́ síbẹ̀ pé ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan le yan ẹ̀sìn tó bá wù ú lẹ́sìn tirẹ̀ tí yóó sì lé àwọn ẹlẹ́sìn tó kù kúrò nílùú.

Ọ̀nà kan ṣoṣo tó bófin mu rèé tẹ́ ẹ lè gbà fi mú ìfẹ́ inú yín ṣẹ. Mo fi ń dá yín lójú, àwọn oníṣẹ̀ṣe nìkan kọ́ lẹ óó lé kúrò nílùú. Kódà, àwọn ẹlẹ́sìn krìstẹ́nì tẹ́ ẹ ti ń bá fa wàhálà lórí iléèwè tí wọ́n fi owó wọn kọ́, ẹ óó rí àwọn náà lé dànù tèfètèfè. Yóó wáá ku ẹ̀yìn ẹlẹ́sìn kan ṣóó n’Ílọrin.

Ṣùgbọ́n ẹ rántí pé bí ẹ̀yin bá ṣe láṣẹ láti sọ Ìlọrin di ẹlẹ́sìn kan ṣoṣo làwọn ìpínlẹ̀ tó kù náà ṣe láṣẹ láti sọ ìlú wọn di ẹlẹ́sìn kan ṣoṣo tàbí kí wọ́n fààyè gba gbogbo ẹ̀sìn. Gbogbo ìpínlẹ̀ tí wọ́n bá ti yan ẹ̀sìn mí-ìn ni wọn óó ti lé àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí jáde pé kí wọ́n máa lọ sí Ìlọrin. Ìbéèrè yín láti sọ ìpínlẹ̀ Ìlọrin di ẹlẹ́sìn kan yóó gba gbọ̀ngán ìlú, fíìdì, àti ojú títì tí wọ́n ti ń kírun lásìkò ọdún iléyá kúrò lọ́wọ́ àwọn mùsùlùmí tó wà ní ìpínlẹ̀ tó kù tí ò gba tiyín – nítorí ìlú ló ni àwọn ààyè yìí tí wọ́n sì ń fún Mùsùlùmí láǹfààní láti ṣe bó ṣe wù wọ́n lọ́jọ́ ọdun tiwọn. Ìjọba nìkan kọ́ ló ń fún Mùsùlùmí lọ́ludé lọ́jọ́ ọdún yìí, àwọn ẹlẹ́sìn mì-ín ò fìgbà kan kọ̀wé ìjà pé ẹ ṣe tẹ́ní dí ojú títì tàbí ẹ ṣe pọ̀ sójú kan láti kírun lọ́jọ́ jímọ̀.

Ìbéèrè yín láti sọ Ìlọrin di ẹlẹ́sìn kan ṣoṣo yóó pín àwọn ọmọ ìyá tó jẹ́ pé ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ń ṣe níyà, kò kúkú sí ohun tó burú níbẹ̀ – ó dá mi lójú pé ẹ óó gbà wọ́n tọwọ́-tẹsẹ̀ wọ ìlú Ìlọrin. Ẹ óó sì fẹ́ràn wọn ju bí ọmọ ìyà wọn ṣe lè fẹ́ràn wọn lọ. Ẹ óó fẹ́ràn wọn ju bí òbí wọn tó jẹ́ ẹlẹ́sìn mí-ìn ṣe lè fẹ́ràn wọn lọ. Kódà, ẹ óó fẹ́ràn wọn ju ọmọ inú yín lọ.

Gbogbo ibi tí wọ́n bá sì ti ń gba àwọn oríṣìíríṣìí ẹ̀sìn, wọn ò ní í fààyè gba Ìsìláàmù láàyè. Wọ́n óó máa sọ ọ́ níbẹ̀ pé níbikíbi tí ẹ bá ti gbà wọ́n láàyè ni wọ́n ti máa ń padà gbilẹ̀ tí wọ́n óó sì lé gbogbo ẹ̀sìn tó kù kúrò tí yóó ku àwọn nìkan ṣo. Wọ́n óó wáá yí orúkọ ẹ̀sìn yìí padà kúrò lẹ́sìn àlááfíà, wọn óó máa pè é lórúkọ tí àwọn Yorùbá tó kọ́kọ́ tako ẹ̀sìn yìí ń pè é nítorí tiyín, Ẹ̀sìn Ìmàle! Ǹjẹ́ ẹ lérò pé ẹ̀sìn yìí yóó kọjá ibi tó dé lónì-ín bẹ́ ẹ bá gbé ìgbésẹ̀ yìí?

Ṣé ẹ ò gbàgbé pé bayìí náà ni wọ́n ṣe lé òjíṣẹ́ ńlá tí Ọlọ́run fi ẹ̀sìn Ìsìláàmù rán kúrò nílùú Baba rẹ̀ nítorí pé kò bá wọn ṣe ẹ̀sìn lọ́nà tí wọ́n gbàgbọ́? Kí ló tẹ̀yin ẹ̀ yọ fún àwọn èrò rẹpẹtẹ tó lòdí sí ẹ̀sìn Ìsìláàmù lọ́dún náà lọ́hùn? Ẹ̀yin mùsùlùmí Ìlọrin tẹ́ ẹ pọ̀ ju àwọn ẹlẹ́sìn mì-ín lọ, mo ti sọ ọ̀nà tẹ́ ẹ lè gbà lé àwọn ọmọ ìlú yín tí ò fẹ́ẹ́ bá yín ṣe ẹ̀sìn kan ṣoṣo tí ẹ̀ ń ṣe kúrò nílùú baba wọn. Ẹ̀yín ọmọ ẹnì tó sọ Kínírá dòfo, ọmọ a-sọ-Fààfà-dilẹ̀, ẹnu kẹ́ wí bẹ́ẹ̀ ni – ẹ̀gbà Ọ̀run óó sì bá yín gbà á. Ẹ̀yin ọmọ Ìlọrin, kí lẹ ti wí?

N ò ní í fẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi gùn jù nínú fọ́nrán yìí, nítorí ẹ̀ n óó fún ọ̀rọ̀ nípa rògbòdìyàn Ìlọrin ní apá kejì.

Láti fèsì sí fọ́rán yìí tàbí ọ̀kankan nínú àwọn fọ́nrán Iris Media Prospects Services, ẹ lè fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ sí irismediaps@gmail.com tàbí kí ẹ pe nọ́mbà yìí ní ọjọ́ Sunday: +2348085548868. Ṣùgbọ́n ṣáájú kí ẹ tóó pè, ẹ lọọ mọ̀ pé gbogbo àjọsọ wa ni yóó wà ní àkásílẹ̀ kí á le jọ padà tún ọ̀rọ̀ wa gbọ́ fún àlékún ìmọ̀ tó péye. Ọjọ́ Sunday nìkan sì ni ń óó le ráàyè gbé ìpè yín.

Musa Babátúndé-Kọ́gà lorúkọ mi. Òjò ni mí n ò bẹ́nì kan ṣọ̀tàá, ẹni eji rí leji ń pa. Ààrá ni mí n ò bẹ́nì kan ṣọ̀tẹ̀, ẹni ó bá dènà dè mí ni óó ríjà arábámbí onígba ọta. Ojú tí mo fi rí ohun tó ń lọ lágbó òṣèlú rèé o. Ìyókù tún dọjọ́ mì-ín táàyè bá gbà mí níbí tẹ́nu mi óó ti léè rọ́rọ̀ sọ.

Ire o.


Post a Comment

0 Comments