Search This Blog

OLÓYÈ ỌBÁSANJỌ́, ỌMỌ ÀLÈ MÀ NÍ Í FỌWỌ́ ÒSÌ JÚWÈÉ ILÉ BÀBÁ Ẹ̀!

 

Ex-President Olusegun Obasanjo and Governor Seyi Makinde (Source: Premium Times)

Èmi àti ẹnì kan jọ ń jíròrò lọ́jọ́ kan, ó sì bèèrè ọ̀rọ̀ tó ṣe é léèmọ̀ nípa mi. Ó ní, “Báwo lo ṣe le ló o gba ti Olúfẹlá Aníkúlápó Kútì, tó ó sì tún ló o ṣe ti ààrẹ àná, Olóyè Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́, nígbà tó jẹ́ pé bí ọ̀tá làwọn méjèèjì yìí rí ara wọn.

Èsì tí mo fẹ́ni náà ni pé — lójú tèmi, èmi gbàgbọ́ pé bí ìwé ìmọ̀ làwọn àgbà inú àwùjọ rí. Gbogbo àṣìṣe táwa ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ẹ́ ṣe lónì-ín làwọn ti ṣe sẹ́yìn. Ọ̀dọ́ tó bá wáá lóun ò ní í wádìí nípa wọn tàbí tó ní ọ̀kan nínú wọn lòun fẹ́ẹ́ gbọ́ nípa ẹ̀ – òun ò fẹ́ẹ́ gbọ́ nípa àwọn tó kù, ara rẹ̀ ló yàn jẹ. Torí kódà béèyàn bá fara balẹ̀ wo òmùgọ̀ ìlú pàápàá, ẹni ó bá fẹ́ẹ́ kọ́gbọ́n óó kúkú rí ọgbọ́n kọ́ lára rẹ̀. Ká tóó wáá sọ àwọn àgbà ìlú tí wọ́n jẹ́ aláṣeyọrí láàyè ara wọn.

Bí mo bá rí dáadáa nínú ọ̀rọ̀ Bàbá 70, dandan ni kí n mú un sápò kí n fi ṣe ìwà wù. Èyí ò ní kí n rí dáadáa nínú ọ̀rọ̀ Ẹbọra Òwu kí n kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Kí n ní torí Fẹlá ti kọrin pè é lólè nígbà ayé ẹ̀, èmi ò ní í gba àmọ̀ràn tó le ṣeni láǹfàání tí Ọbásanjọ́ bá mú wá. Ìwà aláìnílàákáyè lèyíun. N ò sì ṣe Aníkúlápó fúnra rẹ̀ lóore kankan nípa bíbá ọgbọ́n ṣọ̀tàá.

Ohun tó sì fà á rèé tí mo fi fara balẹ̀ ka ìwé ńlá alábala mẹ́ta tí bàbá fi kọ ìtàn ìgbésí ayé wọn, èyí tí wọ́n pe àkọ́lé ẹ̀ ní MY WATCH Vol. 1-3. Gbogbo ìgbà tí orúkọ bàbá yìí bá jáde nínú ìwé ìròyìn tàbí lórí ẹ̀rọ ayélujára ni mo máa ń fẹ́ẹ́ lọọ kà nípa ẹ̀. Irú ẹ̀ lèyí tó jáde láìpẹ́ yìí tá a rí Olóyè Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ níbi tí wọ́n ti ń pàṣe fáwọn ọba aládé pé kí wọ́n dìde bí ọmọ iléèwé, tí wọ́n sì tún ní kí wọ́n jókòó padà.

Nígbà tí mo kọ́kọ́ rí fídíò yìí, apá ibì kan ní ìpínlẹ̀ Ògùn ni mo kọ́kọ́ pè é. Ẹ̀yìn tí mo wáá túbọ̀ tọ pinpin ọ̀rọ̀ náà ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wáá rí I pé lẹ́kùlé mi ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ló ti ṣẹlẹ̀.

Áh! Ikú bọlá jẹ́. Irú nǹkan báyìí ní í máa múni rántí Aláàfin àná, Láyíwọlá Àtàndà Adéyẹmí Alówólódù-bí-ìyèré. Eegun ṣóńṣó tí í parí iké, ọba ńlá tí í mú ọba jẹ. Ibikíbi tó o bá wà ilẹ̀ ire. Kìbá jẹ́ pé bàbá yìí wà láyé ni, irú èmi yìí ò ní í kọ ọ̀rọ̀ kan jáde rárá, ọ̀rọ̀ tí bàbá yìí bá sọ la óó kàn máa fọn rere rẹ̀ káàkiri. Àmọ́ ó ṣeni láàánú, àgbà ò sí nílùú ìlú bàjẹ́, baálé ilé kú ilé dahoro.

Bí a bá wo ìtumọ̀ àṣà lédè òyìnbó, a óó rí I pé àkóónú ìwà àti ìṣe àgbáríjọpọ̀ èèyàn tí wọ́n rí ara wọn bí ọmọ ẹ̀yà tàbí ọmọ orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo ni.

Lára àkóónú àṣà ni ètò ìṣèjọba wà. Kò sí ẹ̀yà èèyàn náà lórí ilẹ̀ ayé yìí tí kò ní ètò ìṣèjọba tirẹ̀ àfi tó bá jẹ́ àkóríjọpọ̀ ọ̀bọ tó fojú jọ̀ọ̀yàn ni wọ́n ló kù.

Nínú ètò ìṣèjọba Yorùbá tó fi hàn pé èèyàn ni wá a kì í ṣe ọmọ ọ̀bọ, òbí ní í ṣàkóso ilé, Baálé ní í ṣàkóso agboolé, Baálẹ̀ ní í ṣàkóso ìletò, Ọba tòun tìjòyè ní í ṣàkóso ìlú. Nínú àṣà Yorúbá, gbogbo agbára àti ìṣàkóso ìlú pin sọ́wọ́ ọba àti àwọn olóyè rẹ̀. Èyí ni a ṣe dé bá a lẹ́nu àwọn baba wa pé ọba ni aláṣẹ ìkejì òrìṣà. Ìyẹn ni pé Ọba ni nọmba wán sitisìn, lẹ́yìn ẹ̀, àwọn òrìṣà tí kò sí láyé mọ́ ló kù.

Ìgbà tí ebi pa àwọn òyìnbó wọ ilẹ̀ adúláwọ̀, tí wọ́n fi ogun gba agbára lọ́wọ́ ètò ìṣèjọba wa ni wọ́n fi ipá ṣàgbékalẹ̀ ètò ìṣèjọba tó jẹ yọ látinú àṣà wọn nílùú tiwa. Ètò ìṣèjọba ọ̀hún náà ló yíjú títí di ohun tá à ń lò lónì-ín.

Lóòótọ́, oyè ọ̀wọ̀ lásán lohun tó kù lọ́wọ́ àwọn ọba wa kì í ṣe oyè agbára. Oyè tó ń ṣàfihàn àti ìrántí pé àwọn òyìnbó ò bá wa lẹ́ranko, ìran èèyàn tó ní àṣà àti ètò ìṣàkóso rẹ̀ ni wá ṣáájú kóyìnbó tóó dé.

Gẹ́lẹ́ bí oyè Gómìnà, Kọmíṣánnà, Mínísítà, àti Púrẹ́sídẹ́ǹtì pàápàá ṣe jẹ́ ipò òṣèlú tó jẹ yọ látinú àṣà ìṣèjọba òyìnbó, bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ loyè ọba, tàwọn olóyè àti baálẹ̀ ṣe jẹ́ oyè òṣèlú ìbílẹ̀ tí òyìnbó fìjọ̀gbọ́n gba agbára lọ́wọ́ ẹ̀.

Bí òyìnbó Lugbard tàbí ọmọ ẹ̀yà mì-ín tó wà lórí oyè òṣèlú àṣà òyìnbó nílẹ̀ wa bá lo agbára rẹ̀ fi yẹ̀yẹ́ ipò òṣèlú Yorùbá tí wọ́n ti gba agbára lọ́wọ́ ẹ̀, gbogbo wa kàn lè máa kùn sínú ṣépè fún un pé Ọlọ́run yóó dá a fún alágbára tí í fi agbára rẹ̀ yan-ni-jẹ. Ṣùgbọ́n bí ọmọ Yorùbá tó mọ bí àwa àti àwọn babańlá wa ṣe pàtàkì ipò òṣèlú wọ̀nyí bá wáá yẹ̀yẹ́ ẹ̀ lójú agbo báyìí, irú orúkọ wo ni ká pe ọmọ ọ̀hún?

Àgbà inú àwùjọ ni Olóyè Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́. Àṣà Yorùbá sì ti lọ́ mi lẹ́nu, ó ní a kì í wo àgbà fìn-ín mọ ilà tó kọ. Ṣé ẹni tí àṣà ti kì mí nílọ̀ pé n ò gbọdọ̀ wò lójú débi tí n óó mọ ilà tó kọ ni ń óó lanu lágbárí fi bẹnu àtẹ́ lu ìwà àìdáa rẹ̀?

Ṣùgbọ́n àṣà yìí kan náà ló ní ọmọ àlè èèyàn ní í fọwọ́ òsì júwèé ilé bàbá rẹ̀. Lójú mi sì rèé, ìwà fífọwọ́ òsì júwèé ilé baba ẹni lèyí tí Olóyè Ọbásanjọ́ wù nípa yíyẹ̀yẹ́ àṣà ìran wa lójú gbogbo ayé yìí.

Ìgbà tí wọ́n óó sì jàjà sọ̀rọ̀, wọ́n ní Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ làwọn fi kinní náà pọ́n lé. Àwọn yìí i pé bí àwọn ọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ṣe ń jòkòó kí Gómìnà kò buyì kún un rárá, níṣe ló yẹ kí wọ́n dìde nítorí ìwé òfin Nàìjíríà ti gbé wọn sábẹ́ ẹ̀. Bẹ́ẹ̀, látòkè-délẹ̀ ìwé òfin Nàìjíríà, èmi ò ríbi tí ìwé òfin Nàìjíríà ti dárúkọ oyè ọba aládé kan pàtó pé ó wà lábẹ́ Gómìnà tàbí Ààrẹ Nàìjíríà kankan. Oyè ọ̀wọ̀ loyè wọn, oyè tí àá fi í rán ara wa létí pé ṣáájú kí Òyìnbó tóó dé la ti ń ṣètò àkóso ayé wa. Ohun tó bá sì mú kí àwọn àgbà ìlú máa yẹ̀yẹ́ ẹ̀ ní gbangba báyìí tí wọ́n sì kọ̀ láti túúbá, ẹnu tiwa kò gbà á láti pè wọ́n lọ́mọ àlè, ṣùgbọ́n ohun tí àṣà Yorùbá sọ fún wa ni pé ọmọ àlè ní í hùwà bẹ́ẹ̀.

Ohun tí Olóyè Ọbásanjọ́ ṣe yìí ò lè tán nílẹ̀ àfi bí wọ́n bá kọ̀wé èbùrẹ́ ni gbangba, torí ní gbangba ni wọ́n ti yẹ̀yẹ́ ìran wa.

Láti fèsì sí fọ́nrán yìí tàbí ọ̀kankan nínú àwọn fọ́nrán Iris Media Prospects Services, ẹ lè kàn sí wa lórí nọ́mbà yìí, +2348085548868. Ẹ share fídíò yìí tó bá ṣe yín lánfààní, ilẹ̀kùn wa sì ṣí sílẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ tí yóó túbọ̀ mú kí iṣẹ́ wa máa tẹ̀síwájú sí I nínú àwùjọ. Musa Babátúndé-Kọ́gà lorúkọ mi. Òjò ni mí n ò bẹ́nì kan ṣọ̀tàá, ẹni eji rí leji ń pa. Àárá ni mí n ò bẹ́nì kan ṣọ̀tẹ̀, ẹni bá dènà dè mí ni óó ríjà arábámbí onígba ọta. Ojú tí mo fi rí ohun tó ń lọ nínú àwùjọ rèé, ìyókù tún dọjọ́ mì-ín táàyè bá gbà mí níbi tí ẹnu mi óó ti lè rọ́rọ̀ sọ.

Ire o




Post a Comment

0 Comments