Ṣáájú kí ọ̀rọ̀ à ń fi POS gbowó tóó gbòde tó báyìí, gbogbo ará Mòwé tó bá fẹ́ẹ́ gbowo gbọdọ̀ lọọ tò nídìí ATM báǹkì First Bank tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Police Station Bus stop Mòwé. Ohun tí mo lọọ ṣe rèé lọ́dún 2014 tí mo fi kó sọ́wọ́ àwọn ajínigbé.
Mo ti gbowó tán kí ọkùnrin kan tóó wáá bá mi nítòsí ọjà mòwé. Ó kí mi, èmi náà sì kí i. Ó ní láti ìlú Èkìtì lòun ti wá, mo ti gbàgbé ibi tó lóun ń lọ gan-an ní pàtó. Ṣùgbọ́n mo rántí pé n ò mọ ibẹ̀ débi tí n óó le júwèé fún un, ohun tí mo sì ń sọ fún un lọ́wọ́ rèé tí ẹnì kan fi wáá bá wa tó bèèrè pé ṣé ò sí? Mo dárúkọ ibi tọ́kùnrin ọ̀hun lóun ń lọ, kàkà kónítọ̀hún sì júwèé, ohun tó bèèrè lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni pé kí ló fẹ́ẹ́ lọọ ṣe níbẹ̀. Ìyẹn lóun fẹ́ẹ́ lọọ ta nǹkan kan ni, n ò ràntí ohun tó lóun féẹ́ lọọ tà yìí, ṣùgbọ́n bí onítibí ṣe gbọ́ orúkọ ohun tó fẹ́ẹ́ lọọ tà yìí ló bèèrè pé “Ṣé ó wà lọ́wọ́ yín báyìí?” Ara èyí tó ń bèèrè ọ̀nà kó tìọ̀ láti dáhùn. Nígbà tóun náà rí èyí ló ṣẹ̀ṣẹ̀ wáá ní ibi tó ń lọ ò jìnnà, òun óó mú un débẹ̀ fúnra òun.
Lẹ̀rù bá ba ẹni tó ń bèèrè ọ̀nà, ó so mọ́ mi pé òun ò lè tẹ̀lé ẹni tó fẹ́ẹ́ mú òun débi tó ń lọ yìí. Ó ní ohun tó ń bèèrè yìí wà lọ́wọ́ òun lóòótọ́, ohun tóun jogún lọ́dọ̀ baba òun tóun fẹ́ẹ́ tà nítorí àbúrò òun tó wà níléèwòsàn ni. Ojú ẹni tóun ń wò yìí le ó sì lè ṣe òun níjàm̀bá, kí n jọ̀wọ́ tẹ̀lé àwọn dé iléeṣẹ́ tóun ti fẹ́ẹ́ tà á yìí kí ọkàn òun le balẹ̀. Bẹ́ẹ̀ lọkùnrin yìí ń rán èdè Èkìtì lẹ́nu bí ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ toko dé.
Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni ẹ̀mí mi ti kọ̀ ọ́. Bí ẹ̀mí mi ṣe kọ̀ ọ́ lèmi náà sì ṣe kọ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ si í bẹ̀ mí pé kí n ran òun lọ́wọ́, ó dárúkọ àrùn tó ń ṣe mí nínú ara tí n ò sọ fẹ́nì kan. Ó ló níwòsàn, bí mo bá le ran òun lọ́wọ́ òun náà óó ràn mí lọ́wọ́. Níbi tí mo ti kó sí i lọ́wọ́ gan-an rèé tí mo ti bẹ̀rẹ̀ si í tẹ̀lé wọn. Ẹ̀mí mi ń sọ fún mi pé ohun tí yóó tẹ̀yìn ojú-ọ̀nà tí mò ń tẹ̀lé wọn yìí ò dáa, ṣùgbọ́n n ò lè padà mọ́. Ohun tí mo kàn ń lè sọ ni pé, “Oore dẹ̀ ni mo fẹ́ẹ́ ṣe yín o.”
Èyí tó fẹ́ẹ́ júwèé ọ̀nà ló kọ́kọ́ sọdá sódìkejì. Ó dà bíi ẹni pé oore dẹ̀ ni mo fẹ́ẹ́ ṣe yín tí mò ń sọ yìí ló kó wọ ẹnì kejì lọ́kàn tó fi ní, “Ó dáa, tẹ́ ẹ̀ bá le ràn mí lọ́wọ́ ẹ lè máa lọ o.” Ní kété tó wí bẹ́ẹ̀ ni mo gba àkóso ara mi padà, mo kọ ìpàkọ́ sí wọn bẹ́ẹ̀ ni mò ń lọ tààrà. Èyí tó ti sọdá sódìkejì ń pariwo pè mí n ò dáhùn mọ́. Ọ̀nà ilé ni mo kọrí sí gbọ̀n-ọ́n.
Ìgbà tí mo délé tí mo ṣàlàyé ohun tójú mi rí, àwọn kan ní oníjìbìtì ni wọ́n. Bí wọ́n ṣe ṣe fẹ́nì kan náà rèé ní Kétu tí wọ́n gba gbogbo owó ọwọ́ ẹ̀ àti ohun tó ní kí iye rẹ̀ tóó sọ. Àwọn kan sì ní oníjìbìtì lásán kọ́ ni wọ́n o, ẹ̀yìn tí wọ́n bá gba gbogbo ohun tí wọ́n fẹ́ẹ́ gbà lára onítọ̀hún tán pàápàá, níṣe ni wọn óó pa á kó má baá tú wọn lásìírí. Lẹ́yìn tí wọ́n bá pa á tán ni wọn óó tún ta ẹ̀yà ara rẹ̀ fún àwọn tí yóó fi í ṣòògùn owó. Ohun tí àwọn ọ̀daràn tó ń ṣe irú ẹ̀ sọ rèé lẹ́yìn tọ́wọ́ àwọn agbófinró tẹ̀ wọ́n.
Èmi o mọ ohun tí ìbá ṣẹlẹ̀ lójú ọ̀nà ibi tí mò ń tẹ̀lé àwọn ọ̀daràn yìí lọ, bóyá jìbìtì ni, ìjínigbé ni tàbí ikú oró látọwọ́ àwọn tó ń wá owó gbígbóná. Ṣùgbọ́n fún gbogbo àwọn tó tẹ̀lé irú wọn dópin ọ̀nà tí wọn ò padà wálé mọ́, àti àwọn aláìmọ̀kan tó ṣì ń lọ́wọ́ sí ìwà láabi yìí tó fi ń tẹ̀síwájú nínú àwùjọ ni mo ṣe kò sí iṣẹ́ ìwádìí láti ṣàwárí òògun owó tó dájú tí kò ní í la ìtàjẹ̀sílẹ̀ lọ. Pẹ̀lú ìdùnnú ni mo fi mú ìròyìn ayọ̀ yìí wá fún gbogbo ẹni tó ń kúṣẹ̀ẹ́ pé mo ti rí i, òògùn owó tó dájú, tó jẹ́ pé kẹ́ ẹ tóó ṣe é rárá lẹ̀yin gan-an óó ti mọ̀ pé iṣẹ́ ti óó dáhùn ni bí èròjà rẹ̀ bá ti pé.
Intro.
Bí wọ́n bá fẹ́ẹ́ ṣiṣẹ́ ìwádìí lórí irú nǹkan báyìí lágbo àwọn onímímọ̀, níṣe ni wọn óó kọ́kọ́ pín ọ̀rọ̀ ọ̀hún sí ẹyọ-ẹyọ, wọn óó wáá ṣèwádìí lórí ẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan láti nímọ̀ tó kúnná nípa ohun tí wọ́n ń wádìí ẹ̀ yìí. Òògùn owó ni mò ń wádìí ẹ̀, láti nímọ̀ tó kúnná nípa ẹ̀, mo ní láti pín in sọ́nà méjì – òògùn àti owó.
Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ mú un látorí oògùn ká tóó kan owó. Kí là ń pè lóòògùn? Òògùn ni ohun èèlò ìwòsàn tí àá fi í dẹ́kun àìlera nínú ara èèyàn tàbí ẹranko. Yàtọ̀ sí ojú ìwòsàn tí a le fi wo òògùn, ìtumọ̀ mì-ín tí òògùn ní láwùjọ wa ni ohun èèlò idán tó le ṣàyípadà nǹkan lọ́nà tó tako ìrírí ènìyàn nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ àti èyí tí ò lè ṣẹlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìrírí ọ̀pọ̀ èèyàn nípa aṣọ ni pé bí a bá jù ú síná yóó jó rúgúrúgú, bí a ò bá sì tètè yọ ọ́ pàápàá, yóó deérú tí ò ní í padà sípò tó wà kó tóó kó sínú iná mọ́. Ṣùgbọ́n bééyàn kan bá lóun mọ nǹkan tó le mú kí aṣọ kó sínú iná tí kò sì ní í jó o láì jẹ́ pé aṣọ ọ̀hún ń rin fún omi tó le pa iná, tàbí tó ní òun le dá aṣọ tó jóna deérú padà sípò tó wà kó tóó kó síná láì jẹ́ pé yóó pààrọ̀ aṣọ ọ̀hún ní kọ̀rọ̀ tẹ́nìkan ò ti ní í fura sí i, òògùn idán nù-un. Òògùn tó le ṣe ohun tó tako làákáyè èèyàn nípa ohun tó le ṣẹlẹ̀ àti èyí tí kò lè ṣẹ̀lẹ̀.
Lẹ́yìn tá a ti fọ́ òògùn sí ohun méjì tó túmọ̀ sí, ìyẹn òògùn ìwòsàn àti òògùn idán, ẹ wáá jẹ́ ká wádìí owó tó mú wa wádìí òògùn gan-an. Kí là ń pè lówó? Owó jẹ́ ohun àjọmọ̀ tí kò níyì kan ju iyì tí ọ̀pọ̀ èèyàn tó kóra jọ sójú kan tàbí lórílẹ̀-èdè kan bá fún un láti sọ ọ́ dohun tí wọ́n fi ń díwọ̀n iyì ara wọn. Bí àpẹẹrẹ, bí mo ṣe ń bá yín sọ̀rọ̀ yìí tí ò bá jẹ́ pé ẹ ti jẹun lónì-ín ó dájú pé ẹ óó ṣì fẹ́ẹ́ jẹun. Bí ìnira ebi bá dé tí ẹ fẹ́ẹ́ pa oró ẹ̀, kàkà kí ẹ wá óúnjẹ, owó Náírà tí ẹ óó mú lọ sọ́dọ̀ ẹni tí yóó fún yín lóúnjẹ lẹ óó máa wá. Kì í ṣe owó ni yóó poró ebi yìí o, ṣùgbọ́n owó lẹ óó mú lọọ bá ẹni tó fi àkókò tó yẹ kó fi sinmi dáná óúnjẹ tí yóó poró ebi tiyín kó tóó le fún yín nínú óúnjẹ́ tó fi àkókò rẹ̀ sè. Torí òun náà mọ̀ pé bí gbogbo óúnjẹ tóun sè yìí bá tán, owó Náírà yìí kan náà lòun óó fún àwọn àgbẹ̀ tí wọ́n fi àkókò tó yẹ kí wọ́n fi sinmi gbin óúnjẹ kí wọ́n tóó le kó óúnjẹ ọ̀hún fóun. Àgbẹ̀ náà yóó gba owó Náírà yìí yóó kó iṣu sílẹ̀ nígbà tóun náà mọ̀ pé bí ẹ̀yìn bá bẹ̀rẹ̀ si í ro òun lẹ́nu iṣẹ́ tóun ń ṣe yìí, nígbà tóun bá dé ọ̀dọ̀ kẹ́míìsì tí yóó fún òun lóòògùn ẹ̀yìn, owó Náírà yìí náà lòun óó mú lọ fún un kó tóó le jọ̀wọ́ òògùn tí yóó wo òun sàn. Kẹ́míìsì náà ò ní í lóun ò kó òògùn sílẹ̀ bó bá rí owó Náírà, nígbà tó mọ̀ pé bí ebi bá dé, owó náírà yìí kan náà lòun óó mú lọ fẹ́ni tó ń se óúnjẹ tà, ìyẹn óúnjẹ tó gbà lọ́wọ́ àgbẹ̀ yìí, kó tóó le bu óúnjẹ ọ̀hún fóun.
Bí a bá wo àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí, a óó rí i pé àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni wọ́n ń fẹ́ nǹkan lọ́wọ́ ara wọn. Ohun tí wọ́n sì ń fẹ́ lọ́wọ́ ara wọn kì í ṣe owó rárá, ṣùgbọ́n owó ni wọ́n óó fún ara wọn tí wọ́n óó fi rí i gbà. Ẹ jẹ́ ká rò ó nínú ọkàn wa pé àgbẹ̀ tó ń gbin óúnjẹ yìí kó o fún ẹni tó fẹ́ẹ́ lọọ sè é tà lọ́fẹ̀ẹ́, nígbà tí kẹ́míìsì náà óó sì lọọ bá ẹni tó ń se óúnjẹ tà, òun náà gbà á lọ́fẹ̀ẹ́ – ó jẹun àjẹyó. Ìgbà tí ẹ̀yìn wáá bẹ̀rẹ̀ si í ro àgbẹ̀ tó ń gbin iṣu, tó wá òògùn lọ sí ṣọ́ọ́bù kẹ́míìsì, ó bá ṣọ́ọ̀bù ní títì pa. Kẹ́míìsì ò wulẹ̀ wá sí ṣọ́ọ́bù nígbà tó ti mọ̀ pé kò sí ohun tóun fẹ́ tóun ò ní í rí lọ́fẹ̀ẹ́, kí lòun ò sùn ti ìyàwó òun nílé sí káwọn jọ máa gbádùn ara àwọn. Àgbẹ̀ ò wáá róògùn gbà ẹ̀yìn ń ro ó kò lè gbin óunjẹ, ẹni tó fẹ́ẹ́ se óúnjẹ tà ò rí óúnjẹ tí yóó sè tà nígbà tí àgbẹ̀ ò le gbìn. Bó pẹ́ bó yá, ọ̀rọ̀ ọ̀hún yóó padà kan ọ̀gá kẹ́míìsì, torí bí ẹni tó ń se óúnjẹ ọ̀fẹ́ ò bá sè é, kò síbi tí yóó ti rí oúnjẹ ọ̀fẹ́ tó fi í lọ́kàn balẹ̀ tó fi lóun ò ní í wúlò fẹ́nì kan.
Ohun tí gbogbo àwùjọ káàkiri àgbáyé ṣe ṣẹ̀dàá owó rèé láti fi díwọ̀n ìwúlò ara wa fún ara wa. Ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń sáré owó lónì-ín ò mọ̀ pé owó gan-an kọ́ làwọn ń wá, ohun tí wọ́n ń wá gan-an ni kí àwọn èèyàn wúlò fáwọn. Ṣùgbọ́n ìṣẹ̀dá owó nínú àwùjọ ń sọ ọ́ pé bí o bá ń fẹ́ káwọn èèyàn wúlò fún ọ, dandan ni kí ìwọ náà wúlò fún ẹlòmì-ín.
Owó yìí ò wáá dà sílẹ̀ látọ̀run, ó ní iléeṣẹ́ ìjọba tó ń tẹ̀ ẹ́ tá à ń pè ní Central Bank of Nigeria, ó sì lóye tí wọ́n gbọdọ̀ tẹ̀ lọ́dún kan kí owó ọ̀hún má baà di yẹ̀yẹ́ kó sì le ṣiṣẹ́ ẹ̀ láwùjọ. Owó àwùjọ gbọdọ̀ jẹ́ ohun tí yóó máa mú kí iṣẹ́ lọ nínú àwùjọ, bí iṣẹ́ bá sì ń lọ nínú àwùjọ, ìtẹ̀síwájú óó máa bá irú àwùjọ bẹ́ẹ̀.
A ti mọ ìtumọ̀ òògùn, a sì ti mọ ìtumọ owó, ẹ wáá jẹ́ ká wọ inú òògun owo gan-an. Òògùn owó lòògùn idán tá a gbàgbọ́ pé ó le ṣe ohun tó tako làákáyè èèyàn nípa ohun tó le ṣẹlẹ̀ àti èyí tí ò lè ṣẹlẹ̀ nípa ṣíṣẹ̀dàá owó tí yóó mú kí àwọn èèyàn wúlò fún wà láì jẹ́ pé a wúlò fún wọn. Àwọn tó ń ṣe òògùn owó yìí àti àwọn tó ń ṣe fíìmù tó ṣàfihàn ẹni tó ṣòògùn owó nìkan náà ló le ṣàlàyé bí òògùn owó yìí ṣe ń jẹ́ gan-an. Bóyá òògùn ọ̀hún yóó tẹ ẹ̀dà owó Nàírà fún wọn ni o, tàbí yóó lọọ gbé nínú ìwọ̀nba owó tí iléèṣẹ́ ìjọba tẹ̀ láti rí i dájú pé ẹnì kan kò rí ìwúlò ẹnì kan láì jẹ́ pé òun náà wúlò fẹ́lòmì-ín ni, bóyá yóó sì lọọ yọ nínú owó ẹni tó ṣiṣẹ́ pawó sápò ara rẹ̀ ni, àwọn onífíìmù òògùn owó àti àwọn tó ń ṣe é nìkan náà ni wọ́n le ṣàlàyé fún wa. Ṣùgbọ́n a ti gbọ́ nípa àwọn tó ṣe òògùn owó ọ̀hún tí wọn ò rí owó kankan, ohun tí àwọn ẹ̀gbẹ̀jí pálọ̀ tí ò ṣòògùn owó rí, tí ò tiẹ̀ ríbi tí wọ́n ti ṣe é rí sì ń sọ̀ ni pé orí wọn ni kò rọ̀ mọ́ ọn, tàbí orí ẹni tí wọ́n pa ló le. Àmọ́ èmi rò pé orí ẹni tó bá le yẹ kó le gbà á sílẹ̀ kó tóó di pé wọ́n pa á ni, ó ṣe wáá jẹ́ pé lẹ́yìn tí wọ́n pa á tán lorí ẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ le tí ò gbówó wá. Àwọn ẹ̀gbẹ̀jí lókà tí fíìmù ti dà lórí rú yìí óó sì máa jiyàn pé òògùn owó ń jẹ́ sẹ́ẹ̀, nígbà táwọn gan-an ò ṣe é rí débi tí wọ́n óó rẹ́ni tí wọ́n ṣe é fún tó jẹ́.
Èmi ò lóòògùn owó ń jẹ́ o, n ò sì ní ò jẹ́. A kì í gbọ́n sí ohun tá à bá mọ̀. Èèyàn ò lè lóhun tóun ò tí ì rí ò sí láyé, ó ṣeé ṣe kó máa bẹ kó jẹ́ pé ìrírí àti ìròrí wa ni ò tí í rìn jìnnà débi tó wà. Ṣùgbọ́n ohun tí ìwádìí ìwéèròyìn Punch fi hàn nígbà tí wọ́n díbọ́n tọ àwọn ológùn owó lọ ni jìbìtì àti ẹ̀ya ara èèyàn tí wọ́n ń tà fáwọn tó gbàgbọ́ nínú òògùn owó. Àwọn fúnra wọn ò lóòògùn owó kan tó ń pawó fún wọn, ẹni tó fẹ́ẹ́ ṣòògùn owó gan-an ni yóó kówó wá tí wọn óó fi po ọṣẹ fún un. Àwọn ò lè ṣe é nítorí wọn ò kúndun ohun ayé, tàbí wọ́n ń bẹ̀rù ohun tí yóó tẹ̀yin ẹ̀ yọ, ṣùgbọ́n wọ́n óó ṣe é fún oníbàárà tó bá le mú owó ẹ̀ wá.
Òògùn owó kan ṣoṣo tí èmi mọ̀ pé ó wà láyé yìí, tó ti ń jẹ́ látìgbà tí aláyé ti dáyé, tí yóó sì tún máa jẹ́ lẹ́yìn táwa bá lọ tán ni ìwúlò fúnra ẹni. Oun làwọn ológùn owó yìí pàápàá ń ṣe tí wọ́n fi ń rówó, ó kàn jẹ́ pé ọ̀nà òdì ni wọ́n ń gbà lò ó ni. Bí àpẹẹrẹ, ẹni tí ẹnu rẹ̀ bá dùn débi tó fi le lùùyàn ní jìbìtì, irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóó le fẹnu polówó ọjà tí ẹni tí ò nílò rẹ̀ gan-an ó fẹ́ẹ̀ lè yáwó rà á. Kódà kò nílò kóun fúnra rẹ̀ lọ́já kankan, ẹnu kó kàn bá iléèṣẹ́ tó ti ní ọjà tí wọ́n fẹ́ẹ́ tà polówó ọjà kájé bú igbá jẹ ni. Bí èrò bá sì ti ra ọjà ọ̀hún, ẹnu kí wọ́n sanwó fún un lórí ọjà kọ̀ọ̀kan táwọn èèyàn rà látọ̀dọ̀ tiẹ̀ ni. Ẹ̀bùn tóun ní lọ́fẹ̀ẹ́ lófò yìí, yóó yà yín lẹ́nu pé àwọn èèyàn ń lọọ lo ọdún mẹ́rin kọ́ ọ nílé ìwé síbẹ̀ tí wọn ò ní in. Ṣùgbọ́n àìmọ̀kan àti àìgbàgbọ́-nínú-ara-ẹni ò jẹ́ kí wọ́n le lo ẹ̀bùn yìí síbi tó yẹ. Dípò bẹ́ẹ̀, jìbìtì ni wọ́n fi ń lù, ẹ̀yà ara èèyàn sì ni wọ́n fi ń tà fáwọn tí wọ́n ń fẹ́ kí ayé wúlò fún wọn nígbà tí àwọn ò fẹ́ẹ́ wúlò fún ẹnikẹ́ni.
Èmi ò mọ ohun tó o mọ̀ ọ́n ṣe tó o le fi wúlò fún ẹlòmì-ín, bóyá ọjà lo mọ̀ ọ́n tà ni, iṣẹ́ ọwọ́ kan ló wà lọ́wọ́ rẹ tó o mọ̀ ọ́n ṣe ni, tàbí iṣẹ́ alákọ̀wé kan lo lọ̀ọ̀ kọ́ níléèwé bíi tèmi báyìí, ohun tó dájú ni pé bí àwọn èèyàn bá ṣe ń ra ọjà rẹ tó, bí àwọn èèyàn bá ṣe ń gbé iṣẹ́ fún ọ tó, bí ẹ̀kọ́ ìmọ̀ rẹ bá ṣe wúlò fún àwùjọ tàbí iléeṣẹ́ tó gbà ọ́ síṣẹ́ tó lowó óó ṣe ọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ tó o.
Fún ẹni tó ń tajà, rí i dájú pé ohun táyé ń wá lò ń tà, sì rí i dájú pé o ò jìnnà síbi táwọn tó nílò ọjà rẹ wà. Àmọ̀ràn tí mo máa ń fún àwọn ọlọ́jà ni pé kí wọ́n rí ọjà wọn bí ọmọge tó ti tó ilé-ọkọ í lọ. Kó kun pankéèkì rẹ́dẹ́rẹ́dẹ́ báwọn ọlọ́mọge òde òní ṣe ń kùn ún, kó múra ìpèníjà tí í sọmọ ọkùnrin dọ̀bọ fún irú ọkọ tó ń wá, ẹ wáá ní kó gbatẹ́gùn lọ òpópónà àwọn báṣẹ́lọ̀ tó ti táyaa gbé sílé. Bí ò bá ní nǹkan mì-ín nínú, kò gbọdọ̀ lọ bẹ́ẹ̀ kó má réèyàn sìn ín wálé, àgbẹdọ̀! Ohun tá a ṣe máa ń bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọlọ́jà rèé pé ṣé ọjà yín dáa, ṣé ó dùn ún wò, ǹjẹ́ agbo àwọn tó sì ti nílò rẹ̀ lẹ ti ń polówó? Nígbà tẹ́ ẹ bá wáá pé méjì-mẹ́ta níbí tẹ́ ẹ ti fẹ́ẹ́ tajà, kín nìwọ ń tà mọ́ ọjà tiẹ̀ tó yàtọ̀ tí àwọn oníbàárà óó fi fẹ́ẹ́ rà lọ́wọ́ ẹ ṣáájú kí wọ́n tóó ra ohun tó ò ń tà lọ́wọ́ ẹlòmì-ín? Dáńgótè nìkan kọ́ ló ń ta sìmẹ́ǹtì ní Nàìjíríà o, ṣùgbọ́n sìmẹ́ǹtì Dáńgótè làwọn èèyàn ń rà jù ló sọ ọ́ dolówó Áfíríkà. Kódà kó jẹ́ Náírà kan lọjà tó ò ń tà, béèyàn mílíọ̀nù kan bá fi rajà lọ́wọ́ rẹ - mílíọ̀nù kan ló wọlé sápò rẹ yìí o. Bó bá wáá jẹ́ Náírà mẹ́wàá lọjà tó o tà féèyàn mílíọ̀nù kan, láì sí àní-àní, mílíọ̀nù mẹ́wàá ni yóó wọ àpò rẹ lẹ́yìn ọjà yìí. Àbí o rò pé iṣẹ́ ọ̀hún óó pọ̀ jù fún ọ? Èmi ò mọ iye tó ń wá o, ṣùgbọ́n tó ò bá le ṣiṣẹ́ kó owó ọ̀hún jọ fún ara rẹ̀, èèyàn onílàákáyè pípé wo ni óó lọọ ṣiṣẹ́ kó owó ọ̀hún jọ fún ọ?
Ọ̀rọ̀ yìí kan náà ló dífá fún oníṣẹ́ ọwọ́ tó ń wówó. Wà nítòsí ibi tí wọ́n ti nílò iṣẹ́ rẹ. Bí àpẹẹrẹ, fún ẹni tó ń kunlé, àwọn abánikọ́lé, àwọn bíríkìlà, àwọn kápẹ́ńtà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ló yẹ kó o mú lọ́rẹ̀ẹ́. Kò yẹ kó o jìnnà sáwọn àdúgbò ibi tí ilé ṣẹ̀ṣẹ̀ ń pọ̀ sí. Àwọn èèyàn gbọdọ̀ mọ̀ ọ́ mọ iṣẹ́ rẹ débi pé wọn ò ní í gbàgbé àti dárúkọ rẹ níbi tí wọ́n ti ń wá ẹni tó ń kunlé. Ǹjẹ́ nígbà tí wọ́n bá sì pè ọ́ tí wọ́n gbéṣẹ́ fún ọ, ṣe é kó dáa ju bí ẹgbẹ́ rẹ yòówù yóó ṣe ṣe é lọ. Bóyá bí àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ bá kunlé tán wọ́n óó fi gbogbo ibẹ̀ sílẹ̀ ní dídọ̀tí tí ọ̀dà óó yí gbogbo ilẹ̀ ni, ìwọ le ṣe tìẹ yàtọ̀ tó jẹ́ pé lẹ́yìn tí wọ́n bá wọ inú ibi tó o kùn tán yóó dà bíì ìgbà téèyàn wọ ààfin ọba ni. Ohun tí ẹni tó o ṣiṣẹ́ fún óó fi ròyìn rẹ fẹ́lòmì-ín tí yóó fi ní ẹlòmì-ín ò ní í kunlé fẹ́nikẹ́ni tóun bá mọ̀ àfìwọ. Bó o bá ṣe ṣiṣẹ́ fáwọn èèyàn sí, lowó ọwọ́ rẹ óó ṣe pọ̀ tó. Èmi ò mọ iye tó ò ń wá tí yóó fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀ o, ṣùgbọ́n bó ò bá le ṣiṣẹ́ kó owó ọ̀hún jọ fún ara rẹ̀, ta ni yóó lọọ forífọ̀nná kó o jọ fún ọ nígbà tíwọ gan-an ò lè ṣe wàhálà kó o jọ fúnra rẹ?
Bó bá sì jẹ́ ẹ̀kọ́ alákọ̀wé nìwọ lọọ kọ́ níléèwé tí wọ́n gbà ọ́ síṣẹ́, ṣiṣẹ́ nípò yòówù tí wọ́n bá gbà ọ́ sí débi pé iléeṣẹ́ ọ̀hún ò ní í fẹ́ẹ́ pàdánù rẹ. Ṣiṣẹ́ débi pé bí ààyè ìgbéga bá yọ, orúkọ rẹ̀ làwọn ọ̀gá tó bá ṣòótọ́ óó rántí. Bó bá sì jẹ́ ibi tí wọn ò ti mọ iyì iṣẹ́ àṣekára lo há sí, kúrò níbẹ̀ bọ́ síbi tí wọ́n óó ti mọ iyì rẹ. Kò sẹ́ni tó pàdánù bí ò ṣe àwọn tí wọ́n ò mọ rírí ẹni tó ń wúlò fún iléeṣẹ́ wọn. Lọ síléeṣẹ́ mì-ín tí wọn óó ti mọ iyì rẹ. Bó ò bá sì tètè rí, kàn sí àwọn tó le ṣiṣẹ́ kárakára bíi tìrẹ̀ kẹ́ jọ dá iléeṣẹ́ tí yóó máa pawó sílẹ̀. Bẹ́ ẹ̀ bá le ronú jinlẹ̀ ṣẹ̀dàá iléeṣẹ́ tí yóó wúlò láwùjọ, tí àwọn tó lówó lọ́wọ́ óó fẹ́ẹ́ kówó lé e lórí pẹ̀lú àfojúsùn pé iléeṣẹ́ ọ̀hún óó pe èrè fún wọn, aa jẹ́ pé ìwọ fúnra rẹ̀ ò wúlò tó fún iléeṣẹ́ tó o ti ń retí owó tó ju iṣẹ́ rẹ lọ nù un. Bó bá sì jẹ́ pé ọ̀kan nínú àwọn alákọ̀wé tí wọ́n jáde níléèwé tí wọ́n rí kọnẹkṣàn àbúro bàbá kan tó fi wọ́n sí ọ́fíìsì kan tí wọ́n ti ń pawo ju iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe ni ọ. Mo kí ọ kú oríburúkú tó ò tí ì mọ̀ pé ó bá ọ. Pẹ̀lú ìbànújẹ́ ni mo fi ń sọ fún ọ pé o wà lára àwọn tó ń dá kún ìṣẹ́ inú àwùjọ. O ò yàtọ̀ sí kẹ́míìsì tí mo sọ̀rọ̀ rẹ̀ níṣàájú tó jẹ óúnjẹ ọ̀fẹ́ tí ò fẹ́ẹ́ ṣiṣẹ́, pàtàkì nínú ohun tó ń ba owó orílẹ̀-èdè yìí jẹ́ ni pé àwọn tó ń ṣe ò pọ̀ tó àwọn tó ń jẹ. Àwọn kan wà bíi tìrẹ yìí tó jẹ́ pé iṣẹ́ díẹ̀ ni wọ́n ń ṣe tàbí kí wọ́n tiẹ̀ má ṣe rárá bẹ́ẹ̀ wọ́n sì ń gba owó rẹpẹtẹ jú àwọn tó ń ṣiṣẹ́ àṣekára lọ. Bí iyì owó orílẹ̀-èdè bẹ́ẹ̀ ò bá wálẹ̀, áá jẹ́ pé Ọlọ́run ṣòjòóró ni tàbí kó jẹ́ pé wọ́n ti ń lo òògùn idán nínú orílẹ̀-èdè náà tó jẹ́ pé àwọn àǹjànnú ló ń bá wọn ṣiṣẹ́ tó yẹ káwọn tó ń gbowó ọ̀fẹ́ ṣe. Torí bí àwọn púpọ̀ yìí ò bá ṣe tí wọ́n sì ń jẹ ohun tí àwọn díẹ̀ tó ń ṣiṣẹ́ àṣekára ṣe láì rérè, kò sí bí orílẹ̀-èdè bẹ́ẹ̀ óó ṣe jẹ àjẹṣẹ́kù débi tí orílẹ̀-èdè mì-ín óó máa wáá rà lọ́wọ́ ẹ̀.
Oríburúkú tí mo sì sọ pé ó bá ọ tó ò tí ì mọ̀ ni pé, oun tó ṣẹlẹ̀ sí kẹ́míìsì ń bọ̀ wáá ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà. Ounjẹ ọ̀fẹ́ tó fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀ tí ò jẹ́ kó o ṣiṣẹ́ ń bọ̀ wáá tán tí ìwọ àti àwọn ọmọ àwùjọ tó kù óó padà máa wáá gbé abọ́ kiri tọrọ óúnjẹ lọ́wọ́ àwọn àwùjọ tó rí i dájú pé ọmọ orílẹ̀-èdè wọn kan ò jẹ níbi tí ò ṣe sí. Ọlọ́run ò ní í jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa dà bẹ́ẹ̀ kó tóó yé wa o.
N ò mọ ipò tó o wà lọ́wọ́ yìí bó o ṣe ń gbọ́ mi. N ò mọ irú gbèsè tó ti mù ọ́ lẹ́wù tó o fi rò ó pé òògùn owó nìkan lọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro rẹ. N ò mọ́ bóyá o ti lọ sọ́dọ̀ àwọn tí yóó bá ọ wá ẹni tẹ́ ẹ fẹ́ẹ́ lò àbi bóyá wọ́n tiẹ̀ ti bá ọ rẹ́nì kan jí gbé tó jẹ́ pé kẹ́ gba ẹ̀mí lẹ́nu onítọ̀hún ló kù. Mo fẹ́ kó o rántí pé a ò tí ì rí ọlọ́pọlọ pípé kan tó jáde sọ níta gbangba pé òògùn owó lòun ṣe là tó sọ òun dolówó. Ṣùgbọ́n òògùn owó èyí tí mo ṣàlàyé yìí, a rí i pé òun làwọn tí wọ́n láwọn ń ṣòògun owó ń ṣe tí wọ́n fi ń gbowó lọ́wọ́ àwọn èèyàn. Wọ́n óó láwọn le wúlò fún wọn nípa ṣíṣe òògùn owó fún wọn ni tàbí nípa wíwá ẹ̀ya ara èèyàn tó ṣòrò fún wọn láti rí. Dípò gbígbàgbọ́ nínú àwọn èèyàn wọ̀nyí, mo fẹ́ẹ́ bèèrè pé ọ̀nà tó bófin mu wo nìwọ le gbà wúlò fẹ́lòmì-ín? Ìwúlò wo lo le ṣe fún aráayé tó jẹ́ pé yóó máa dùn mọ́ ìwọ fúnra rẹ̀ nínú bí o ṣe ń wúlò fún ìran ènìyàn? Ọ̀nà yìí nìkan lèmi mọ̀ pé o le gbà fi rí ohun tó ò ń wà, ohun tí yóó mú kí àwọn èèyàn tó kù láwùjọ náà wúlò fún ọ rèé.
N ò mọ̀ bóyá o ti gbọ́ ewì àtìgbàdégbà yìí rí, ṣùgbọ́n jẹ́ kí n kà á fún ọ lọ́nà mì-ín bóyá ìtumọ̀ rẹ̀ yóó le túbọ̀ wọ̀ ọ́ lára.
Iṣẹ́ lòògùn kan ṣoṣo tá à lò sí ìṣẹ́
Múrá sí iṣẹ́ rẹ ọ̀rẹ́ mi
Iṣẹ́ la fí í dẹni gíga.
Bí a ò bá rẹ́nì kan fẹ̀yìntì
Bí ọ̀lẹ la óó rí
Bí a ò bá wáá rẹ́nìkan gbẹ́kẹ̀lé báyìí
Níṣe là áá tẹra mọ́ṣẹ́ ẹni.
Ìyá rẹ lèé lówó lọ́wọ́ bíi Fọlọ́runṣọ́ Alákijà
Bàbá rẹ sì leè lẹ́ṣin léèkàn kí mọ́tò pọ̀ rẹpẹtẹ ní gáráàjì yín
Ṣùgbọ́n bí o bá fi gbójú lé wọn.
O tẹ́ tán ọ̀rẹ́ mi, díẹ̀ ló kù.
Tórí ohun tí a ò bá jìyà fún,
Kì í lèé tọ́jọ́ bí ọ̀rọ̀ ọ̀gá kẹ́míìsì aríṣẹ́máṣe.
Ohun tí a bá fara ṣiṣẹ́ fún ní í pẹ́ lọ́wọ́ ẹni.
Apá lará tó o ní
Ìgúnpá rẹ méjèèjì nìkan sì làwọn tó le ṣe bí ọmọọyàá fún ọ.
Bí ayé bá ń fẹ́ ọ lónì-ín.
Bí o bá lówó lọ́wọ́.
Wọ́n óó ṣì tún máa fẹ́ ọ lọ́la.
Tàbí kí o wà nípò àtàtà.
Bó o bá ṣe n bọ̀ lọ́ọ̀ọ́kán layé óó ti máa rẹ́rìn-ín sí ọ.
Ìwọ dẹni tí ń ráágó tí ò rí nǹkan jẹ.
Ìgbà náà lo óó rí bí ayé tí í fẹyín sí’ni tí í yínmú sí’ni.
Ẹ̀kọ́ sì tún ń sọ’ni í dọ̀gàá.
Múra kí o kọ́ ọ dáadáa.
Bí o bá wáá rí ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n ń fẹ̀kọ̀ọ́ ṣẹ̀rìn-ín rín.
Jọ̀wọ́ má ṣe fara wé wọn.
Torí ìyà ń bọ̀ fọ́mọ tí ò gbọ́n – débi tí yóó wúlò fáwùjọ.
Ẹkún ọjọ́ iwájú ń bẹ fọ́mọ tó ń sá kiri.
Má fòwúrọ̀ ṣeré ọ̀rẹ́ mi
Múra síṣẹ, ọjọ ń lọ́.
Látọwọ́ Ọ̀jọ̀gbọ̀n Joseph Fọláhàn (JF) Ọdúnjọ, ẹni tó kọ ìwé Aláwìíyé.
Jọ̀wọ́ fi fídíò yìí ránṣẹ́ sí gbogbo ẹni tó o mọ̀ bó bá ṣe ọ́ láǹfààní, a ò mọ ẹni tí yóó kàn tí yóó kan ni. Ọmọ wa ò ní í sọnù o, ẹni wa ò sì ní í kó sọ́wọ́ àwọn alágbèédá yìí tí wọ́n óó wáá gbé ojú ẹ̀ sí pépà pẹ̀lú orí èèyàn tó gbàgbọ́ pé ó le sọ òun dolówó òjijì lọ́wọ́. Àwọn èèyàn wa ò ní í gbọ́ ibi nípa wa, àwa náà ò sì ní í gbọ́ ibi nípa wọn o.
Láti fèsì sí fọ́nrán yìí tàbí láti ṣonígbọ̀wọ́ àwọn ètò Iris Media Prospects Services kí iṣẹ́ wa le máa tẹ̀síwájú, ẹ lè fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ sí irismediaps@gmail.com tàbí kí ẹ kàn sí wa lórí Whatsapp pẹ̀lú nọ́mbà yìí, +2348085548868. Ẹ sì lè tẹ̀lé wa ní gbogbo ìkànnì ayélujára láti mọ̀ nígbàkígbà tí a bá fi ètò sórí ìkànnì ayélujára. Musa Babátúndé-Kọ́gà lorúkọ mi. Òjò ni mí n ò bẹ́nìkan ṣọ̀tàá, ẹni eji rí leji ń pa. Àárá ni mí n ò bẹ́nì kan ṣọ̀tẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni bá dènà dè mí ni yóó ríjà arábámbí onígba ọta. Ojú tí mo fi róun tó ń lọ láwùjọ wa rèé, ìyókù tún dọjọ́ mì-ín táàyè bá gbà mí níbi tẹ́nu mi óó ti léè rọ́rọ̀ sọ.
Ire o.
0 Comments