Search This Blog

ṢÉ LÓÒÓTỌ́ NI PÉ OPAY FẸ́Ẹ́ KÓWÓ ÀWỌN ÈÈYÀN LỌ?



 

Bọ́mọ bá ṣe dáadáa, ó yẹ ká wí torí ọjọ́ tí yóó ṣe ọ̀kan tó kù tá óó sán an lábàádà ọ̀rọ̀. Ọmọ tá ò gbóríyìn fún lọ́jọ́ tó ṣe dáadáa, tá a wáá ń ran-an-gun apá fún ún níyà lọ́jọ́ tó hùwà àìdáa, bí ò bá tíẹ̀ lè mú wa torí pé a jù ú lọ, Ọlọ́run tó ju gbogbo wa lọ fúnra rẹ̀ ni yóó dá sèèríà fún wa torí ìwà àìdáa àti ìyànjẹ la wù fún un.

Láyé ọjọún tí Sápá ń bá mi sùn tó ń bá mí jí nínú ilé tí ténáǹtì gbà mí sí, ọ̀kan nínú àwọn olùgbàlà tí mo sá tọ̀ ní Forex. Forex kì í ṣẹ̀èyàn o, Foreign Exchange gan-an lorúkọ rẹ̀ bá ò bá gé e kúrú. Ìtumọ̀ rẹ̀ lédè Yorùbá kò sì jù fífowó ṣòwò lọ tàbí iṣẹ́ Aṣẹ́wó lédè Yorùbá. A óó ra owó orílẹ̀-èdè kan nígbà tí kò wọ́n, a óó sì tà á nígbà tó bá pàdà wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tó jẹ́ pé ẹni tó bá ṣẹ́ dọ́là kan sí Náírà yóó gba ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta Náìrà, ìyẹn N500. Ẹni tó bá ra dọ́là méjì lásìkò yìí lẹ́gbẹ̀rún kan Náírà tó wáá padà ṣẹ́ ẹ sí Náírà nígbà tí dọ́là kan ti di N1000, ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé èrè ẹgbẹ̀rún kan Náírà lonítọ̀hún yóó jẹ. Kókó ohun tá à ń pè ní Foreign Exchange kò jù báyìí lọ, iṣẹ́ aṣẹ́wó hán-rán-ún lẹni tó ń ṣe é ń ṣe.

Àsìkò tí mò ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Forex yìí gan-an ni mo mọ kókó iṣẹ́ tí báǹkì ń ṣe fún ìdàgbàsókè àwùjọ. Kókó iṣẹ́ wọn ni láti gba owó jọ nínú àwùjọ, láti yá àwọn èèyàn lówó ọ̀hún pẹ̀lú èlé kí wọ́n fi ṣòwò jèrè. Bí wọ́n bá ṣe ń yá àwọn èèyàn lówó yìí tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́, tí wọ́n ń san án padà fún báǹkì pẹ̀lú èlé tí wọ́n bèèrè lórí owó olówó tó wà lọ́wọ́ wọn, bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni báǹkì fúnra rẹ̀ náà óó ṣe máa fún àwọn tó kówó sí wọn lọ́wọ́ ní ṣéńjì díẹ̀ díẹ̀ lórí owó tí wọ́n kó pamọ́.

Ṣáájú àwọn báǹkì ìgbàlódé tí à ń kówó sí lónì-ín, ojúbọ òòṣà tí àwọn òyìnbó ń pè ní tẹ́ḿpílì àti ààfin ọba làwọn èèyàn kọ́kọ́ ń kó àwọn ohun ìṣúra wọn sí. Ẹni tí kò bá fẹ́ kí Ṣàngó pa òun kò ní í lọọ jalè lójúbọ Ṣàngó. Ẹni tí kò bá sì fẹ́ kí Ẹ̀ṣọ́ ọba sọ orí òun kalẹ̀, kò ní í lọọ jí góólù táwọn èèyàn kó pamọ́ sáàfin. Nígbà tí àwọn ọrọ̀ yìí bá pọ̀ nílẹ̀ bẹ́ẹ̀ tí wọn ò rí nǹkan fi ṣe ni wọ́n ń yá àwọn oníṣòwò pé kí wọ́n fi í ṣiṣẹ́, nígbà tí wọ́n óó bá sì san án padà pẹ̀lú èlé - ẹni ó gbówó pamọ́ lójúbọ òòṣà tàbí ààfin ọba óó jèrè, ẹni to kówó sí wọ́n lọ́wọ́ óó jèrè, ìyẹn lẹ́yìn tí ẹni tí wọ́n yá lówó fúnra rẹ̀ bá ti jèèrè àjẹṣẹ́kù lórí òwò yòówù tó bá fẹ́ẹ́ ṣe. Ipasẹ̀ tí báǹkì ń tọ̀ rèé dònì-ín, ká gbowó jọ, ká yá àwọn èèyàn fi ṣòwò, ká sì dá a padà fólówó nígbàkigbà tó bá fẹ́ẹ́ lò ó pẹ̀lú èrè.

Kówó le máa wà ní báńkì, oríṣìíríṣìí ètò ní wọ́n óó máa ṣe láti fa àwọn èèyàn lójú mọ́ra. Òmì-ín lè ní iye báyìí-báyìí tó pọ̀ ju tàwọn ẹlẹgbẹ́ òun lọ lòun óó máa fi lé owó yín bí ẹ bá kówó pamọ́ sọ́wọ́ òun, òmí-ìn sì lè ní iye báyìí-báyìí tí kò tó iye tí àwọn ẹlẹgbẹ́ òun ń gbà lòun yóó bèèrè bí èlè bí ẹ̀yin tí ẹ̀ ń kówó sóun lọ́wọ́ bá fẹ́ẹ́ yáwó.

Lásíkò tí mò ń kọ́ Forex yìí ni mo rí i pé owó a máa wọ́n nílùú, nígbà tí gbogbo èèyàn bá ń kówó sí báǹkì kí owó wọn le máa pawó fún wọn. Bí kò bá sì sówó nílùú, iṣẹ́ ò ní í lọ nínú àwùjọ. Èyí nìjọba ṣe máa ń ṣe àwọn òfin tí yóó mú kí àwọn aráàlú gba owó kúrò ní báǹkì, ọ̀kan lára àwọn òfin bẹ́ẹ̀ ni yóó fààyè gba báǹkì láti máa dín owó olówó tó wà lọ́wọ́ wọn kù. Kò sẹ́ni tí yóó kọ́ àwọn èèyàn pé kí wọ́n kówó sí báǹkì nígbà tí wọ́n bá ń rí èrè lórí ẹ̀, kò sì sẹ́ni tí yóó fipá mú wọn láti kówó ọ̀hún kúrò nígbà tí wọ́n ń rí i pé díẹ̀ díẹ̀ lowó tí àwọn kó sí báǹkì ń yòrò.

Lọ́dún 2022 kọ́ ni Opay bẹ̀rẹ̀, láti ọdún 2018 ni wọ́n ti ń gba owó aráàlú sọ́wọ́. Ṣùgbọ́n nínú ọdún 2022 yìí gan-an ni ògo rẹ̀ túbọ̀ bú yọ dáadáa - ọpẹ́lọpẹ́ Emefiele tó tẹ owó Náírà tuntun tí kò káárí ìlú. Ọ̀kan nínú àwọn ìkànnì tí àwọn èèyàn ti ń fowó ránṣẹ́ síra wọn tí kì í yẹ̀, tó sì jẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lówó ọ̀hún yóó dé ọ̀dọ̀ ẹni tá a fi í ránṣẹ́ sí ni Opay. Yàtọ̀ sí oríṣìíríṣìí ọ̀nà ìfanilójúmọ́ra tí Opay ń lò, ọ̀kan nínú àwọn ètò tó wọ́ èrò rẹ̀pẹtẹ lọ sọ́dọ̀ wọn ni Owealth. Ǹjẹ́ kín ni Owealth yìí, àpò ìkówósí tí í ṣàfikún òwó ẹni lójoojúmọ́ ni lórí Opay. Owó tí wọ́n ń fi kún un yìí kì í ṣe owó rẹpẹtẹ o, ṣùgbọ́n bí owó èèyàn bá ṣe pọ̀ tó ni owó ọ̀hún yóó ṣe pọ̀ tó. Ìgbàkígbà tó bá sì wu olówó ló lè lóun fẹ́ẹ́ gba owó òun padà tòun tèrè orí ẹ̀, kodà bó ṣòru lolówó lóun fẹ́ẹ́ gba gbogbo owó òun tàbí nínú ẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni wọn óó yọ̀ǹda rẹ̀ fún un. Èyí kò wáá mọ́ èrè tí àwọn èèyàn ń rí bí wọ́n bá gba Opay ra káàdì tàbí dátà sórí fóònù wọn.

Ọ̀rọ̀ ọ̀hún ti ń fẹ́ẹ́ jọ ìpòlówó àbí? Ẹ̀ẹ̀h! Mo ti sọ láti ìbẹ̀rẹ̀ pé béèyàn bá ṣe dáadáa ẹ jẹ́ ká kí i kó lè máa bá bẹ́ẹ̀ lọ. Nígbà tá a bá kọ̀ tá ò kí olóòótọ́ kẹ́lòmì-ín le wò ó láwòkọ́ṣe, ǹjẹ́ a ò ní í ya alábòsí bí a bá ń kígbe lé oníjìbìtì èèyàn nígbà tí wọ́n mọ̀ pé kò sí èrè kan láwùjọ fún ẹni tó bá ń ṣòótọ́? Ohun tó sì fà á rèé tí Opay fúnra rẹ̀ fi gba àwọ́ọ̀dù bíi mẹ́ta pọ̀ lọ́dún 2023.

Ẹgbẹ́ àwọn onípolówó ní Nàìjíríà, Advertisers’ Association of Nigeria (ADVAN), kóra jọ fún Opay láwọ̀ọ́dù Consumer Choice Award for Best Fintech ọdún 2023 – ìyẹn ìkànnì ètò ìfowóránṣẹ́-síra-ẹni lórí ẹ̀rọ ayélujára táwọn èèyàn gba tiẹ̀ jùlọ lọ́dún 2023. Àjọ elétò ọrọ̀-ajé lágbàáyé pàápàá gbóríyìn fún Opay lórí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe. Àjọ yìí ni wọ́n ń pè ní World Economic Forum. Ó tún kù dẹ̀dẹ̀ kí ọdún 2023 parí ni àjọ NITDA (National Information Technology Development Agency) tún fi àmì ẹ̀yẹ mì-ín dá a lọ́lá.

Nígbà tí a sì ti ń fura díẹ̀ díẹ̀ pé wàhálà ń rúwé bọ̀ rèé. Ohun tá a kọ́kọ́ rí ni fídíò ọdún 2020 nígbà tí Opay ní ááwọ̀ pẹ̀lú àwọn oníbàárà rẹ̀ kan, èyi tí wọ́n paná ẹ̀ pé ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ ni la tún rí fọ́tò kan tó ń pòòyì orí ìkànnì ayélujára. Nínú fọ́tọ̀ yìí, àwòràn ẹnì kan wà níbẹ̀ tí ẹni tó yà á rí i dájú pé ọ̀rọ̀ bo ojú onítọ̀hún dáadáa. Ohun tí a sì rí nínú fọ́tò yìí ni àkọsílẹ̀ ẹnì kan tó ń sọ fẹ́nì kejì rẹ̀ pé kóun àti gbogbo ẹbí ẹ̀ tètè lọọ kówó kúrò ní Opay torí wọ́n ti fẹ́ẹ́ pajú dé, wọ́n óó sì kówó àwọn èèyàn lọ.

Opay fúnra wọn ti jáde sọ̀rọ̀ lórí èyí pé àhesọ lásán ni gbogbo ọ̀rọ̀ tó wà nínú fọ́tò ọ̀hún, Opay ò níbì-kan-an lọ. Àwọn tó ṣe eléyìí mọ̀ pé irú ọ̀rọ̀ báyìí yóó tà nínú àwùjọ táwọn èèyàn ò ti mọ iṣẹ́ tí ẹ̀ka ìjọba kọ̀ọ̀kan ń ṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Opay ti kéde pé àwọn ò fìgbà kan gbèrò láti kógbá nílẹ̀, síbẹ̀ àìmọye èèyàn lèmi rí tí wọ́n kówó kúrò lórí Opay nítorí ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ tí kò ríbì kan fẹsẹ̀ múlẹ̀ yìí. Bí ẹ bá bi eléyìí, yóó ní Opay ò dáa. Bí ẹ bá bi tọ̀hún, yóó ní Opay fẹ́ẹ́ kógbá nílẹ̀. Ẹlomì-ín yóó tiẹ̀ ní nítorí wọ́n fẹ́ẹ́ lu àwọn èèyàn ní jìbìtì ni wọ́n ṣe ń fún wọn láwọn àǹfààní tí wọn kì í rí lára àwọn báǹkì mì-ín tẹ́lẹ̀. Ohun tó sì mú mi kọ́kọ́ bẹ̀rè ọ̀rọ̀ mi nípa sísọ àkọsẹ̀jayé báǹkí ní bó ṣe yẹ kó rí gan-an rèé. Ẹni tí wọ́n bá ń lù láti ilé ọkọ kan bọ́ sí òmì-ín, kò sí bí kò ṣe ní í ní wọ́n fẹ́ẹ́ fòun ṣòògùn owó ni bó bá rọ́kùnrin tó ń kẹ́ ẹ gẹ̀gẹ̀ bó ṣe yẹ kí ọmọlúàbí gbéyàwò.

Ní gbogbo ìgbà tí èèyàn bá tan Opay, yóó gbé orúkọ ilé ìtẹwójadé àgbà báǹkì ní Nàìjíríà, Central Bank of Nigeria, jáde gẹ́gẹ́ bí ẹni tó fáwọn láṣẹ láti máa ṣiṣẹ́, yóó sì gbé orúkọ àjọ NDIC sẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀ pé wọ́n ń mójútó iṣẹ́ àwọn. Àwọn wo ni NDIC, iléeṣẹ́ ìjọba tó ń mójútó bí owó tá a kó sí báǹkì ò ṣe ní í bá afẹ́fẹ́ lọ ni. Iléesẹ́ yìí wà lómìnira, kò sí lábẹ́ CBN fúnra ẹ̀ tábí lábẹ́ iléeṣẹ́ ìjọba kankan tó le ṣàì má jẹ́ kó ṣiṣẹ́ ẹ̀ bó ṣe yẹ. Àwọn ìjọba ológun ló dá a sílẹ̀ nígbà tí wọ́n ṣì ń ṣàkóso Nàìjíríà lọ́dún 1986, National Deposit Insurance Corporation gan-an ni àpèjá orúkọ wọn, ṣùgbọ́n níbikíbi tí ẹ bá ti rí NDIC, àwọn náà ni.

Bí àjọ CBN bá fún báńkì kankan láṣẹ láti máa gba owó àwọn èèyàn sọ́wọ́, bí NDIC kò bá tí ì fọwọ́ sí báǹkì yìí, kíkówó sí báǹkì ọ̀hún dà bí ìgbà tí èèyàn bá ń gbórí sẹ́nu kìnnìún ni, lọ́jọ́ ebi bá pa á tó gbe eyín lé olúwa ẹ̀ lọ́rùn kò sẹ́ni tí yóó dá kìnìhún lẹ́bi torí gbogbo èèyàn ló mọ̀ ọ́n lájeegun-jẹran tẹ́lẹ̀. Èèyàn ọlọ́pọlọ pípé tó lọọ gbé orí rẹ̀ sí kìnnìhún lẹ́nu ni wọ́n óó máa bú pé ó kú ikú agọ̀.

Kín ni iṣẹ́ àjọ NDIC yìí gan-an? Lọ́dún 1983 nìjọba ológun gbé àjọ kan sílẹ̀ pé kí wọ́n ṣèwádìí lórí àwọn ìṣòrò tí ẹni tó bá ń kówó sí báńkì lè kojú bí báńkì ọ̀hún bá déédé pajúdé, tí wọ́n bá ṣẹ̀ sófin tí ìjọba ní kí wọ́n palẹ̀mọ́ tàbí tí àwọn adarí báǹkì bá bẹ̀rẹ̀ si í ṣe ètò báǹkì báṣubàṣu tó di pé owó táwọn èèyàn kó sí wọn lọ́wọ́ di ìdàkudà tí wọn ò lè ṣiṣẹ́ mọ́, ọ̀nà wo la lè fi dáàbò bo owó àwọn èèyàn tó kówó sí báǹkì. Àbájáde ìwádìí ọ̀hún ló bí Nigeria Deposit Insurance Corporation, kókó iṣẹ́ wọn náà sì ni láti rí i dájú pé ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ sí Báńkì, àwọn tó ń kówó sí wọn lọ́wọ́ kò sì pàdánù owó tí wọ́n ń kó sí wọn lọ́wọ́ kódà bí wọ́n bá fẹ́ẹ́ pajúdé.

Láti ríṣẹ́ yìí ṣe, ojúṣe wọn ni láti mojútó báńkì kí wọ́n le rí i dájú pé wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe, àwọn fúnra wọn sì ń yá báńkì lówó bó bá ní ìṣòrò owó tó le ba iṣẹ́ rẹ̀ jẹ́. Lára ojúṣe wọn ni láti gba báńkì nímọ̀ràn bó bá fẹ́ẹ́ gbé ìgbésẹ̀ tó le ṣe é ní ìjàm̀bá, bó bá sì di pé àwọn adarí báǹkì kò gbọ́ ìkìlọ̀ tí wọ́n ń gbé ìgbésẹ̀ tó le ba iléeṣẹ́ wọn jẹ́ tí yóó sì padà pa owó àwọn èèyàn lára, ìjọba Nàìjíríà fún NDIC láṣẹ láti gba àkóso báǹkì ọ̀hún tàbí kí wọ́n so ó pọ̀ pẹ̀lú báǹkì mì-ín kó má di pé owó táwọn èèyàn kó sí wọn lọ́wọ́ yóó bómi lọ. Bó bá wáá di pé kò sí ọ̀nà àbáyọ kankan ju kí wọ́n pa ojú báǹkì ọ̀hún dé, NDIC yóó kọ́kọ́ fún àwọn èèyàn tó kówó síbẹ̀ ní owó gbà dání nínú owó tí wọ́n kó sí báǹkì yìí kí wọ́n tóó bẹ̀rẹ̀ si í ta gbogbo ohun tí báǹkì ọ̀hún ní láti sanwó àwọn tó kówó sí wọn lọ́wọ́.

Èyí ni ìfọ̀kànbalẹ̀ ṣe wà fún ẹnikẹ́ni tó bá kówó sí báǹkì pé bí NDIC bá ti ń mójútó báǹkì, kò sí ohun tó le ṣe gbogbo owó àwọn tó wà lọ́wọ́ wọn. Ǹjẹ́ ẹ ti gbọ́? Opay wà lára àwọn iléèfowópamọ́ tí àjọ NDIC ń mójútó láti rí i dájú pé owó tí àwọn èèyàn ń kó sí wọn lọ́wọ́ kò bómi lọ. Èyí fi ń túmọ̀ sí pé bi Opay bá tiẹ̀ fẹ́ẹ́ pajúdé tó fẹ́ẹ́ lu àwọn èèyàn ní jìbìtì, àjọ NDIC àti olórí rẹ̀, Ọ̀gbẹ́ni Bello Hassan, kò lè gbà fún un. Báwo wáá lèèyàn kan yóó ṣe máa wáá gbé àhesọ̀ pé Opay fẹ́ẹ́ kówó àwọn èèyàn lọ sí?

Bí a bá sì ní ká bẹ̀rẹ̀ si í tọ pinpin ọ̀rọ̀ yìí dáadáa, àwọn atiláawí la óó bá níbẹ̀. Àwọn tí í gbowó lọ́wọ́ ẹni, tí kì í fi kún un àfi kí wọ́n yọ kúrò níbẹ̀. Àwọn tí kò láǹfààní kan tí wọ́n le ṣe fún’ni ju kí wọ́n fún èèyàn mẹ́wàá ní mọ́tò nínú èèyàn mílíọ́nù mẹ́wàá tó ń kówó sí wọn lọ́wọ́. A ò sì lè sọ, ó le má jẹ́ àwọn ni ajere ọ̀rọ̀ óó ṣí mọ́ lórí o, ṣùgbọ́n bí isó bá ń rùn – ẹni tó tí ń lọọgun inú rírun náà la óó fura sí. Ìgbà tí àwọn èèyàn ń kígbe pé Opay ò ṣeé fọkàn tán, ó kúkú níbi tí wọ́n ń rọ́jú kówó lọ bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn wọ̀nyí kò lè ṣe wọ́n láǹfààní kankan.

Opay lọ́fíìsì o, wọ́n láwọn òṣìṣẹ́ tó lé lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta tó jẹ́ pé láti ilé wọn ni wọ́n ti ń dá àwọn èèyàn lóhùn bí ẹnikẹ́ni bá níṣòrò pẹ̀lú báǹkì wọn. Yàtọ̀ séyìí, àwọn òṣìṣẹ́ kún ọ́fíìsì wọn bìbà tí wọ́n ń dá àwọn èèyàn lóhùn. Bí ohunkóhun bá ń rú yín lójú nípa ètò wọn, ẹ le lọ sí ọ́fíìsì wọn kẹ́ lọọ bèèrè wò.

Bí èèyàn bá ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ Opay tó fi kóòdù ẹni tó pè é wọlé síbẹ̀, wọ́n óó fún un ni N1,200, ẹni tó pè é wọlé náà óó gbà N800 lọ́fẹ̀ẹ́. Ẹ jọ̀ọ́, báwo ni irú báǹkì bẹ́ẹ̀ ò ṣe ní í gbòrò.

Ẹ wò ó, bí ẹ bá wà lára àwọn tó kówó kúrò ní Opay lọ síbi tí wọ́n ti ń yọ owó yín díẹ̀ díẹ̀ nítorí pé wọ́n ní ẹnì kan sọ pé Opay fẹ́ẹ́ kówó sá lọ, ẹ lọọ dá owó yín padà síbẹ̀ kó máa pọ̀ sí i. Opay ò níbì kan-an lọ. Bí Opay bá tiẹ̀ ń lọ pàápàá, ètò NDIC ò ní í jẹ́ kówó yín tẹ̀lé e lọ síbikíbi.

Bí àwọn èèyàn óó bá tilẹ̀ kọ Opay sílẹ̀, ẹ jẹ́ kí wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀ nítorí Opay ò ṣe dáadáa sí wọn mọ́ nínú àwùjọ. Ṣùgbọ́n ká máa wáá fi irọ́ àti àwọn àhesọ burúkú báyìí ba iṣẹ́ ẹni tó ń ṣe dáadáa jẹ́ kì í ṣe nǹkan gidi. Ní lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí o, Opay ń pé àwa tí à ń kówó sí i. Kí báńkì tó bá fẹ́ẹ́ bá wọn figagbága náà ṣe ohun tí yóó fa ojú àwọn èèyàn mọ́ra ju ti Opay lọ.

Láti fèsì sí fọ́nrán yìí tàbí ọ̀kankan nínú àwọn fọ́nrán IRIS MEDIA PROSPECTS SERVICES, ẹ lè kàn sí wa lórí nọ́mbà yìí +2348085548868 tàbí +2348135875210. Iṣẹ́ àwùjọ niṣẹ́ ìbọ́pọ̀-èrò-sọ̀rọ̀. Iṣẹ́ àdáṣe ni ká rorí, ká ṣiṣẹ́ ìwádìí, ká sì gbé e kalẹ̀ lọ́nà tí yóó fi yé tolórí tẹlẹ́mù. A ò gbowó oṣù lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, ṣùgbọ́n bí a bá rí ìrànlọ́wọ́ a ò le kọ̀ ọ́. Ẹ fi fídíò wa ránṣẹ́ sọ́pọ̀ èèyàn kó le túbọ̀ ṣiṣẹ́ ìdàgbàsókè nínú àwùjọ, ẹ sì lè kàn sí wa ká gbọ́ látẹnu yín bí àwọn ọ̀rọ̀ wa bá tako ìgbàgbọ́ yín.

Musa Babátúndé-Kọ́gà lorúkọ mi, òjò ni mí n ò bẹ́nì kan ṣọ̀tàá, ẹni eji rí leji ń pa. Àárá ni mí n ò bẹ́nì kan ṣọ̀tẹ̀, ẹni bá dènà dè mí ni óó ríjà arábámbí onígba ọta. Ojú tí mo fi rí ohun tó ń lọ láwùjọ wa rèé ò, ìyókù tún dọjọ́ mì-ín táàyè bá gbà mí níbi tí ẹnu mi óó ti leè rọ́rọ̀ sọ. Ire o.


Post a Comment

0 Comments