Làákàyè ṣe pàtàkì nínú ayé ọmọ ẹ̀dá ènìyàn. Ó wà lára àwọn kókó pàtàkì tó yà wá sọ́tọ̀ láàárín àwọn ẹ̀dá ayé gbogbo. Abẹ́ làákàyè ni ìgbàgbọ ohun tó le ṣẹlẹ̀ àti èyí tí kò lè ṣẹlẹ̀ ń gbé nínú orí wa. Ṣùgbọ́n ibi tí mo fẹ́ẹ́ mú ọ lọ lónì-ín pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu mi, ibi tí làákàyè ò ti ní í wúlò púpọ̀ ni. Ibi tí làákàyè tí í di ẹrù jángan-jàgan tí í fa'ni sẹ́yìn ni.
Torí ẹ̀ ni mo ṣe fẹ́ẹ́ gbà ọ́ nímọ̀ràn pé kí o gbé làákàyè rẹ sílẹ̀ lẹ́nu ibodè. Jẹ́ ká jọ sáré lọ kánmọ́-kánmọ́ ká dé kíákíá. Ibi tá à ń lọ ò sì fi bẹ́ẹ̀ jìnnà púpọ̀ o, ẹgbẹ̀rún ọdún méjì lásán ni lórí ilẹ̀ tá a wà yìí. Ṣùgbọ́n má fòyà. Báyòówù ká rìn jìnnà tó, mo fi ń dá ọ lójú pé nǹkan kan ò ní í ṣe ẹrù tó o gbé kalẹ̀ síbodè. Nígbà tí a óò bá ti ìrìnàjò tí à ń lọ yìí dé, ọ̀pọ̀ yanturu lẹrù ìrírí tó ó kó padà síbi tá a ti gbéra.
Ní báyìí ọ̀rẹ́ mi, da tọwọ́ rẹ'ẹ́lẹ̀. Gbàgbé gbogbo nǹkan tó o ti mọ̀ nípa ayé yìí kí o sì tẹ̀lé mi lọ sínú ayé tuntun. Níbi tí àwọn mì-ín yòó pè ní ayé àtijọ́. Níbi tí àwọn bàbá nlá rẹ fi ṣe ibùgbé wọn nígbà kan.
Hm̀! Òǹkọ̀tàn ni mí. Ṣùgbọ́n n ò fí bẹ́ẹ̀ lórúkọ láàrin àwọn akẹgbẹ́ mi. Ìtàn tèmi yátọ̀ sí tiwọn gedegbe. Ìtàn àtijọ́, àwọn orúkọ ńlá ìgbànnì tí kò ríbi wọ inú ìwé àkọọ́lẹ̀ lèmí ń kọ. Báwo wáá ni mo ṣe ǹ mọ àwọn ìtàn wọ̀nyìí nígbà tẹ́nìkan ò fi í sínú àkọọ́lẹ̀ rí?
Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé fúnra àwọn tó ni ìtàn ọ̀hún ni wọ́n máa ń wá bá mi. Òmíràn yóò ní nǹkan bíi ọgọ́rùn-ún méje ọdún sẹ́yìn lòún lo ìsẹ̀mì-ín òun. Òmí-ìn yóó ní láàrín ọdún 1420 sí 1510 lòún fi gbáyé. Àì sí àkọọ́lẹ̀ láàárín àwọn èèyàn òun ló jẹ́ kí ìtàn òun bómi lọ. Torí ẹ̀ lòun ṣe wáá bá mi láwòrán èèyàn, kí n le ṣàkọọ́lẹ̀ ìtàn òun fún gbogbo ayé rí.
Níbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ni ẹ̀rù kọ́kọ́ ń bà mí. Ṣùgbọ́n àwọn ẹni àtijọ́ wọ̀nyí ò ṣeé sá fún. Àwọn funra wọn kì í wá lọ́nà tí í ba ni lẹ́rù gan-àn. Bí n ò sì ṣàkọọ́lẹ̀ ìtàn wọn bí wọ́n ṣe fẹ́, wọn kì í le padà sínú ìsinmi. Ìtàn wọn kì í sì í ṣe ọ̀rọ̀ tá a lè kọ kalẹ̀ lérèfé ká mójú kúrò. Odidi ìtàn ìgbésí ayé ẹnì kan ni. Iṣẹ́ tí yóó gba’ni ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí, tàbí àìmọye ọjọ́ nígbà mí-ìn ni.
Iṣẹ́ tó máa ń gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà ni, ṣùgbọ́n nígbà tó yá, èmi náà padà ń gbádùn ọ̀rọ̀ wọn. Torí ìtàn ìgbésí ayé wọn lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà, à-rí-má-leè-lọ̀ ni. Ó padà wáá mọ́ mi lára débii pé ó fẹ́ẹ̀ má jẹ́ nǹkan kan mọ́ nísìnyí bí mo bá pàdé wọn. A óó jọ wá ibì kan fìkàlẹ̀ sí ni. Èmi áá mú ìwé àti gègé ìkọ̀wé mi jáde, àwọn óó sì bẹ̀rẹ̀ si í sọ ìtàn tí n óó kọ sílẹ̀.
Ṣùgbọ́n èyí tí mo fẹ́ẹ́ sọ lónì-ín yìí yàtọ́ pátápátá sí ohun tí mo ti ń rí. Ojú àlá lèmi àti ọkùnrin náà ti kọ́kọ́ pàdé ara wa. Fúnra rẹ̀ ló dá ọjọ́ àti àkókó tóun óó wáá pàdé mi, ó sì ní n lọọ dúró de òun létíkun Ẹlẹ́gùṣì lọ́jọ́ náà.
Mo kọ́kọ́ ń ṣiyèméjì pé ó le jẹ́ àlá lásán. Àmọ́ àwọn ìrírí tí mo ti rí sẹ́yìn nínú ìrìnàjò ìwé kíkọ mi ò jẹ́ n le ṣiyèméjì. Mo kó ìwé àti gègé ìkọ̀wé sínú àpò àgbékọ́pá mi, mo sì gba etíkun Ẹlẹ́gùṣì lọ lọ́jọ́ àti àkókò tó dá.
Èmi tiẹ̀ ń ṣe fàájì mi lọ létíkun lọkùnrin ọ̀hún dé. Bó ṣe rí lójú àlá náà ló rí. Ó dúdú, ó ga, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ síngbọnlẹ̀. Èèyàn tó láńkì ni. Ẹni èèyàn le kò lọ́nà tí ìdákẹ́jẹ́jẹ́ rẹ̀ lásán le kó jìnnìjìnnì báàyàn ni.
Hm̀-hm̀! Ọ̀rọ̀ ọ̀hún ti ń jọ ohun tí ò lè ṣẹlẹ̀ àbí? Mo kìlọ̀ fún ọ ká tóó gbéra pé kí o tọ́jú làákáyè rẹ̀ sẹ́nu ibodè torí ìlú èèmọ̀ pelebe là ń lọ. Kódà bí kì í báá ṣe pé èmi ni mo kọ ìtàn yìí ni, n ò lè fi làákáyè gbé e kí n gba ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ gbọ́ rárá. Púpọ̀ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ inú ẹ̀ ló tako làákáyè mi. Bó bá jẹ́ ohun téèyàn kan ròyìn fún mi ni, n ò bá bá onítọ̀hún jiyàn dọ́ba.
Ṣùgbọ́n n ò lè báàyàn jiyàn eléyìí. Ẹni tí mo rí lójú àlá ni mò ń wò níwájú mi yìí. Mi ò lè sọ "Á" sí i. Ojú kan tó ti bá mi náà ni mo dúró sí. Ìgò míníráàsì mi ń bẹ lọ́wọ́ mi, ètè ìsàlẹ̀ ni mo fi gbá sírọ́ọ̀ inú ẹ̀ mú. Kì í ṣe pé mo fi ń mu míníráàsì ọ̀hún o, mo kàn ń wò dọ̀ọ̀ níbẹ̀ ni bíi atọ̀ọ́lé.
Fúnra ọkùnrin yìí ló kọ́kọ́ sọ̀rọ̀. Ó rẹ́rìn-ín ṣúkẹ́ nígbà tó rí bí mo ṣe ń wo òun. Ó ní, "Kí ló dé tó ò ń wò mí báyìí? Ṣèbí èmi náà lò ń dúró dè?" Àsìkò yìí niyè mi ṣẹ̀ tóó sọ. Mo ní, "Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀yin náà ni mò ń dúró dè. Ẹ máa bọ̀, ẹ jẹ́ ká jọ wá ibìkan jòkòó sí."
A wá ibi táàyè wà dáadáa láti sọ̀rọ̀. Níbi tí n óó ti le ṣàkọọ́lẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ láì ní ìdíwọ́. A kọ́kọ́ jọ sọ̀rọ̀ láti fi fa ojú ara wa mọ́ra. Lẹ́yìn náà ló ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ si í sọ̀rọ̀ nípa ìgbésí ayé rẹ̀. O ní: ...
0 Comments