Ọmọ Ìpọ̀nrí-Ìbílẹ̀ ni ìyá mi, ṣùgbọ́n Ìpọ̀nrí-Àṣẹ ni wọ́n tí bí bàbá mi.
Ìrú ìsopọ̀ báyìí kì í sáábà wáyé. Púpọ̀ nínú àwọn ọmọ Ìpọ̀nrí-Àṣẹ tí wọ́n bí bẹ́ẹ̀, ọmọ àlè ni wọ́n. Èmi náà ò lè pe ara mi lọ́mọ ọkọ, torí kò sí ìgbéyàwó kankan láàárín àwọn òbí mi kí wọ́n tóó fún ara wọn lóyún. Ibi ọ̀rọ̀ sì ti wáá burú pátápátá ni pé ọmọọba ni ìyáà mi n'Ípọ̀nrí-Ìbílẹ̀. Àrọ́mọdọ́mọ Oyèbísí tó kọ́kọ́ jọba n'Ípọ̀nrí-Ìbílẹ̀ ni.
Títí tí mo fi pé ọmọ ọdún mẹ́wàá, n ò fojú kan bàbá mi rí. Ṣùgbọ́n àì lè kọlà ìlú Ìpọ̀nrí-Ìbílẹ̀ fi hàn pé bàbáà mi ò kì í ṣe ọmọ ibẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ọmọ ìlú kankan tó wà lágbègbè Ìpọ̀nrí-Ọ̀rá. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ àlè Ìpọ̀nrí-Àṣẹ tí wọ́n bí s'Ípọ̀nrí-Ọ̀rá níbi tí wọ́n ti ń fẹlá kiri ni mí lójú ẹnikẹ́ni.
A ò lè kọlà agboolé Ìpọ̀nri-Ọ̀rá, bẹ́ẹ̀ ni a ò lè kọlà Ìpọ̀nrí-Àṣẹ bí kì í báá ṣe pé bàbáa wa gbà wá. Ẹní bá sì yọ́ ilà kọ níbikíbi nílẹ̀ Ìpọ̀nrí láì gbàṣẹ lọ́wọ́ baalé agboolé bàbá ọmọ, ìdájọ́ ikú ni fún gbogbo ẹni tó bá lọ́wọ́ sí ètò ilà kíkọ náà.
Àwọn ará Ìpọ̀nrí-Ọ̀rá máa ń kórira wa nítorí ẹ̀jẹ̀ bàbá wa tó jẹ́ ọmọ Ìpọ̀nrí-Àṣẹ, àwọn bàbá wa kì í fẹ́ẹ́ rí wa sójú débi tí wọ́n óó gbà wá nítorí àwọn ìyá wa tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Ìpọ̀nrí-Ọ̀rá. Ìwàláyé wa máa ń bí wọn nínú. Rírí wa máa ń rán wọn létí ọjọ́ tí wọ́n ṣìwàwù tí wọ́n bá ọmọ ọ̀tá wọn lájọṣepọ̀. Ṣọ̀bọ̀rọ́ Ìpọ̀nrí ni wọ́n ń pè lọ́mọ aláìníran. Àìlèkọlà ìyá tàbí bàbá wa mú ká dà bíi ọmọ ẹyẹ tó jábọ́ látojú-ọ̀run tẹ́nì kan ò mọ ẹni tó ṣu ú.
Pé ìyá mi jẹ́ ọmọọba ò yà mí sọ́tọ̀ nínú àwọn ṣọ̀bọ̀rọ́ tí wọ́n kórira lágbègbè Òkè-Ọba Ìpọ̀nrí-Ìbílẹ̀ tá à ń gbé. Ṣùgbọ́n tèmi sàn ju ti àwọn tí wọ́n ń gbé láàárín aráàlú tó jẹ́ ikú àìmọ̀dìí ló ń pa wọ́n sínú oko.
Lẹ́yìn tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́wàá, ó hàn sí ìyá mi fúnra rẹ̀ pé kò lè dáàbò bò mí mọ́. Èéfín ogun ń rúgbó bọ̀ nílẹ̀ Ìpọ̀nrí, ẹnì kan ò sì mọ̀gbà tí iná rẹ̀ ó sọ.
Èyí ló mú kó ránṣẹ́ sí bàbá mi n'Ípọ̀nrí-Àṣẹ fún ìgbà àkọ́kọ́ látìgbà tó ti bí mi.
Gbogbo rẹ̀ sì tún dà bí àná, lọ́jọ́ tí n óó kọ́kọ́ fojú kan bàbá mi. Hm̀! Akínkanjú ọkùnrin ni baba mi.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun nìkan ló dá wá, kò sí béèyàn óó ṣe rí i tí ò ti ní í mọ̀ pé ọlọ́lá ibì kan ni. Ó ga dáadáa, àwọ rẹ̀ sì mọ́ tónítóní. Èèyàn pupa ni, ṣùgbọ́n irun ìpéǹpéjú ẹ̀ kún o sì dúdú dáadáa. Báwo tiẹ̀ ni mo ṣe lè ṣàpèjúwèé ẹwà baba mi tí yóó yé ọ gan-an? Bàbá mi ni irúfẹ́ ọkùnrin tí obìnrin máa ń fi tẹ̀gàn pè ní fàwọ̀rajà. Bẹ́ẹ̀ ni òun sì ń fàwọ̀rajà lóòótọ́, àwọ̀ ló fi rajà tó fi bí mi. Ọjọ́ yìí náà ni mo mọ̀.
Òru ló fi délé ìyá mi lọ́jọ́ náà, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóó ti wọ Òkè-Ọba lójú ọjọ́, torí àwọn ẹ̀ṣọ́ kì í ṣílẹ̀kùn Òkè-Ọba fún ẹnikẹ́ni bóòrùn bá ti wọ̀, báyòòwù kí onítọ̀hún ṣe jẹ́. Àfi tó bá jẹ́ Ọba Ìpọ̀nrí-Ìbílẹ̀ fúnra rẹ̀, tàbí àlejò tí Onípọ̀nrí-Ìbílẹ̀ ń retí gan-an.
Alẹ́ ọjọ́ náà yàtọ̀ gedegbe nínú ilé wa. Ìyá mi ò rẹ̀ mí tẹ́ bí í tí í máa ṣe tẹ́lẹ̀. Níṣe ló bepo kún inú fìtílà, títí tó sì fi di àkókò àkọ́kọ́kọ àkùkọ ìdájí, èyí tí a ò bá máa pè ní aago méjì òru lónì-ín, orí ìjókòó lèmi àti ìyá mi wà.
Déédé àkókò yìí náà la gbúròó ìkànkùn lẹ́nu ọ̀nà wa. Màámi ò wulẹ̀ bèèrè orúkọ ẹni tó wà lẹ́nu ilẹ̀kùn tó fi lọọ ṣí i. Bí onítọ̀hún ṣe kanlẹ̀kùn pàápàá yàtọ̀ sí béèyàn ti í kanlẹ̀kùn lásán. Ó jọ bíi ẹni pé òun àti ìyá mi ti jọ mọ ohùn ìkànkùn náà. Bí kò bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, kò ní í ṣílẹ̀kùn fún un láì kọ́kọ́ mọ ẹni tó jẹ́. Bó sì ti ṣílẹ̀kùn fún un tán náà ló padà sídìí fìtílà tó jókòó sí tẹ́lẹ̀ bíì ẹni tí kò bìkítà fún un. Bíyàá mi ṣe ṣílẹ̀kun yii naa ni mo rí i pé àwọn ẹ̀ṣọ́ ìyá mi tó wà lẹ́nu ọ̀nà lọ́hùn-ún ti sùn lọ gedegbe bíi ẹni kú. Irú ẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí látọjọ́ tí mo ti gbọ́njú mọ àwọn ẹ̀ṣọ́ ìyá mi. Òòró ni wọ́n máa ń wà tọ̀sán-tòru. Irú àlejò èèmọ̀ wo ló wáá dé yìí tí gbogbo wọn sùn lọ fọnfọn.
Fìrìgbọ̀n rẹ̀ dáyà já mi nígbà tó wọlé, ṣùgbọ́n lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ náà ló ti rẹ́rìn-ín sí mi.
Ó bẹ̀rẹ̀ síwájú mi láti bá mi dọ́gba, ó rẹ́rìn-ín bí ó ti ṣe ń béèrè pé, "Ǹlẹ́ o, arákùnrin, kí loókọ rẹ?", "Ẹniìtàn" lèsì tó jáde lẹ́nu mi. Ó tún ní, "Orúkọ oríkì ńkọ́?" Èmi náà sì fún ún lésí pé, "Àtàndá nìyáà mi sọ mí." O ní, “Kí wáá lorúkọ agboólé rẹ o?” Mo doríkodò torí n ò mọ ìdáhùn síbèérè yìí. Mo ní, “N ò lórúkọ agboolé. Bàbá mi ò gbà mí.” Bàbá mi fi ìka ìlábẹ̀ rẹ̀ gbé àgbọ̀n mi sókè, ó ní, "Wò mì lójú! Ẹniìtàn Àtàndá Ìbú lorúkọ rẹ, torí agboolé Ìbú Ìpọ̀nrí-Àṣẹ ni wọ́n ti bí èmi bàbá rẹ, Ìgbẹ́kọ̀yìí Àdìgún."
Ọ̀rọ̀ yìí bá mi lójijì, ojú ìyá mi si ni mo kọ́kọ́ lọ́ọ́ wò tààrà láti mọ̀ bóyá òótọ́ lèyí. Ìyá mi náà rẹ́rìn-ín sí mi, ó ní, "Bẹ́ẹ̀ ni Ẹniìtan, bàbá rẹ nù-un. Lọ́ọ́ dúró dè mí ní yàrá ìsàlẹ̀, mo fẹ́ẹ́ bá bàbá rẹ ní gbólóhùn díẹ̀."
Síbẹ̀ ọkàn mí pòruru, mo rọra ń rìn lọ sẹ́nu ọ̀nà. Ìbéèrè kan ń sọ kútú nísàlẹ̀ ọkàn mi, ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà mì látì bèèrè torí n ò mọ irú ìdáhùn tí yóò mú wá. Mo ti dé ẹnu ọ̀nà tán kí n tóó rọra kọjú sẹ́yìn bèèrè lọ́wọ́ bàbá mi pé, "Ṣé ẹ ṣetán láti gbà mí bíi ọmọ ni?" Bàámi ní, "N ò fìgbà kan kọ̀ ọ́ rí Ẹniìtàn. Títí tí ayé óó sì fi parẹ́ ni kò sóhun tí yóó yí i padà pe ọmọ mi ni ọ́."
Inú mi mà dùn lóru ọjọ́ yìí o. Mo jáde lóòótọ́ ṣùgbọ́n n ò rìn jìnnà rárá. Inú mi tó ń dùn ò jẹ́ n lè lọ síbi tíyàá mi rán mi. Gbogbo ohun tí wọ́n sì ń sọ pátá ni mò ń fetí kọ́ lẹ́nu ilẹ̀kùn.
Ìbéèrè nìyáà mi fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ fún bàbá mi, ó ní, "Látìgbà wo lo ti mọ̀?" Bàámi ní, "Kó o tóó bí í rárá ni. Ṣùgbọ́n mo wò ó pó ò ní í fẹ́ kí n mọ̀ nípa ẹ̀ nítorí ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín wa. Nígbà tó sì jẹ́ ọmọ-ọmọ Ọba Erínfọlámí ni, mo gbàgbọ́ pé yóó wà lálàáfíà l'Ókè-Ọba níbí ju ibikíbi lọ. Torí ẹ̀ ni mo ṣe ṣe bíi ẹni tí ò mọ nǹkan kan. Ó wáá yà mí lẹ́nu pé nígbà tí ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Láderin, jọba Ìpọ̀nrí-Ìbílẹ̀ gan-an lo wáá ń sáré fi í hàn mí bíi ẹni pé ẹ̀mí rẹ̀ wà nínú ewu níbí. Ṣé ẹ̀ ń pilẹ̀ ogun n'Ípọ̀nrí-Ìbílẹ́ ni?"
Màámi ní, "Ṣé á ń pilẹ̀ ogun n'Ípọ̀nrí-Ìbílẹ̀ ni? Bó o bá pa bàbá ọmọ-ọba, tọmọ-ọba ọ̀hún padà wáá dọba, kí lo retí pé kónítọ̀hún ṣe fún ọ o? Kó gbàlú kó máa bá ọ jó? Iná ogun tó o dá s'Ípọ̀nrí-Ìbílẹ̀ lọ́dún mọ́kànlá sẹ́yìn ti kẹjú gidi, kò sì dájú pé Ìpọ̀nrí-Àṣẹ nìkan ni yóó jó, gbogbo ilẹ̀ Ìpọ̀nrí pátá ni yóó gbóná janjan láìpẹ́.
"Ṣùgbọ́n Ẹniìtàn ò lẹ́ṣẹ̀ kankan lọ́rùn. Bógun bá sì bẹ̀rẹ̀, ó ṣeé ṣe káwọ̀n ẹ̀gbọ́n mi fẹ́ẹ́ bẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ wò lára rẹ̀. Ohun tó tiẹ̀ dájú ni.
"Torí ẹ̀ ni mo ṣe fẹ́ kó o mú un kúrò n'Ípọ̀nrí-Ìbílẹ̀. Ẹniìtàn ò gbọdọ̀ kú o. Mò ń fi ẹ̀mí ẹ̀ lé ọ lọ́wọ́ lónì-ín, torí mo mọ̀ pé kò sẹ́nì kan lórí ilẹ̀ ayé yìí tó le fẹ́ràn rẹ̀ bí èmi àfi ìwọ. Ọmọ wa nù-un."
Bàámi ní, "Mo mọ̀ pé ó ṣeé ṣé kírú ọjọ́ òní wáyé. Mo rí i, bẹ́ẹ̀ n ò sì ṣe nǹkan kan sí i."
Ìyá mi ní, "O ṣe nńkan sí i, Kọ̀yìí. O pa bàbá mi, ìwọ lo dá ọjọ́ òní sílẹ̀ lórí ilẹ̀ Ìpọ̀nrí."
Bàámi ní: "Hm̀! Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń rò ó, pé báwo ni ìbá ti rí tó bá jẹ́ lọ́jọ́ tí mo pàdé rẹ o ò kì í ṣe ọmọọba, èmi náà kì í ṣe alamí. Ṣé o rò pé ìtàn wa yóó yàtọ̀?"
Ìyá mi ní, "Kọ̀yìí Àdìgún Ìbú! O ò kì í ṣe alamí nìkan nígbà tó o pàdé mi. O ti níyàwó méjì s'Ípọ̀nrí-Àṣẹ tí wọ́n ti bímọ rẹpẹtẹ fún ọ. Àǹfààní lásán lo rí lárà mi lọ́jọ́ tó o rí mi. O mọ̀ pé èmi lẹyinjú bàbá mi, o sì fi mí ṣàtẹ̀gùn dé ọ̀dọ̀ rẹ̀. Wò ó, n ò fẹ́ kẹ́nikẹ́ni rí yín títí tẹ́ óó fi kúrò l'Ókè-Ọba. Ǹṣó lọ́dọ̀ rẹ̀ kí n le dágbére fọ́mọ mi fúngbà ìkẹyìn."
Báyìí ni mo gbọ́ mọ tí ìyá mi fi jáde, kò pẹ́ sígbà náà rárá ni bàbá mi jáde. Wọ́n bá mi lẹ́nu ọ̀nà, ni wọ́n bá ń wojú ara wọn.
Ìyá mi bẹ̀rẹ̀ tì mí, ó ní:
"Àtàndá mi ọ̀wọ́n, máa tẹ̀lé bàbá rẹ lọ s'Ípọ̀nrí-Àṣẹ. Kò ní í pẹ́ témi náà óó fi wáá bá yín lọ́hùn-ún. Ùn-ún! Àwọn ẹrù mi ni mò ń palẹ̀mọ́. N óó wáá bá yín bílẹ̀ bá mọ́."
Mo mọ̀ pé irọ́ nìyáà mi ń pa, torí mo gbọ́ ohun tí òun àti bàbá mi jọ sọ nínú ilé. Lóòótọ́ ni ìnú mi dun láti pàdé bàbá mi, ṣùgbọ́n kò wù mí láti pàdánù ìyá tó ti ń dá mi tọ́ látìbẹ̀rẹ̀ ayé mi. Mo sì mọ̀ pé bí mo bá fi tẹ̀lé bàbá mi lóru ọjọ́ náà, òru ọjọ́ náà ni n óó rí ìyá mi mọ. Torí ìdí èyí, mo bẹ̀rẹ̀ si í sunkún gidigidi, mò ń fẹsẹ̀ walẹ̀, n ò fẹ́ kí ìyá mi gbé mi fún bàbá mi.
Ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ si í ba ìyá mi pé ariwo mi óó jí àwọn aládùúgbò. Ìyá mi fúnra rẹ̀ gan-an ti ń sunkún. Kò wu òun náà láti fi mí sílẹ̀, àyànmọ́ ni ò jẹ́.
Bàbá mi pe orúkọ mi, "Ẹniìtàn Àtàndá, sùn!" Kínni mo gbọ́ báyìí sí ọ̀rẹ́ mi, mo sùn lọ gbayawu ni. Òòrùn ti yọ dáadáa kí n tóó lajú sórí ẹṣin pẹ̀lú bàbá mi. Àmọ́ ọpọlọ orí ò tí ì máa ṣiṣẹ́ pé lásìkò náà. Gbogbo egungun ara mi ló ṣì rẹ̀, síbẹ̀ mo ṣì ń gbìyànjú láti janpata kuro lori ẹṣin, bẹ́ẹ̀ ni mò ń sọ̀rọ̀ bíi ẹni tó ń ṣe ìrànràn láti ojú oorun.
Bàbá mi wò mí lójú, èmi náà sì tún wò ó bí mo ṣe ń tòògbé àti sùn lọ. Ó rẹ́rìn-ín ṣúkẹ́, ó ní, "Ó jọ bíi pé o lágídí díẹ̀. Ó dáa bẹ́ẹ̀, yóó wúlò fún ọ dáadáa níbi tá à ń lọ." Èyí ni mo gbọ́ mọ tí mo fi tún sùn lọ.
0 Comments