"Hm̀! Ọ̀rẹ́ mi. N ò lè sọ fún ọ pé báyìí ni kí o ṣe lo ìgbésí ayé rẹ, torí n ò mọ bí òní ṣe rí sí àná tí èmí ti wá. Ṣùgbọ́n mo le ṣàlàyé fún ọ bí mo ṣe gbélé ayé mi lánàá, àwọ́n àṣeyọrí àti àṣewọlẹ̀ mi, àwọn àṣeyege àti àṣìṣe mi. Nípa gbígbọ́ ọ, ó ṣeé ṣe kí o rí àpẹẹrẹ àná lára òní, bóyá àṣìṣe mi le di àṣeyọrí fún ọ.
Bí kò bá sì wúlò fún ọ lọ́nà yìí, o kàn lè gbọ́ ọ láti fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀ pé ìwọ nìkan kọ́ ni ò ń ṣe àṣìṣe, ìṣubú rẹ lónì-ín ò sì túmọ̀ sí pé ilẹ̀ lo ó wà títí láéláé.
Ronú padà sẹ́yìn ọ̀rẹ́ mi. Ronú sí bíi ẹgbẹ̀rún méjì ọdún sẹ́yìn lórí ilẹ̀ adúláwọ̀. Rò ó wò pé báwo ni nǹkan yóó ṣe rí nígbà náà. Rò ó wò pé àwọn òfin wo ló le dèèyàn mọ́lẹ̀ nírú àwọn àkókò yìí. Àwọn nǹkan wo ló le ṣẹlẹ̀ nígbà náà tí kò lè ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ nísìnyí mọ́ láéláé.
Lẹ́yìn tí o bá gbé ọkàn rẹ sípò yìí nìkan làwọn àlàyé mi tóó lè yé ọ dáadáa. Torí láàárín àwọn ìgbà líle yìí lèmi ti wá.
Ìpọ̀nri lorúkọ tí wọ́n sọ ilẹ̀ ibi tí wọ́n ti bí mi. Bí mo bá fẹ́ẹ́ ṣàlàyé ìtàn ìlú mi lọ́nà tí yóó gbà yé ọ, mo ní láti padà lọ sí ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. Mo ní láti sọ bí wọ́n ṣe fi ẹ̀jẹ̀ àti ẹkún sọ ọ́ lórúkọ.
Ní nǹkan bíi ẹgbẹ̀rún ọ̀dún kan ṣáájú ìgbà yìí ni ìtàn ìlú mi bẹ̀rẹ̀, nígbà tí ogun tú ìlú Ìpọ̀nrí àkọ́kọ́, tí Ọba Yọ́rọ̀sọ tó jẹ́ adarí ìlú náà bógun lọ.
Nínú àwọn ọmọ méjìdínlógún tí ọba náà bí, méje ló yè nínú wọn, ọkùnrin mẹ́rin àti obìnrin mẹ́ta. Orúkọ wọn ni Oyèbísí, Adéoyè, Ikúkọ̀yìí, Adéọlá, Adéòtí, Afọláṣadé ati Àgànjú.
Lóòótọ́ ni pé ọmọọba kan náà làwọn méjèèje, ṣùgbọ́n ìyá mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló bí wọn. Agboolé ìya wọn sì ni wọ́n ti tọ́ wọn dàgbà gẹ́gẹ́ bíi àṣà Ìpọ̀nrí.
Ọkùnrin ni Oyèbísí ati Adéoyè, ọmọ ìyá kan náà ni wọ́n. Agboolé Erínléndé ni wọ́n ti bí ìyá wọn. Ọkùnrin ni Ikúkọ̀yìí, ọmọọ̀yá rẹ̀ sì ni Afọláṣadé tó jẹ́ obìnrin. Agboolé Bájàṣóòrò ni ìyá tiwọn ti wá. Ìyá kan náà ló bí Adéọlá àti Adéòtí, ṣùgbọ́n obìnrin làwọn méjèèjì. Àwọn ni wọ́n sì kéré jùlọ nínú àwọn ọmọọba yìí. Agboolé Òkòtì-Ẹ̀yọ̀ ni wọ́n ń pe agboolé ìyá tiwọn. Àgànjú ni kò lọ́mọọ̀yá kankan láàárín wọn, ṣùgbọ́n ọkùnrin lòun náà. Agboolé Ọ̀kínbalóyè ni ìyá tiẹ̀ ti wá.
Àwọn ọmọọba méjèèje yìí ni wọ́n kó ìwọ̀nba ẹrù tí wọ́n le rí kó, wọ́n kó àwọn aráàlú tí Ọlọ́run ní kí orí kó yọ, wọ́n sì kó wọn gba orí omi sá kúrò nílùú abínibí wọn.
Àwọn ọkùnrin mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí ni wọ́n dá ìlú ńlá Ìpọ̀nrí mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sílẹ̀: Ìpọ̀nrí-Ìbílẹ̀, Ìpọ̀nrí-Òkè, Ìpọ̀nrí-Ìsàlẹ̀ àti Ìpọ̀nrí-Àṣẹ. Nínú àwọn ìlú mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí, ìlú Ìpọ̀nrí-Àṣẹ nìkan làwọn ìlú ńlá ńlá mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó kù kò gba tiẹ̀. Kò sì jọ bíi ẹni pé òun náà ń fi tiwọn ṣe nígbà náà. Wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ pátápátá ni.
Ìtàn líle kan wà láàárín ìlú mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó bí ìkórira náà, ohun tó sì mú kí iná ìkórira yìí ṣòroó pa ni pé ọ̀tọ̀ lọ̀nà tí oníkálukú ń gbà sọ ọ́ fáwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn.
Nílùú Ìpọ̀nrí-Ìbílẹ̀ tí mo ti gbọ́njú, ohun tí wọ́n sọ fún wa ni pé Ìpọ̀nrí-Ìbílẹ̀, Ìpọ̀nrí-Òkè, Ìpọ̀nrí-Ìsàlẹ̀ àti gbogbo ilẹ̀ tó wà lábẹ́ Ìpọ̀nrí-Ọ̀rá títí dé etí-odò Olúbùṣe, odidi ìlú kan ni tẹ́lẹ̀. Òun gan-an ni wọ́n kọ́kọ́ dá sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n kúrò n'Ípọ̀nrí àtijọ́ tí ogun tú.
Ohun tó dá wọn dúró sórí ilẹ̀ náà ni àmì ìyanu tó fi hàn sí wọn. Ohun yòówù tí wọ́n bá gbìn sórí ilẹ̀ yìí, ọjọ́ tí wọ́n bá gbìn ín náà ni yóó wù. Kí ilẹ̀ ọjọ́ ọ̀hún sì tóó ṣú lohun tí wọ́n gbìn yóó ti sèso rẹpẹtẹ tó ṣeé jẹ.
Ohun tó mú wọn tẹ̀dó sórí ilẹ̀ yìí gan-an rèé tí wọ́n sọ ibẹ̀ ní Ìpọ̀nrí-Ọ̀rá. Oyèbísí tó dàgbà jùlọ nínú àwọn ọmọọba yìí ló kọ́kọ́ ń ṣe adarí wọn. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọdún díẹ̀ tí èrò ti pọ̀ ní Ìpọ̀nrí-Ọ̀rá, wọ́n pín ìlú ńlá náà sí ọ̀nà mẹ́ta.
Oyèbísí dúró gẹ́gẹ́ bíi ọba Ìpọ̀nrí-Ìbílẹ̀, Adéoyè dúró gẹ́gẹ́ bíi ọba Ìpọ̀nrí-Òkè, Ikúkọ̀yìí sì ni wọ́n fi jẹ ọba ilẹ̀ Ìpọ̀nrí-Ìsàlẹ̀. Gbogbo ilẹ̀ tó kù títí dé etí odò Olúbùṣe ni wọ́n fi ṣe oko ìlú. Lára ẹ̀ náà ni wọ́n ti dá apá kan sí tí wọ́n fi ṣe igbó ọdẹ wọn.
Oyèbísí kò pín ilẹ̀ kankan fún Àgànjú torí òun ló fẹ́ kó jogún ìtẹ́ Ìpọ̀nrí-Ìbílẹ̀ lẹ́yìn tóun bá kú tán.
Ṣùgbọ́n Àgànjú kò fẹ́ bẹ́ẹ̀. Àìnítẹ̀lọ́rùn yìí ló sì fi kó àwọn ará agboolé ìyá ẹ̀ kúrò n'Ípọ̀nrí-Ọ̀rá pẹ̀lú ìrètí pé òun yóó kan irú ilẹ̀ yìí níbòmí-ìn. Àwọn àbúrò rẹ̀ méjèèjì tó ní lọ́bàkan, ìyẹn Adéọlá ati Adéòtí, náà tẹ̀lé e láti wá ilẹ̀ ìlérí tuntun yìí. Ṣùgbọ́n ọ̀tọ̀ lohun tí wọ́n bá pàdé lójú ọ̀nà ìrìnàjò wọn. Oko aṣálẹ̀ ni wọ́n padà tẹ̀dó sí, níbi tí nǹkan kan kò ti lè wù.
Nígbà tí àtijẹ-àtimu nira fún wọn ni Àgànjú àti Adéọlá wá agbára lọ sọ́dọ̀ àwọn àǹjọ̀nnú. Agbára yìí ló fi sà sí wọn n'Ípọ̀nrí-Ọ̀rá tó fi jẹ́ pé wọ́n gbọdọ̀ máa kó ìṣákọ́lẹ̀ lọọ bá à lọ́dọọdún. Gbogbo oúnjẹ tí wọ́n bá sì ṣe wàhálà gbìn káàkiri ilẹ̀ Ìpọ̀nrí-Ọ̀rá, wọ́n gbọdọ̀ máa wáá tà á lówó pọ́ọ́kú nínú ìlú tuntun tí Àgànjú dá sílẹ̀ yìí bí wọ́n bá fẹ́ kí oúnjẹ so nílùú wọn lọ́dún náà.
Gbogbo àwọn ọmọ agboolé ìyá ẹ̀ ló ró lágbára burúkú yìí, tó jẹ́ pé wọ́n láǹfààní láti sọ̀rọ̀ mẹ́sàn-án lójúmọ́ tí àṣẹ yóó sì gùn ún lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Lára ìwà ìgbéraga ọmọọba yìí náà ló fi sọ ìlú rẹ̀ n'Ípọ̀nrí-Àṣẹ — ìlú àwọn ẹni ọ̀wọ̀, ìlú àwọn aláṣẹ̀.
Nígbà tí àwọn ará Ìpọ̀nrí-Ọ̀rá kọ́kọ́ múra láti gba ara wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ ìmúnisìn yìí, ọmọọba Adéọlá l'Àgànjú dẹ sí wọn lójú ogun tí wọ́n pè ní ogun Aládé. Ṣùgbọ́n nísìnyìí, ó ti yàtọ̀ sí Adéọlá, ọmọọba tó kúrò n'Ípọ̀nrí-Ọ̀rá, ó ti di Adéọlá Iyeníjù, àǹjọ̀nnú obìnrin tí í bá kìnnìhún sọ́rọ̀. Àwọn abàmì kìnnìhún rẹ̀ méjèèje ló sì darí lọ s'Ípọ̀nrí-Ọ̀rá láti fi dúkookò mọ́ àwọn ọba wọn.
Ọba yòówù tí ò bá le fi adé àti ọ̀pá àṣẹ rẹ̀ sílẹ̀, ìpakúpa ni Adéọlá ń pa wọ́n. Àwọn kìnnìhún Adéọlá ló máa ń pa irú ọba bẹ́ẹ̀ jẹ. Igbe rara ọba nínú ààfin ẹ̀, tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀ lórí ìtẹ́ ẹ̀ ni Adéọlá fi ń gbadé tòun tọ̀pá àṣẹ kúrò láàfin ọba tó bá ṣorí kunkun.
Látìgbà náà ni Àgànjú àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ si í fọba jẹ ní gbogbo ilẹ̀ Ìpọ̀nrí-Ọ̀rá, òun ló sì gba oyè bàbá wọn nílùú Ìpọ̀nrí àtijọ́, Oyè Ọlọ́fin.
Ṣùgbọ́n n'Ípọ̀nrí-Àṣẹ, ọ̀tọ̀ nìtàn tí wọ́n ń sọ níbẹ̀.
0 Comments