Search This Blog

ILẸ̀ TÍ A FI Ẹ̀JẸ̀ ÀTI ẸKÚN DÁ (2)— Ọ̀WỌ̀ Series (EP03)




 Ìtàn tí wọ́n fi ń kọ́ àwọn ọmọ wọn ni pé Oyèbísí yan Àgànjú jẹ nítorí kò lọ́mọọ̀yá kankan lọ́kùnrin tó le jà fún un, òun ló sì kéré jùlọ láàárín àwọn ọmọ ọkùnrin Ọba Yọ́rọ̀sọ tí wọ́n jọ tẹ ilẹ̀ Ìpọ̀nrí-Ọ̀rá dó. Nítorí ó jẹ́ àbúrò kékeré yìí ni wọ́n ṣe fẹ́ẹ́ dọ́gbọ́n pa orúkọ rẹ̀ rẹ́ nínú ìtàn, kí ìran wọn le máa ṣe aṣáájú lọ.

Ọ̀rọ̀ yìí kò dùn mọ́ Àgànjú àti àwọn aráalé ìyá rẹ̀ nínú, ṣùgbọ́n kò sóhun tí wọ́n lè ṣe fáwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tí wọ́n ti gbàkóso ilẹ̀ ọlọ́rọ̀ náà. Ìbànújẹ ọ̀hún ló sì mú wọn bẹ Àgànjú pé kó darí àwọn kúrò lórí ilẹ̀ yìí. Ibi yòówù tó bá forí àwọn sọ̀, kódà bí kò bá lóore nínú bíi ilẹ̀ ọlọ́ràá yìí, àwọn yóó máa gbébẹ̀ pẹ̀lú ìdùnnú. Níwọ̀n ìgbà tó bá ti jẹ́ òun làwọ́n yàn gẹ́gẹ́ bíi ọmọ Ọba Yọ́rọ̀sọ tí yóó ṣáájú àwọn.

Bí Àgànjú àti àwọn ará agboolé ìyá rẹ̀ ṣe bínú kúrò n'Ípọ̀nrí-Ọ̀rá rèé, tí Adéọlá àti Adéòtí sì tẹ̀lé wọn nítorí ìfẹ́ tí wọ́n ní sí Àgànjú àti bí inú wọn kò ṣe dùn sí ìyànjẹ burúkú yìí.

Ìrìnàjò dé'Pọ̀nrí-Àṣẹ kò rọrùn rárá. Lójú ọ̀nà yìí ni ìjì líle ti gbé ọmọọba Adéọlá lọ, ẹnì kan kò sì gbúròó rẹ̀ mọ́ àfìgbà t’Ógun Aládé Ìpọ̀nrí bẹ̀rẹ̀.

Ṣùgbọ́n lójú àwọn ọmọ Ìpọ̀nrí-Àṣẹ, ire tí wọ́n rí lórí ilẹ̀ wọn tuntun yìí ju ìyà yòówù tí wọ́n jẹ kí wọ́n tóó débẹ̀ lọ. Gbogbo ọmọ Ìpọ̀nrí-Àṣẹ tó kọ́kọ́ dórí ilẹ̀ yìí ló di abàmì èèyàn. Wọ́n lágbára láti sọ nǹkan mẹ́sàn-án lójúmọ́ tí yóó sì ṣẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ àfi ti oúnjẹ tó wọ́n lórí ilẹ̀ wọn. Oko aṣálẹ̀ gidi ni ibẹ̀, kò sóhun tí wọ́n le gbìn sí i tí yóó wù láéláé. Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá jí láàárọ̀ tí wọ́n bá ní kí ìjì óó máa jà, ìjì óó máa jà kíkan kíkan ni. Bí àwọn ọmọ Ìpọ̀nrí-Àṣẹ bá ń lo agbára àṣẹ wọn lọ́wọ́, bíi òrìṣà ni wọ́n máa ń rí. Kò sí ohun kan lórí ilẹ̀ ayé yìí tó le dá wọn dúró àfi ọba wọn. Àṣẹ rẹ̀ nìkan ló borí gbogbo àṣẹ yòówù tí ọmọ Ìpọ̀nrí-Àṣẹ kankan lè pa.

Àwọn ará Ìpọ̀nrí-Ọ̀rá ń wáá tá ounjẹ́ lọ́dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n lówó tó wọ́n gidi ni. Ọba Ìpọ̀nrí-Àṣẹ ló sì de àwọn èèyàn rẹ̀ mọ́lẹ̀, kò jẹ́ kí wọ́n le fi agbára kó àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ lẹ́rú.

Nígbà tó yá, Ọlọ́run gbèjà Ìpọ̀nrí-Àṣẹ. Ilẹ̀ wọn n'Ípọ̀nrí-Ọ̀rá febi tó le pa wọ́n. Ìwádìí sì fi yé wọn pé bí wọ́n bá fẹ́ kí iyàn tó ń mú nílẹ̀ wọn lọ, àfi kí wọ́n máa mú ìṣákọ́lẹ̀ lọ sí Ìpọ̀nrí-Àṣẹ kí ọba ibẹ̀ súre fún wọn. Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni àwọn oníṣòwò wọn gbọdọ̀ máa gbé ọjà lọ s’Ípọ̀nrí-Àṣẹ, gbogbo ọjà tí wọ́n bá sì gbé lọ fún títà ni wọ́n gbọdọ̀ tà níye tí Onípọ̀nrí Àṣẹ bá fàṣẹ sí.

Wọ́n ṣe èyí fúngbà díẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tó yá, ara wọn ò gbé e mọ́. Wọ́n ṣígun láti gba adé lórí Onípọ̀nrí-Àṣẹ, kó le jẹ́ àwọn ni wọn yóó máa fi ẹni tí yóó bá gba ìṣákọ́lẹ̀ jẹ n'Ípọ̀nrí-Àṣẹ.

Àsìkò Ogun Aládé yìí ni Adéọlá Iyeníjù dé pẹ̀lú àwọn abàmì kìnnìhún méje. Òun ló darí ogun Ìpọ̀nrí-Àṣẹ tó sí gba adé mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ilẹ̀ Ìpọ̀nrí fún Àgànjú. Èyí tó sọ ọ́ di Ọlọ́fin àkọ́kọ́ gbogbo ilẹ̀ Ìpọ̀nrí kejì, oyè Ọba Yọ́rọ̀sọ. Bí wọ́n ṣe ń sọ ọ́ n'Ípọ̀nrí-Àṣẹ rèé.

Káàkiri gbogbo ilẹ̀ Ìpọ̀nrí, ẹnì kan ò jẹ́ rí àwọn ọmọ Ìpọ̀nrí-Àṣẹ fín. Ẹni ọ̀wọ̀ ni wọ́n máa ń pe ara wọn. Wọ́n sì gbàgbọ́ pé níbi yòówù táwọn bá dé, ó yẹ kí wọ́n máa pọ́n àwọn lé ni. Ìwọ̀sí yòówù tí wọn ò báà wáá fi lọ àwọn ará Ìpọ̀nrí-Ọ̀rá, lójú tiwọn, ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn babańlá wọn ni wọ́n ń jẹ.

Lẹ́yìn tí Ìpọ̀nrí-Àṣẹ fi ogun àti ẹ̀jẹ̀ tẹ orí àwọn ìlú ńlá Ìpọ̀nrí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ba, àwọn ìlú ńlá mẹ́rin mì-ín padà dìde lórí ilẹ̀ Ìpọ̀nrí. Àwọn ìlú wọ̀nyí ni Apọ́ndú, Ìdí-Àbàtà, Ìṣokùn àti Ìjegun. Àwọn ìlú mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí ni wọ́n dá sílẹ̀ lẹ́yìn Ogun Aláde.

Lẹ́yìn ọdún gbọọrọ tí ilẹ̀ yìí ti ń ṣe ohun mèremère fún ìran wa, agbára rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ si í dín kù díẹ̀ díẹ̀. Àṣẹ padà tán n'Ípọ̀nrí-Àṣẹ. Nílẹ̀ Ìpọ̀nrí-Ọ̀rá tí wọ́n sì ti ń jẹ iṣu tí wọ́n gbìn lóòjọ́ di ohun tí wọ́n ń pé jọ lọ́dún láti wa iṣu. Ọ̀rẹ́ mi, gbogbo ẹ̀ ló dìtàn.

Bíi ìtàn àròsọ lèmi náà fi gbọ́ ọ. Lára àwọn ìtàn alẹ́ tí wọ́n fi ń kọ́ wa níwà ìrẹ̀lẹ̀ n'Ípọ̀nrí-Ìbílẹ̀ ni. Ìtàn àròsọ tí wọ́n fi ń dùn wá nínú pé orí ilẹ̀ àràm̀barà ni ìlú abínibí wa dúró lé lórí.

Ọ̀kan pàtàkì nínú ohun tí a mọ Ìpọ̀nrí-Àṣẹ mọ́ ni Ìjáfùrú Ọba. Eégún méje Ìpọ̀nrí tí í kùn yunmuyunmu lẹ́yìn Ọlọ́fin. Àwọn mì-ín ń pè wọ́n ní etí Ọlọ́fin tàbí Ọdẹ Ọ̀daràn. Ìtàn gbé e pé Adéọlá Iyeníjù ló dá wọn sílẹ̀. Iṣẹ́ wọn ni láti gbógun ti ìwà ọ̀daràn yòówù tó bá le ṣàkóbá fáwọn ará Ìpọ̀nrí-Àṣẹ. Ẹnì kan ò lè sọ pé òun rí wọn rí, bẹ́ẹ̀ ó fẹ́ẹ̀ má sí ohun pàtàkì kan tí yóó ṣẹlẹ̀ n'Ípọ̀nrí-Àṣẹ tí wọn kì í dá sí. Kò sí bí ọ̀daràn kan ṣe lè làgbára tó n'Ípọ̀nrí-Àṣẹ, bí àwọn èèyàn bá ṣì ń gbọ́ orúkọ rẹ̀, kì í ṣe pé ipá àwọn Ìjáfùrú Ọba o ká a o, wọn ò kàn tí ì sọ̀rọ̀ kàn án nínú ẹgbẹ́ wọn ni.

Yàtọ̀ sí Ọlọ́fin Ìpọ̀nrí, ẹnì kan kì í dá wọn mọ̀. Kódà ẹ lè fojú di wọ́n bíi ọmọdé, bẹ́ẹ̀ wọn kì í ṣe ọmọdé rárá, àjẹ́ tí í pa ọmọ jẹ tẹ́ ò ní í rẹ́jẹ̀ lẹ́nu ẹ̀ láéláé ni wọ́n. Gbogbo àwọn tá a sì ń sọ̀rọ̀ wọn yìí kì í ju méje lọ.

Ètò ààbò tó gbópọn táwọn Ìjáfùrú ṣe s'Ípọ̀nrí-Àṣẹ, àti bó ṣe jẹ́ ojú ọjà kànńpá fún tọmọdé-tàgbà oníṣòwò sọ ìlú náà di ìlú elérò rẹpẹtẹ. Òun náà ló sì sọ ọ́ di ọ̀tá àwọn ilẹ̀ Ìpọ̀nrí tó kù lábẹ́ ẹ̀.

Àwọn ọmọ Ìpọ̀nrí-Àṣẹ náà ò sì tún mú nǹkan rọrùn rárá, ayé alábátá ni wọ́n ń jẹ káàkiri gbogbo ilẹ̀ Ìpọ̀nrí. Wọ́n ń gba oko olóko, aya aláya, ilẹ̀ onílẹ̀ tẹ́nì kan ò sì jẹ́ bá wọn wí.

Báyòówù kí ẹ̀ṣẹ̀ náà burú tó, ẹnì kan ò jẹ́ dájọ́ ọmọ Ìpọ̀nrí-Àṣẹ nílùú yòówù tó bá lọ. Ìlú rẹ̀ náà ni yóó ti lọọ gba ìdájọ́ rẹ̀. Ọlọ́fin nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti dájọ́ ọmọ Ìpọ̀nrí-Àṣẹ. Ọba yòówù tó bá dán irú ẹ̀ wò n'Ípọ̀nrí, wọn óó fi orí ẹ̀ ránṣẹ́ s'Ípọ̀nrí-Àṣẹ ni.

Bí wọ́n bá sì gbé ẹjọ́ dé'Pọ̀nrí-Àṣẹ́ náà, ẹnì kan ò mọ ohun tí wọ́n óó bá pàdé lẹ́nu Ọlọ́fin.

Nínú ìdájọ́ àwọn Ọlọ́fin àtijọ́, wọ́n aa máa dá àlejò tó bá jàre láre tí wọn óo sì fìyà jẹ ọmọ Ìpọ̀nrí-Àṣẹ tó bá jẹ̀bi. Ṣùgbọ́n bẹ́ẹ̀ kọ́ lọ̀rọ̀ máa ń rí lọ́pọ̀ ìgbà. Àìmọye ẹjọ́ ni wọ́n ti dá tó jẹ́ pé ẹ̀bì ni wọ́n dá àlejò tó jàre. Ìyà líle tí wọ́n sì ń fi jẹ wọ́n fi hàn pé wọ́n fẹ́ káwọn aráàta máa bẹ̀rù láti kẹ́jọ́ wá s'Ípọ̀nrí-Àṣẹ.

Èyí ló mú kí wọ́n da tàwọn Ẹni-Ọ̀wọ̀ sí wọn lára. Ṣùgbọ́n kì í ṣe pé wọ́n fẹ́ràn wọn rárá. Bíi kí wọ́n fò ṣánlẹ̀ kí wọ́n kú ni wọ́n ń wò wọ́n ní gbogbo ìgbà.

***

Nísìnyìí tí mo ti sọ ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn ìlú ńlá Ìpọ̀nrí fún ọ àti bí ìkórira tó wà láàárín wọn ṣe jinlẹ̀ tó, kò ní í le púpọ̀ fún ọ láti gbọ́ ìtàn mi lágbọ̀ọ́yé. O ti mọ ìlú mi, ó wáá ku kí n ṣàlàyé ìtàn ara tèmi gan-an fún ọ. Kí lorúkọ mi? Kí ló so mí pọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ tí a fi ẹ̀jẹ̀ àti ẹkún dá? Irú ipa wo sì ni mo kó nínú ìtàn ìlú mi?

Post a Comment

0 Comments