1. TA NI WÁ ÀTI PÉ KÍ LÀ Ń ṢE?
Iléeṣẹ́ ìgbétòjáde lóríṣìíríṣìí ọ̀nà tá a forúkọ rẹ̀ sílẹ̀ lábẹ́ àjọ tó ń mójú tó ọ̀rọ̀ iléeṣẹ́ ní Nàìjíríà, Corporate Affairs Commission, ni IRIS MEDIA PROSPECTS SERVICES. Nínú oṣù karùn-ún ọdún 2022 la ṣe ìforúkọsílẹ̀ yìí. Iṣẹ́ tá a gbé lọ́wọ́ ni ṣíṣe àtúpalẹ̀ ìmọ̀ ìgbàlódé fún àwọn elédè kan ṣoṣo tó jẹ́ pé èdè Yorùbá nìkan ni wọ́n gbọ́ tí wọ́n sì lè sọ. À ń ṣàtúpalẹ̀ àwọn ìmọ̀ yìí fún àgbọ́yé àwọn èèyàn wa nípa ṣíṣe àmúlò Ì mẹ́rin kan tí a pè àkójọpọ̀ rẹ̀ ní Í4. Àpèjá Í mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí ni Ìdunninínú, Ìdánilẹ́kọ̀ọ́, Ìmóríyá àti Ìfìmọ̀mọni. Gbogbo ọ̀rọ̀ tàbí ètò yòówù tí a bá gbé jáde lórí ìkànnì yìí gbọdọ̀ wà ní ìbámu pẹ̀lú méjì nínú àwọn Ì mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí a yọ sókè yìí, ó kéré tán. Ìyẹn ni pé bí ò bá jẹ́ ọ̀rọ̀ tó ń múni lórí yá bó ti ń dáni lẹ́kọ̀ọ́, áá jẹ́ ọ̀rọ̀ tó ń dunni nínú bó ṣe ń fìmọ̀ mọni. Pàápàá bó bá tiẹ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ tó kó mẹ́ta nínú àwọn Ì tá a kà ṣáájú yìí, tàbí tó tiẹ̀ ṣàkójọ pọ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin — ìrú ètò yìí gan-an ló dára jùlọ fún àgbéjáde lọ́dọ̀ wa. Bí ẹ bá gbọ́ ohunkóhun láti iléeṣẹ́ IRIS MEDIA PROSPECTS SERVICES, bí ò bá mú yín lórí yá bó ṣe ń dá yín lẹ́kọ̀ọ́, áá jẹ́ ohun tí yóó máa dùn yín nínú bó ṣe ń fìmọ̀ mọ̀ yín. Ohun tí ò bá fi bá àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí ṣe, ẹ má wulẹ̀ yiiri ẹ̀ wò — kì í ṣe látọ̀dọ IRIS MEDIA PROSPECTS SERVICES ló ti jáde.
Iṣẹ́ tá a gbé dání ni láti dí àlàfo ìmọ̀ tí ò jẹ́ kí àwọn tó jẹ́ pé èdè Yorùbá nìkan ni wọ́n gbọ́ jèèrè àwọn ànfààní rẹpẹtẹ tó kún orí ẹ̀rọ ayélujára lónì-ín. A gbàgbọ́ pé àìmọye ànfààní làwọn elédè kan ṣoṣo yìí ò bá máa ṣe fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, àti àgbáyé lápapọ̀, bó bá jẹ́ pé àwọn ìmọ̀ ìgbàlódé yìí wà lárọ̀wọ́tó wọn. Bí ayé ṣe ń yí lọ síwájú ni àwọn ànfààní ń ti inú ẹ̀ jáde fún àwọn Yorùbá lọ́nà tó jẹ́ pé àwọn tó gbọ́ èdè òyìnbó nínú wọn nìkan ló le ríbi jèèrè ẹ̀ lọ́nà ìrọ̀rùn.
Lọ́pọ̀ ìgbà, ojú aláìmọ̀kan tí ò lè gbọ́ àgbọ́yé àwọn ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ayíbírí tó yí ìwàláyé ọmọnìyàn po ni àwùjọ wa fi ń wo àwọn elédè kan ṣoṣo tí ò gbóyìnbó. A ṣàkíyèsí pé ìgbà tí àwùjọ máa ń rántí wọn ni bí àwọn oníléeṣẹ́ bá fẹ́ẹ́ ṣèpolówó ọjà tàbí nígbà tí àwọn olóṣèlú, gbajúmọ̀, tàbí oníléeṣẹ́ aládàáni bá nílò àtìlẹyìn wọn.
Kò sí èsì ìwádìí kan tó fìdìí ẹ̀ múlẹ̀ pé ọ̀rọ̀ kan wà tó le débi pé kò ṣeé tú palẹ fún àgbọ́yé nínú èdè kan lórí ilẹ̀ ayé yìí. Bí kò bá sí ọ̀rọ̀ kan tó ṣòroó tú palẹ̀ fún àgbọ́yé lédè Jamaní, Ṣinkò, Faransé, Kọ̀ráà, Pọtugí, Rọ́ṣíà, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, dájú dájú kò sí èdè tá ò lè sọ di kọ́kọ́rọ́ tí yóó ṣílẹ̀kùn àwọn ìmọ̀ ayíbírí òde òní — ìyẹn bá a bá fẹ́ẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀.
Kì í ṣe pé a lòdì sí èdè Gẹ̀ẹ́sì tàbí àwọn Yorùbá alákọ̀wé tó gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì lọ́nà kankan o. Ohun tí àwa ń lé ni láti fẹ ojú gbàgede ìmọ̀ àwọn Yorùbá tí ò gbóyìnbó kí wọ́n le dúró fẹ̀gbẹ́-kẹ̀ngbẹ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀mọ ìyá wọn alákọ̀wé tó gbédè Gẹ̀ẹ́sì — kó fi jẹ́ pé níbikíbi tálákọ̀wé bá ti ń sọ̀rọ̀, àwọn pàápàá yóó le sọ̀rọ̀ níbẹ̀ láì kọsẹ̀. A gbàgbọ́ pé bí àwọn èèyàn bá lékún nínú ìmọ̀, ìwúlò wọn nínú àwùjọ yóó lékún, bí ìwúlò wọn nínú àwùjọ bá sì lékún — ìtèsíwájú àgbàá-ńlá-ayé tá a jọ wà nínú ẹ̀ yìí yóó le túbọ̀ yásẹ̀ sí i.
2. ǸJẸ́ A NÍLÒ ÌRÀNLỌ́WỌ́?
Bẹ́ẹ̀ ni! Bẹ́ẹ̀ ni, a nílò ìrànwọ́. Ní lọ́wọ́ báyìí, ìnáwó láti ṣàgbéjáde àwọn ètò wa kú sí ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnléláàádóje ó lé igba Náírà (₦174,200). Ohun tí èyí kájú nílẹ̀ ni owó yàrá iṣẹ́, owó òṣìṣẹ́, owó oníbodè ẹ̀rọ ayélujára tá à ń pè ní dátà, owó iná mọ̀nàmọ̀nà, owó àwọn ẹ̀rọ tó ṣeé gbá mú pẹ̀lú èyí tí ò ṣe é gbá mú tá a fi ń ṣiṣẹ́, àti owó ìwọlé sí yàrá ìkàwé ti a ti ń ṣàfikún ìmọ̀ wa. Ṣùgbọ́n kó tóó le yé yín ìdí tá a ṣe nílò ìrànwọ́, a ní láti bọ́ sínú ìbéèrè tó kàn lẹ́yìn èyí — “Ta ló ń jẹ́ ÀWA?”
2.1 TA LÓ Ń JẸ́ ÀWA?
Bí a óó bá sòótọ́ fún ara wa láì fi tèké bọ̀ ọ́, èèyàn kan ṣoṣo ló ń jẹ́ àwa tó ń dún nínú ẹ̀kú IRIS MEDIA PROSPECTS SERVICES. Orúkọ ẹni tó ń ṣe ọ̀gá àti ọmọọṣẹ́ iléeṣẹ́ yìí ni Musa S. Babátúndé-Kọ́gà, akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nípa òpó ìgbọ́rọ̀káyé. Ọdún kẹwàá rèé tó ti ń fakọ yọ gẹ́gẹ́ bíi ògbóǹtarìgí akọ̀wé lédè Yorùbá àti Gẹ̀ẹ́sì. Mo mọ̀ pé kò ní í ṣàì kó yín léyín síta bó ṣe ń pà mí lẹ́rìn-ín lọ́wọ́ báyìí pé òun fúnra rẹ̀ ló ń kọ abala ìrànwọ́ yìí tó ń ki ara rẹ̀ síbẹ̀ ní mẹ́sàn-án mẹ́wàá. Ìrírí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé elédè méjì wà lára ohun tó pilẹ̀ kíkọ́ àti dídarí iléeṣẹ́ IRIS MEDIA PROSPECTS SERVICES. Òun lakọ̀wé, òun lalágbéjáde ètò, òun ni alábòójútó àgbéjáde ètò, òun ni alábàáwí òde, àti ọ̀gá àgbà pátápátá oníṣirò owó fún iléeṣẹ́ IRIS MEDIA PROSPECTS SERVICES.
2.2 NÍBO LOWÓ Ń GBÀ WỌLÉ?
Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ nínú ìdáhùn ìbéèrè 2.1 pé bíi àdìmẹ́rù Baba Sùwé ni Musa S. Babátúndé-Kọ́gà ṣe ń darí iléeṣẹ́ IRIS MEDIA PROSPECTS SERVICES. Ṣùgbọ́n bí yóó bá rówó ṣàgbéjáde iṣẹ́ iléeṣẹ́ yìí, dandan ni kó máa gbé ẹrù wíwo rẹ̀ yìí sílẹ̀ wá iṣẹ́ ajé tí yóó fi rówó lọ. Ó ń ṣiṣẹ́ akọ̀wé fáwọn èèyàn àti àwọn iléeṣẹ́ mì-ín kó le rówó kó jọ láti máa bá iṣẹ́ iléeṣẹ́ gbọ̀gán ìgbétòjáde yìí lọ.
2.3. KÍN NI ÌDIWỌ̀N ÌRÀNWỌ́ TÁ A NÍLÒ?
Bí ìṣòro ìnáwó àgbéjáde ètò bá fi kúrò nílẹ̀, èyí yóó fún iléeṣẹ́ IRIS MEDIA PROSPECTS SERVICES ní òṣìṣẹ́ àkọ́kọ́ tó jẹ́ pé kò sóhun mì-ín tó gbájú mọ́ ju iṣẹ́ iléeṣẹ́ náà lọ. Ṣùgbọ́n kò wù wá láti jẹ́ kó mọ níbẹ̀. IRIS MEDIA PROSPECTS SERVICES nílò àgbájọ ọwọ́ tí yóó bá a gbẹ́rù dórí, ọ̀pọ̀ ohùn tí yóó máa dún lábẹ́ ẹ̀kú ẹ̀, ọ̀pọ̀ akọ̀wé tí yóó máa fi gègé dá bírà àti ọ̀pọ̀ ìpolówó tí yóó jíhìnrere iṣẹ́ rẹ̀ káàkiri àgbáyé kó le kan àwọn èèyàn wa lára.
2.4. BÁWO NI Ẹ ṢE LÈ RÀN WÁ LỌ́WỌ́?
A ti ń wò ó látàárọ̀ náà pé ìgbà wo lẹ óó bèèrè. Ọ̀nà méjì ni ẹ lè gbà ran iléeṣẹ́ IRIS MEDIA PROSPECTS SERVICES lọ́wọ́. Ọ̀nà àkọ́kọ́ ni fífi iṣẹ́ wa han ẹbí àti ọ̀rẹ́ yín níle àti lórí àwọn ìkànnì ayélujára gbogbo. Ìrànwọ́ ìpolongo lẹ̀ ń fún wa ní gbogbo ìgbà tí ẹ bá ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, èyí yóó sì túbọ̀ mú wa súnmọ́ àwọn èèyàn tó le kápá irú ìrànwọ́ kejì tá à ń wá. Ìrànwọ́ kejì ni towó tí yóó dín ẹrù wúwo ọrùn wa kù, tí yóó sì máa mú wa yọ lókè téńté. Ẹ lè lò nọ́mbà ìsàlẹ̀ yìí fi ìrànwọ́ owó ránṣẹ́ sí IRIS MEDIA PROSPECTS SERVICES: (6490559874, Iris Media Prospects Services, Moniepoint MFB).
Owó kan ò kéré, kò sì sí èyí tó pọ̀ jù. Gbogbo ìrànwọ́ owó tá a bá gbà la óó kéde àfi tẹ̀yin tí ẹ bá ní ẹ ò fẹ́ ká gbé orúkọ yín sáyé.
2.5 DÌGBÀ WO NI A LÈ ṢE ÈYÍ DÀ?
Ọ̀gá-iṣẹ́ àti ọmọ-iṣẹ́ IRIS MEDIA PROSPECTS SERVICES bẹ̀rẹ̀ iléeṣẹ́ yìí pẹ̀lú ìlérí kan tó kọ sílẹ̀ nínú ìwé ìrírí rẹ̀, “N óó ṣe ohun tí mo bá lágbára láti ṣe lásìkò tí mo lágbára láti ṣè é, n óó sì fi èyí tí n ò bá lágbára láti ṣe sílẹ̀ dìgbà tí n óó lágbára láti ṣe é.” Àkójọpọ̀ ẹyọ ọ̀rọ̀ tó ń darí ìrìn wa rèé látìgbà tí a ti gbèrò láti ṣiṣẹ́ yìí. Ní gbogbo ìgbà lẹ óó máa bá IRIS MEDIA PROSPECTS SERVICES níbi tó ti ń ṣiṣẹ́ tá a torí ẹ̀ dá a sílẹ̀. A ò ní í dúró, a ò ní í tisẹ̀, a ò sì ní í yéé tẹ̀síwájú pẹ̀lú èròjà yòówù tó bá wà ní ìkápá wa. Bí a bá ṣe le ṣiṣẹ́ rẹpẹtẹ sí la óó ṣe ṣiṣẹ́ rẹpẹtẹ sí, bó bá sì jẹ́ lóní-mọ́mbé náà lapá wa ká a óó gbé e síta bẹ́ẹ̀ — ṣùgbọ́n laelae, a ò ní í dúró.
2 Comments
Ẹ kú iṣẹ́ takuntakun, Elédùà Yóò túbọ̀ kà wá yẹ nínú ohun gbogbo.
ReplyDeleteÀmín àṣẹ Èdùmàrè.
DeleteẸ ṣeun fún àdúrà yín. Ẹ má gbàgbé láti fi àwọn àkọsílẹ̀ àti fọ́rán wa ránṣẹ́ sí àwọn èèyàn yín nílé-lóko. Elédùà yóó bá wa dúpẹ́ lọ́wọ́ yín bí ẹ ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀.
Ire o. 🙏🏽