Àbí yóó wù ọ́ láti gbọ́ àkọsílẹ̀ yìí dípò kíkà á? Tẹ ibí.
Fún ọmọ Nàìjíríà yòówù tó bá ti mọ ọwọ́ ọ̀tún yàtọ̀ sósì láàárín ọdún 1966 sí 1999 kò lè lóun ò gbọ́ Kúù rí. Ọ̀rọ̀ yìí le má nítumọ̀ béèyàn bá kọ́kọ́ gbọ́ ọ torí kì í ṣe èdè Yorùbá, kì í ṣe èdè Gẹ̀ẹ́sì pàápàá, èdè Faransé ni. Àpèjá rẹ̀ ni Coup d'éqtat.
Bí a bá fẹ́ẹ́ sọ̀rọ̀ Coup de tat yìí lédè Yorùbá, kò sí nǹkan mì-ín tó túmọ̀ sí ju ìdìtẹ̀gbàjọba lọ. Èyí ni pé àwọn èèyàn díẹ̀ kan yóó kó ara wọn jọ, wọn yóó sì jọ gbìmọ̀ pọ̀ láti gba agbára lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n wà níjọba láì bọ̀wọ̀ fófin. Nígbà mì-ín, ìdìtẹ̀gbàjọba yìí máa ń gba kí wọ́n pa àwọn tí wọ́n wà níjọa, kí wọ́n jù wọ́n sẹ́wọ̀n tàbí kí wọ́n tilẹ̀ lé wọn kúrò nílùú pátápátá.
Yàtọ̀ sí ètò ìjọba àwa-ara-wa tó jẹ́ pé kí ẹnikẹ́ni tóó le gbàjọba, yóó nílò ìfọwọ́sowọ́pọ̀ aráàlú pẹ̀lú ìbò wọn, Coup kò nílò ìbò aráàlú láti fún àwọn òǹdìtẹ̀ yìí lágbára, ẹnikẹ́ni tí ìdìtẹ̀gbàjọba náà kò bá tẹ́ lọ́rùn ṣetán láti bá ìbọn ní gbólóhùn nìyẹn. Ìyẹn bó bá ṣeé sọ.
Ààrín àwọn ológun ni ìdìtẹ̀gbàjọba yìí ti wọ́pọ̀ jùlọ, kò sí nínú ètò olóṣèlú àfi bí wọ́n bá da nǹkan rú, tí ohun gbogbo ò sì lọ bó ṣe yẹ kó lọ.
Láti ayébáyé làwọn èèyàn ti ń dìtẹ̀gbàjọba káàkiri àgbáyé, ṣùgbọ́n ní lọ́wọ́ bí a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, orúkọ Coup de tat yìí ló gbilẹ̀ jùlọ láti fi ṣàpèjúwèé ìdìtẹ̀gbàjọba.
Yàtọ̀ sí pé àwọn ológun wọ̀nyí dìtẹ̀gbàjọba, wọn aa máa fẹ̀sùn ìwà ìbàjẹ́ kan àwọn òǹṣèjọba tí wọ́n gba agbára lọ́wọ́ ẹ̀ kí aráàlú le túbọ̀ gba tiwọn, kódà nígbà tí agbára ìbọn wà lọ́wọ́ wọn.
Wọ́n le ní àwọn òǹṣèjọba tó kọjá lọ ń kówó jẹ, wọ́n ń ṣe ẹ̀yàmẹyà, tàbí wọn kò ṣètò ìjọba bó ṣe yẹ. Èyí le jẹ́ òótọ́, ó sì lè jẹ́ irọ́, ṣùgbọ́n gbogbo ohun tí àwọn aṣẹ́gun yìí bá le sọ láti fi fa ojú aráàlú mọ́ra ni wọn óó sọ. Torí bí aráàlú bá fi kọ̀yìn sí ìgbàjọba wọn, àtiṣubú àwọn náà kò ní í pẹ́ mọ́. Wọn ò sáà ní í le pa gbogbo èèyàn tán láti ṣèjọba lórí òfo.
Ìdìtẹ̀gbàjọba àkọ́kọ́ tó ṣẹ̀lẹ̀ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni ti ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún, oṣù kìn-ín-nì ọdún 1966, nígbà tí Col. Emmanuel Ifeajuna, Lit. Kaduna Nzeogwu, Maj. Adéwálé Adémóyèga, Maj. Timothy Onwuatuegwu, Maj. Chris Anuforo, Maj. Humphrey Chukwuka, àti Maj. Donatus Okafor, dìtẹ̀gbàjọba lọ́wọ́ àwọn olóṣèlú alágbádá lórí ẹ̀sùn pé ìjọba náà ń ṣe ẹ̀yàmẹ́yà, wọn ń kówó jẹ, wọ́n kò sì ṣètò ìjọba lọ́nà tí ara óó fi dẹ aráàlú.
Yàtọ̀ sí ìdìtẹ̀gbàjọba oṣù kìn-ín-ní ọdún 1966 tó ṣídèrí lórí ètó yìí fún Nàìjíríà, ìdìtẹ̀gbàjọba mẹ́fà ló tẹ̀lé e kó tóó di pé agbára padà dúró sọ́wọ́ àwọn olóṣèlú bó ṣe dúro yìí.
Èyí ni àwọn ìdìtẹ̀gbàjọba náà bó ṣe lọ:
1. Ìdìtẹ̀gbàjọba oṣù keje 1966 tí Muritala Muhammed àti Theophilous Yakubu Danjuma darí tó gbé Ọgágun Yakubu Gowon wọlé ìjọba.
2. Ìdìtẹ̀gbàjọba ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù keje ọdún 1975, èyí tó sọ Muritala Muhammed di olórí ìjọba Nàìjíríà.
3. Ìdìtẹ̀gbàjọba ọjọ́ kẹtàlá, oṣù kejì ọdún 1976 tí Colonel Buka Suwa Dimka darí. (Ìdìtẹ̀gbàjọba yìí kò yọrí síre fáwọn tó darí ẹ̀, òun ló sì sọ Ọ̀gágun Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ di olórí ìjọba Nàìjíríà)
4. Ìdìtẹ̀gbàjọba ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù kejìlá ọdún 1983, èyí tí Ọ̀gágun Muhammadu Buhari darí.
5. Ìdìtẹ̀gbàjọba ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù kẹjọ ọdún 1987, èyí ti Ọ̀gágun Ibrahim Badamosi Babangida darí.
6. Ìdìtẹ̀gbàjọba ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù kejìlá ọdún 1993, èyí tí Ọ̀gágun Sani Abacha darí.
Ìdìtẹ̀gbàjọba jẹ́ ohun tó le sọ àwọn tó bá ń gbìmọ̀ rẹ̀ di alágbára láàárín ìlú, ó sì lè pàdí dà kó di ohun tí yóó gbẹ̀mí wọn. Ohun tó bá fi mú kí ètò náà fìdìí rẹmi tí wọn ò délé ìjọba, gbogbo àwọn tí wọ́n lọ́wọ́ sí i ni wọ́n óó fẹ̀sùn ọlọ̀tẹ̀ kan. Ikú sì ni ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀.
0 Comments